AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA CONVENANT KÚ SÍ ORÍ PÁPÁ ÌṢERÉ.
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Convenant kú sí orí pápá ìṣeré lásìkò tí òun àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ń gbá bọ́ọ̀lù. Toluwase Jesutunmise ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, ìpele karùn-ún ló wà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ilé kikọ́.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu ọ̀gá ilé ìwé náa; Ọ̀jọ̀gbọ́n Timothy Anake ni pé Toluwase ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lórí pápá ilé ìwé, ṣàdédé ló ní ó rẹ òun tí ó sì bọ́ sí ẹ̀gbẹ́ lọ mu omi. Bí ó ṣe mu omi tán ló di pé kò le mí dáadáa mọ́, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ilé ìwé náà tó wà ní àdojúkọ pápá ìṣeré náà. Nígbà tí wọn yóò fi dù ú dé ilé ìwòsàn ńà, Toluwase ti dákẹ́ kò sí mí mọ́.
Anake ṣe àlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Toluwase kò mí mọ́ lásìkò tí wọ́n gbé e dé ilé ìwòsàn náà, àwọn dọ́kítà gbìyànjú àwọn ìlànà tí wọ́n le fi jí i bóyá èémí rẹ̀ ṣì le padà àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Àwọn dọ́kítà náà wí pé àìsàn ọkàn ni ó ṣekú pa Toluwase ó sì ti wà lára rẹ̀ tipẹ́.
Wàyí o, àwọn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́jáde nílé ìwé náà faraya lórí ìkànnì ayélujára, wọ́n kọ̀ ọ́ pé ilé ìwòsàn náà kàn wà níbẹ̀ ni wọn kìí ṣe ìtọ́jú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn. Ẹnìkan kọ ọ́ pé ní ọdún 2017 tí òun nílò àfẹ́fẹ́ èémí, ilé ìwòsàn náà kò ní pé Ọlọ́run ni kò pa òun.
Oríṣiríṣi ni àwọn nǹkan tí wọ́n kọ, wọ́n ní àwọn dọ́kítà ibẹ̀ máa ń dágunlá wọn kìí ṣe iṣẹ́ wọn bíi iṣẹ́, ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé wọn kò tọ́jú Toluwase ni.
Anake ti yí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí dànù pé irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ ni, àwọn dọ́kítà náà ṣe iṣẹ́ wọn àmọ́ ó padà já sí òfo.
Àwọn aṣojú ilé ìwé dúró sílé ìwòsàn títí àwọn ẹbí rẹ̀ fi dé wọ́n sì jọ sin òkú rẹ̀ ni. Anake bá àwọn ẹbí Toluwase kẹ́dùn, ó ṣe àpèjúwe ikú rẹ̀ bíi ọ̀fọ̀ ńlá – AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA CONVENANT KÚ SÍ ORÍ PÁPÁ ÌṢERÉ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ikú òjijì nílé ìwé ti ń wáyé lemọ́lemọ́ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí, akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé OAU kan náà ṣe bẹ́ẹ̀ di èrò ọ̀run láti ojú oorun. A mú ìròyìn náà wá pé:
Àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó fìkàlẹ̀ sí Ile-Ife ń dárò akẹ́kọ̀ọ́ kan tó sùn tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú láti ojú oorun.
A gbọ́ pé Timileyin Toromade; akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kẹta ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó sùn ní alẹ́ ọjọ́ Ajé kò sì padà jí sáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Timileyin, ìpele kẹta ló wà nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó àti iṣẹ́ abẹ.
Alukoro ilé ìwé náà; Abiodun Olanrewaju fi àtẹ̀jáde kan léde, nínú rẹ̀ ló ti sọ pé Timileyin kú ní nǹkan bíi aago méjì òru mọ́jú ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ìdí ni pé nǹkan bíi aago méjì òru náà ni akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣí ilẹ̀kùn fún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí wọ́n jọ ń gbé.
Ọ̀gá ilé ìwé náà; Ọ̀jọ̀gbọ́n Simeon Bamire bá àwọn ẹbí Toromade kẹ́dùn ọmọ wọn tó lọ, ó fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí wọn pé òun banujẹ́ gidi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Timileyin fi ara da gbogbo àdojúkọ tó rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó pẹ̀lú ìrètí pé yóò máa ṣe ìwòsàn fún àwọn èèyàn lọ́la àmọ́ kòkòrò kò jẹ́ kí a gbádùn obì tó gbó, ikú mú Timileyin lọ láàrín àwọn akẹgbẹ rẹ̀.
Ilé ìwé náà ṣe ìlérí àtiṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ohun tó le fa ikú Timileyin, wọ́n rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pàápàá àwọn akẹgbẹ́ Timileyin láti kún fún àdúrà fún mọ̀lẹ́bí akẹgbẹ́ wọn náà lásìkò yìí.
Òmíràn tó tún dàbí rẹ̀ ni ti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé NOUN tí òun náà fò ṣánlẹ̀ tó sì kú. A gbọ́ pé:
Michael Coker wà ní gbọ̀gán ìdánwò ní ẹ̀ka ilé ìwé náà tó wà ní Victoria Island, ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdánwò rẹ̀ ní ó ṣàdédé mú ìdí lọ sílẹ̀, ẹni tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ló pàdé rẹ̀ tó sì tẹ́ ẹ sílẹ̀. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ ṣúgbà rẹ̀ kí wọn ó ṣa aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ kan tó jẹ́ obìnrin ní kí wọn ó fi sílẹ̀ pé yóò dìde ó sì lé wọn padà sídìí ìdánwò wọn.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́rin tí Michael ti wà nílẹ̀ tí èémí rẹ̀ sì ń ṣe ṣégeṣège, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tún gbìyànjú àtiṣe aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ náà tún lé wọn padà. Nígbà tó lé ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún tí Michael ti wà nílẹ̀, olùkọ́ mìíràn wọlé wá ó sì wí pé àwọn ti pé nọ́ọ̀sì. Ó gba nọ́ọ̀sì náà ní ìṣẹ́jú márùn-ún mìíràn kí ó tó gbé Michael jókòó, lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣèt̀ àtigbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Bukola; ẹni tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àlàyé pé àwọn bèèrè bí Michael bá ní wárápá tàbí gìrì, wọ́n tilẹ̀ gbìyànjú àtifi ṣibí há a lẹ́nu àmọ́ olùkọ́ náà kò gbà.
Ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé Michael lọ kò gbà á, wọ́n darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn mìíràn àmọ́ Michael kú kí wọ́n tó dé ilé ìwòsàn kejì.
Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ parí ìdánwò ni wọ́n gbọ́ pé Michael Coker ti kú, wọ́n nàka àbùkù sí olùkọ́ náà pé òun ni kò jẹ́ kí wọn ó tètè ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Olùkọ́ mìíràn ní ilé ìwé náà tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun ṣe àlàyé pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò dákú tí yóò sì tún dìde. Ó wí pé púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni ó ní àìsàn lágọ̀ọ́ ara, òmíràn kò tilẹ̀ mọ̀ títí yóò fi wá dákú sí ilé ìwé tàbí nínú ìdánwò.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan ti dákú rí tó sì jẹ́ pé òògùn olóró tó mu ló fà á. Òmíràn ní gìrì, òmíràn ní ikọ́ọfe tí wọn yóò sì máa dákú.
Akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ èrò rẹ̀ pé òun kò lérò pé olùkọ́ náa mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe ìdíwọ́ fún ìtọ́jú Michael, ó lè jẹ́ pé ó kàn fẹ́ kí wọn ó fún un ní ààyè kí atẹ́gùn le fẹ́ síi. Ó ní òun kò sí nínú gbọ̀ngán lásìkò náà òun kàn gbọ́ ariwo ni.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ilé ìwòsán Bonny Camp tí wọ́n kọ́ gbé Michael lọ, dọ́kítà ibẹ̀ ní àwọn kò kọ Michael, àwọn darí rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn nítorí àwọn kò ní èémí tó nílò.




