Yorùbá bọ̀, wọ́n ní bá ò lẹ́gbẹ́ láyé, a kò le è lẹ́gbẹ́ lọ́run, Ìdí nìyí ti ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn Mùsùlùmi nílẹ̀ Nàìjíríà, MURIC tí Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA jẹ́ olórí wọn fọnmú, ó fi àáké kọ́rí, ó wù kẹ̀kẹ̀, ó sì kọ̀ jálẹ̀ nípa bí Ààrẹ wa àná, Ọ̀gágun IBRAHIM BABANGIDA ṣe gba adé ìdàború ti ọdún JUNE 12 1993 ṣí mọ́ ọn lórí. Bí ẹ ò bá gbàgbé, ọjọ kejilá, oṣù kẹfà ọdún 1993 ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ètò ìdìbò tó yanrantí jùlọ, gbogbo ọmọ Nàìjírà ló pawọ́pọ̀ dìbò yan Olóyè MOSHOOD KÁṢÌMAAWÒÓ ABÍỌ́LÁ lọ́dún náà lọ́hùn-ún sí ipò Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà.
Inú gbogbo ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà dùn yùngbà pé ìdẹ̀ra dé é , a bọ́ lóko ẹrú ológun.
Abẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú SDP; ìyẹn ẹgbẹ́ ẹlẹ́ṣin ni Olóyè Moshood Káṣìmáàwòó Abiola ti jáwé olùborí. Orín ẹ̀yẹ orílẹ̀ èdè wa ló dédé gbòde kan lórí rédíò àti ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Págà! Ìlù yí padà, orin ọ̀tẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ìjọba ológún IBRAHIM BABANGIDA ti dójú ìbò délẹ̀, ó fagilé ibò JUNE 12 1993, ni yánpọnyánrin bá bẹ̀rẹ̀. Ààrẹ SANNI ABACHA dìtẹ̀ gba ìjọba, Olóyè MOSHOOD KAṢIMAWÒÓ ABIOLA dèrò ẹ̀wọn, Akínkanjú Ayà rẹ̀, KUDI ABIOLA dolóògbé látàrí ìjà-n-gbara pé kí ọkọ rẹ̀ le è dórí alééfà tí gbogbo ìlú fọwọ́ sí fún un.
Lẹ́yìn ikú Ààrẹ SANNI ABACHA lọ́dún 1998 ni MKO náà di olóògbé tí àlá rẹ̀ kò si fi bẹ́ẹ̀ wá sí ìmúṣẹ. Ní báyìí, Ààrẹ àná, IBRAHIM BABANGIDA ti gbé ìwé kan jáde lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún lé méjì tí ó fi lọ́lẹ̀ lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù yìí, Àkọ́lé ìwé náà ni: ÌRÌNÀJÒ MI LẸ́NU IṢẸ́. TRANSCORP HILTON tó wà ní olú ìlú ilẹ̀ Nàìjíríà ni àwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ wa péjú-pésẹ̀ sí fún ìfilọ́lẹ̀ ìwé Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA lọ́jọ́bọ ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Bílíọ́nù mẹ́tàdínlógún ni wọ́n fi ṣíde ìwé náà. Gbogbo àwọn èèyàn jànkànjànkàn, olóṣèlú àti ọ̀tọ̀kùlú ló wà ní ìkàlẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá. Ibi ayẹyẹ ìfisọrí ìwé ni Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA ti jẹ́wọ́ pé òun ló ṣe atọ́nà àti màdàrú bí àjọ ètò ìdìbò ìgbà náà, FEDECO fi fagilé ìbò tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà gbà pé ó yanrantí jùlọ nílẹ̀ yìí, IBRAHIM BABANGIDA kò fa ẹni tá a fìbò yàn kalẹ̀, ìyẹn Olóyè MOSHOOD ABÍỌ́LÁ KÁṢÌMAWÒÓ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ titun nígbà náà, ó dojú ìbò ọdún JUNE 12 1993 dé porongodo.
Lọ́jọ́ ìsinmi tó kọjá, ọjọ́ kẹtàlá oṣù yìí ni ọ̀gá àgbà àti olùdarí ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA kéde pé òun tako bí Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA ti jẹ́wọ́ ìfagílé ìdìbò JUNE 12 1993.
Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní kí IBRAHIM BABANGIDA má fi búrẹ́dì kówa lọ́bẹ̀ jẹ nítorí ẹni tí adé ìwà ìbàjẹ́ náà ṣímọ́ lórí jù ni ọ̀gágun SANNI ABACHA fún ìfagilé ètò ìdìbò JUNE 12 1993.Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOL
A ní kí gbogbo ọmọ ilẹ̀ yìí máa ṣe ìrántí Akọni olóyè MKO ABIOLA, aya rẹ̀; KUDIRAT ABIOLA àti ALFRED REWANE. Ọ̀jọ́gbọ́n tún ké tantan sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti má ṣe gbàgbé ọgbẹ́ ọkàn àti ìfẹ̀tọ́-ẹni-dunni tí ètò ìdìbò JUNE 12 1993 dá sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní àṣìṣe ìtàn ni èyí àti pé Ààrẹ BABANGIDA IBRAHIM ń gé ìka àbámọ̀ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìdìbó JUNE 12 1993, Ó ní SANNI ABACHA ló lo ọwọ́ agbára gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ nígbà náà láti dojú ìbò JUNE 12 1993 bolẹ̀. Àwọn èrò wọnyìí ló mú Ọ̀jọ̀gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA rú láti fẹ́ tún ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ kọ, ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọgbọ́n àrékérekè láti wẹ ara rẹ̀ mọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ ọjọ́ pípẹ́ náà ni èyí. Ọ̀jọ̀gbọ́n nà ìka àbùkù sí Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA fún dída omi àlàáfíà ilẹ̀ Nàìjíríà rú láti ọjọ́ pípẹ́, Ó ní Ààrẹ kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ní àlá rere sí ètò ìdìbò ilẹ̀ yìí mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti fojú winá ìfagilẹ́ ètò ìdìbò JUNE 12 1993 tí gbogbo àwọn ènìyàn gbà pé òunni ètò ìdìbò tó yanrantí tó sì pegedé jùlọ, Olóyè MKO ABIOLA ló jáwé olúborí ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe màdàrú rẹ̀, wọ́n fi ọwọ́ ọlá gbá ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà lójú, wọ́n sì da ètò ìdìbò JUNE 12 1993 rú porongodo.
Ẹgbẹ́ MURIC tún bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ọ̀tọ̀kùlú èèyàn jànkànjànkàn ilẹ̀ yìí ti ṣùgbá ìwà láabi àti ìdọ̀tí tó kún inú ìwé náà, tí wọ́n sì ń gbé e gẹ̀gẹ̀ bí ohun rere kan báyìí. Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu tó fi igi gún egbò ọjọ́ pípé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùfọkànsìn ilẹ̀ yìí nítorí ṣe là ń gbé ẹni ibi gẹ̀gẹ̀ tá a wá sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.
Àjọ MURIC na ìkà àbùkù bá Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA nítorí ìjọba rẹ̀ ló fi ilẹ̀ Nàìjíríà sí oko gbèsè ọdúnmọ́dún, ìjínigbé, ìpayínkeke, ìdàrúdàpọ̀, ìfẹ̀tọ́ọ́mọnìyàn-dunni, ìjíàpótí-ìdìbò-gbé, ikú oró, dídu oyè olóṣèlú tí kò tọ́ sí ni, fífi ìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀ lọ́nà àìtọ́ abbl.
Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní kí gbogbo ọmọ ilẹ̀ yìí máa ṣe ìrántí Akọni olóyè MKO ABIOLA, aya rẹ̀; KUDIRAT ABIOLA àti ALFRED REWANE. Ọ̀jọ́gbọ́n tún ké tantan sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti máa ṣe gbàgbé ọgbẹ́ ọkàn àti ìfẹ̀tọ́-ẹni-dunni tí ètò ìdìbò JUNE 12 1993 dá sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àwọn òǹkọ̀wé ti kọ oríṣìí àwọn ìwé nípa àsìkò ìṣejọba Babangida yìí kí òun gan-an tó kọ fúnra rẹ̀.
Òǹkọ̀wé èdè Yorùbá kan tilẹ̀ wà, ìwé márùn-ún ni Alàgbà yìí kọ lédè Yorùbá láti fi ṣe àpèjúwe ohun tí àwùjọ wa ń là kọjá lákòókò ìjọba ológun tí Babangida ń darí
* Ẹkún Elédùmarè ( Ewì ni)
*Pápá ń jó. ( Ewì ni)
* Dìgbòlùjà. ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
* Pelemọ. ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
* Kannakánná ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
Gbogbo àwọn ìwé yìí ni Débọ̀ Awẹ́ fi ṣàpèjúwe pọ́nǹpọ́nnáyan tójú ọmọ Nàìjíríà rí lásìkò tí Màràdónà wà lórí ìjọba. Àsìkò Jẹnẹra Babangida kò sanmọna fọ́mọ orílẹ̀-èdè yìí rárá ni. Àléébù rẹ̀ pọ̀ ju àǹfààní rẹ̀ lọ.