ABUCHI PA ÌYÀWÓ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS – Ọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Abuchi ti ń ṣẹ́jú pàkò lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekú pa ìyàwó rẹ̀.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ni pé kọmíṣọ́nà gan-an ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn ará abúlé Amaji ló fa Abuchi lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ lẹ́yìn tó ṣekú pa ìyàwó rẹ̀. Inú oko ni wọ́n wà tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, Abuchi àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tahùn síra wọn nígbà tí wọn kò gbọ́ ara wọn yé mọ́, ọkọ kò ṣe méní ṣe méjì, ó mú ọ̀bẹ ó sì fi gún ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn.
Ariwo obìnrin yìí ló pe àwọn tí wón wà lóko, Abuchi kò fi obìnrin náà sílẹ̀, ó jókòó lé e ó sì ń gún un lọ́bẹ lọ, wọ́n gba obìnrin náà kalẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ wọ́n sì fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Àwọn ojú ọgbẹ́ náà burú tó bẹ́ẹ̀ tí ìyàwó Abuchi fi kú lójú ẹsẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ya àwọn ara abulé lẹ́nu, wọn kò le sọ ohun tó fa irú ìwà bẹ́ẹ̀ nítorí Abuchi àti ìyàwó rẹ̀ kìí jà.

Itokasi Aworan : PunchNG
Ní báyìí, Abuchi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá títí di ìgbà tí yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn ìpànìyàn mìíràn láti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pé:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá Ọ̀yọ́ ti tẹ àwọn méjì kan tí wọ́n ṣekú pa ìyá àgbà kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ìyá àgbà ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta ni ìyá tí wọ́n ṣekú pa náà ní agbègbè Orí àpata, Oderemi ní ìjọba ìbílẹ̀ Ido, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ẹnìkan tó ń lọ sí oko ló kan òkú náà nílẹ̀ níbi tó wú bàǹtù sí ní àbáwọ̀lú. Kíá ni wọ́n ti ránṣẹ́ sí àwọn ọlọ́pàá.
Ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ tó jìn ni wọ́n bá lọ́rùn ìyá náà yóò sì ti tó ọjọ́ méje tí wọ́n ti pá sí ibẹ̀. Ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú àwọn afurasí méjì náà tí orúkọ wọn jẹ́; Muhammed Sanusi àti Ogbu James. Ẹni ọdún méjìlélógójì ni Sanusi nígbà tí James jẹ́ ẹni ogójì ọdún.
Olayinka Ayanlade; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde, ó wí pé àwọn ti tari ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka CID tí yóò ṣe ìwádìí rẹ̀ délẹ̀, wọ́n sì ti fa àwọn afurasí méjéèjì náà fún wọn pẹ̀lú. Ìlú Oderemi ni àwọn afurasí náà ń gbé, wọn kìí ṣe àjòjì rárá, èyí ló mú ìpayà bá àwọn ará àdúgbò náà pé ǹjẹ́ irú rẹ̀ kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́?
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé irú rẹ̀ kò tún ní wáyé mọ́ nítorí pé àwọn yóò mú kí ètò ààbò ó nípọn lágbègbè náà.
Ó ṣe pàtàkì láti kọ nípa ọ̀daràn paraku tí ọwọ́ tẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Anambra:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti tẹ afurasí ọ̀daràn kan tó jẹ́ ògbólògbó tí wọ́n ti ń wá láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Gbogbo ìpànìyàn, ìjínigbé, òògùn olóró àti àwọn ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ ní Urum kò le ṣẹ̀yìn Ndibe Onyenwe.
Ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta ni Ndibe, ó ti pẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá ti ń ṣọ́ ọ àmọ́ ó máa ń yọ́ àfi bíi aláyúm̀bẹ́rẹ́ títí di ìgbà tí ọwọ́ wọn tẹ̀ ẹ́ yìí.
Níbi tó le dé, àwọn ọlọ́pàá kò ríi mú, àwọn ológun ló lọ pàdé rẹ̀ níbi tó ti ń pitú ọwọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì mú un, wọ́n fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ fún ìwádìí àti ìjẹ́jọ́ rẹ̀.
Ọjọ́ karùn-ún, oṣù Èrèlé ni àwọn ọlọ́pàá tẹ́wọ́ gba Ndibe lọ́wọ́ àwọn ológun. Òun àti Felix Godwin ni wọ́n jọ lọ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn, Felix ti sá lọ ní tirẹ̀ àmọ́ ọta ìbọn mú Ndibe sílẹ̀.
Ojú pópó Urum ni wọ́n lọ lọ́jọ́ náà pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wá wọn, wọ́n dá àwọn èrò ọ̀nà dọ̀bálẹ̀ wọ́n sì ń jà wọ́n lólẹ̀, wọn kò bá jí wọn gbé àmọ́ àwọn ológun bá wọn lálejò.
Ndibe jẹ́wọ́ pé Felix ló gba àwọn adigunjalè wá láti Ayamelum tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ náà. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà ni ó san fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn adigunjalè mẹ́rẹ́ẹ̀rin náà owó ọ̀yà.
Bákan náà ni Felix fún Ndibe lówó láti ra ọta ìbọn tí iye rẹ̀ dín ní irinwó ẹgbẹ̀rún fún iṣẹ́ náà. Àwọn èèyàn mẹ́fa ni wọ́n yìnbọn pa níbi ìkọlù ọjọ́ náà nígbà tí àwọn mìíràn wà nílé ìwòsàn báyìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò dẹ́kun àwọn ọ̀daràn ní agbègbè Urum.
Lórí ikú Patrick, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ̀rọ̀ sókè:
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa ti fi ọkùnrin kan léde pé àwọn ń wá a lórí ẹ̀sùn pé ó lọ́wọ́ nínú ikú tó pa ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní ìpínlẹ̀ náà. Ẹni tí wọ́n ń wá náà ni Bodmas Kemepadei, ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú rẹ̀ kàn án náà ni Patrick Peresuodei.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Patrick, àwọn ẹbí rẹ̀ ló ké gbàjarè síta pé Bodmas ló ṣekú pa Patrick látàrí pé ó fi àwọn ẹ̀ṣọ́ NSCDC gbé e tí wọ́n sì lù ú títì tó fi padà kú lẹ́yìn tí wọ́n fi sílẹ̀.

ItokasI Aworan : PunchNG
Àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ ni a mú wá nígbà náà pé:
Àwọn ẹbí Patrick Peresousdei ti fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé wọ́n fi ìyà jẹ Patrick títí tó fi kú.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Patrick, ọjọ́ kẹfà tó dé láti àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ló dágbére fáyé. Àbúrò rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Destiny Peresousdei ló jáde fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n ṣe òun àti Patrick mọ́kumọ̀ku tí wọ́n sì tún tì wọ́n mọ́lé, èyí ló fa àárẹ̀ sí Patrick lára tó sì gba ibẹ̀ kú.
Àwọn ọ̀dọ́ Yenagoa ti faraya, wọ́n jáde ṣe ìwọ́de pé kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe àlàyé ikú tó pa Patrick.
Àlàyé tí Destiny ṣe ni pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bodmas Kemepadei ló kó àwọn ẹ̀ṣọ́ NSCDC wá ká òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ́lé, Badmus ní Patrick ń dúnkokò mọ́ òun, àwọn NSCDC bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú àti Destiny. Wọ́n wọ́ àwọn méjéèjì sínú ọkọ̀ Bodmas ó dilé rẹ̀. ibẹ̀ ni wọ́n ti jẹ ìyà àjẹbólórí, wọ́n lù wọ́n bíi aṣọ òfì àfi bíi bẹ̀m̀bẹ́, lẹ́yìn ìyà ọlọ́sẹ̀ kan ni wọ́n dá Destiny sílẹ̀ wọ́n sì mú Patrick lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, àwọn ọlọ́pàá náà lù ú títí tó fi bẹ̀rẹ̀ àárẹ̀.
Bodmas náà ló pè wọ́n kí wọ́n wá gbé e, nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ti pàdé, wọ́n wọ́ Patrick jù sílẹ̀ wọ́n sì bá tiwọn lọ. Patrick kò le sọ̀rọ̀, kò le gbápá tàbí gbé ẹsẹ̀, àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé e lọ kò ríi tọ́jú títí tó fi padà kú lọ́jọ́ kẹfà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Bayelsa ti fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Musa Muhammad pé Patrick ti fi ara pa kí ó tó dé ọ̀dọ̀ wọn, Musa ní àwọn gba àkọsílẹ̀ Bodmas àti àwọn yòókù àmọ́ ara Patrick kò dá kò sì le è kọ àkọsílẹ̀ ni wọ́n bá kúkú gbé e lọ sílé ìwòsàn níbi tí àwọn dọ́kítà ti wí fún wọn pé kí wọn ó yọ̀ǹda rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀ fún ìtọ́jú tó péye. Ọ̀sẹ̀ kejì tí àwọn dá a sílẹ̀ ni àwọn gbọ́ pé ó ti kú.
Ikú patrick yìí ti bí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn, àwọn ọ̀dọ́ ti jáde bèèrè lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọn ó ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ ṣáájú àsìkò yìí.
Ní báyìí, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa; Iyamah Edebor ló fèsì pé àwọn ti tẹ́ ìwé ìpẹjọ́ síwájú adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ náà láti pe Bodmas wá jẹ́jọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti kéde Bodmas Kemepadei ní ẹni tí wọ́n ń wá báyìí ki ó wá jẹ́jọ́ ikú tó pa Patrick. Ẹni tó bá kófìrí Bodmas Kemepadei kó ta àwọn ọlọ́pàá lólobó nítorí wọ́n ń wá a.




