Àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ yìí NCAA ti fi òfin de olórí ọmọ ọba Akile Ìjẹ̀bú tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Kwam1 fún oṣù mẹ́fà gbáko lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrín òun àti àwon òṣìṣẹ́ ValueJet ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikiwe ní Abuja.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde ni a ti rí Mayegun Marshall tó ń ṣe fàǹfà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ValueJet tí ó sì tún gbìyànjú àti dá ọkọ̀ òfurufú náà dúró nípa dídúró sí iwájú rẹ̀.
Awakọ̀ òfurufú náà kò torí náà má gbéra, díẹ̀ ló kù kí ìyẹ́ ọkọ̀ náà ó gbá Wasiu lórí.
Àlàyé tí àwọn aláṣẹ ValueJet ṣe ni pé Wasiu kọ̀ láti tẹ̀lé òfin ìrìnnà nípa pé ó kọ̀ láti gbé ike ọtí ọwọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
ValueJet wí pé òfin ni, ẹnikẹ́ni kò le wọ inú ọkọ̀ òfurufú pẹ̀lú ohun mímu, nítorí pé ó kọ̀ láti gbé e sílẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ náà kò ṣe gbà á láàyè àti wọ inú ọkọ̀ tó fi di ohun tí wọ́n jọ ń fà.
Ilé iṣẹ́ ValueJet ti dá àwọn awakọ̀ òfurufú náà méjì dúró náà nítori pé wọ́n rú òfin tó sọ pé àyíká gbọdọ̀ wà ní àlàáfíà kí wọ́n tó gbéra.
Fọ́nrán yìí ti tàn kálé káko, àwọn èèyàn sì ké sí ìjọba láti gbé e yẹ̀wò.
Ẹni tó jẹ́ adarí ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú ẹ̀ka NCAA; Micheal Achimigu ti sọ wí pé kò sí èyí tí yóò mú un jẹ nínú Wasiu Ayinde àti àwọn òṣìṣẹ́ ValueJet, ó wí pé àwọn ti fi òfin de Wasiu báyìí fún oṣù mẹ́fà gbáko, kò ní ní anfààní àti rin ìrìn àjò pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú.
Bákan náà ló wí pé àwọn ti kọ̀wé sí ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá láti fi òfin gbé Wasiu lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Festus Keyamo; ẹni tó jẹ́ mínísítà fún ìrìn àjò ojú òfurufú náà fèsì pé àwọn kò ní fi ààyè gba irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ẹni tó wù kó jẹ́. Ó pàṣẹ kí wọn ó fi òfin de Wasiu títí ìwádìí ó fi parí.
Nígbà tí àwọn èèyàn bèèrè lọ́wọ́ Achimigu pé ǹjẹ́ yóó ṣe é ṣe láti fi òfin gbé Wasiu tàbí fi ìyà jẹ ẹ́ lábẹ́ òfin nítorí pé ọ̀rẹ́ ni òun àti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Èsì tí Achimigu fọ̀ náà ni pé ààrẹ gan-an kò ní lọ́wọ́ sí rírú òfin nítorí pé òtítọ́ àti òdodo ni ààrẹ dúró fún.
Ohun tí Achimigu sọ nípa ààrẹ wa Bola Ahmed Tinubu yìí ni yóò gbé wa dé Àríwá lọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí wọ́n pe ara wọn ní Northern Progressive Coalition.
Ẹgbẹ́ NPC yìí ṣe àpèjúwe ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi èèyàn ire, bàbá dáadáa tí kò fẹ́ kí ìyà ó jẹ ọmọ.
Wọ́n ṣe àpèjúwe Tinubu gẹ́gẹ́ bíi olùgbàlà tí ó ń tọ́jú àwọn ní Àríwá.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ rèé:
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ariwa tí wọ́n pe ara wọn ní Northern Progressive Coalition ti sọ̀rọ sókè níbi ìpàdé tó wáyé lónìí pé kò sí ẹni méjì tí àwọn yóò dìbò fún lọ́dún 2027 ju ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ.
Àwíjare wọn náà ni pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe bẹbẹ fún àwọn ní Ariwa ní gbogbo ẹ̀ka, ó tún àwọn ilé ìwé ṣe, ó ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀yáwó-kàwé tí àwọn jẹ anfààní rẹ̀, ó pèsè iná, ó pèsè omi tó já geere, ó tún ṣe ètò ẹ̀kọ́ fún àwọn Almanjiri.
Ẹgbẹ́ NPC wí pé àwọn kò tíì gbádùn ìjọba kankan bíi ti Tinubu yìí rí, gbogbo nǹkan ni ó fi mú ayé rọrùn fún àwọn.
Usman Abdullahi, ẹni tí egbẹ́ NPC fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu ló ṣe àlàyé èyí, ó wí pé kò sí ẹni méjì tí àwọn yóò tún dìbò fún ju Tinubu lọ.
Yàtọ̀ sí àwọn ètò ẹ̀kọ́, oríṣìí àwọn iṣẹ́ àkànṣe bíi ọ̀nà tó yọ̀ kùlùlù, iná ọba tó ranjú kankan, oúnjẹ àjẹyó àjẹbì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ààrẹ ti pèsè fún àwọn.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti dá ìrètí àwọn tó ti sọnù láti ọjọ́ tó ti pẹ́ padà, àwọn ti ń gbé ayé ìrọrùn àti ìgbádùn, fún ìdí èyí, tewúré tàgùntàn Ariwa ni yóò fi ìdùnnú àti ayọ̀ dìbò fún Tinubu lọ́dún 2027.
Bí a bá wo ọ̀rọ̀ yìí lóòótọ́, ó jọ ara wọn nipa pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi owó bàǹtàbanta dá àwọn agbábọ́ọ̀lù obìnrin ilẹ̀ wa lọ́la, ó tún fún wọn ní ilé fún àṣeyọrí tí wọ́n ṣe.
Nígbà tí àwọn kan kan sárá sí Ààrẹ, àwọn kan tàbùkù rẹ̀ pé owó náà ti pọ̀jù.
Gbogbo ohun tí wọ́n wá ń sọ yìí pàápàá ohun tí egbẹ́ NPC sọ nípa ààrẹ Tinubu yìí lòdì sí ohun tí egbẹ́ òṣèlú PDP sọ nípa rẹ̀.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò rí Tinubu bí èèyàn ire rárá, ohun tí wọ́n sọ náà ni pé:
Ọmọ Nàìjíríà rere kan tí orí rẹ̀ sì pé dáadáa kò ní dìbò fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní ọdún 2027.
Akọ̀wé gbogbogbò ẹgbẹ́ náà; Debo Ologunagba ló bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nìkan ló le yẹ àga mọ́ Tinubu nídìí lọ́dún 2027.
Ó wí pé kò sí ibi tí a dé tí a kò ní bá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí pé ẹgbẹ́ tí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ni àti pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ń retí ìpadàbọ̀ ẹgbẹ́ naa.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé kò sí ẹni tí ó ń fojú winá ohun tí Tinubu ń ṣe fún wa lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí tí yóò wá ṣe àtìlẹ́yìn fún un ní sáà kejì.
Bákan náà ni ó mẹ́nuba bí àwọn olóṣèlú ṣe ń yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ náà.
Debo wí pé àwọn bán-kún-ẹgbẹ́ ni àwọn tí wọ́n ń yapa náà wọn kò sí nínú àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ náà, àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ náà wà ní digbí wọn kò yapa, nítorí náà, digbí ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP wà.
Ta ni ẹ̀yin wà pẹ̀lú nínú NPC àti PDP?




