Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀rí; Nasir El-Rufai ti fèsì sí awuyewuye tó ń lọ lórí ìtàkùn ayélujára pé òun bá ọ̀rọ̀ òṣèlú lọ sí ilé ààrẹ àná; Muhammadu Buhari lẹ́yìn tí òun ti yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
El-Rufai fèsì sí èyí pé irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni o pé oúnjẹ òsán lásán ni òun yà jẹ ní ilé ààrẹ àná; Muhammadu Buhari. Ó ṣe àlàyé pé òun àti ikọ̀ òun ń bọ̀ láti mọ́ṣáláṣí tó wà ní òpópòná Yahaya níbi tí àwọn ti kí irun Jímọ̀, àwọn yà ní ilé Muhammadu Buhari láti ṣe é ní pẹ̀lẹ́ kí àwọn sì kí olùtọ́ni àwọn ìyẹn Muhammadu Buhari.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé kí àwọn olólùfẹ́ òun ó má mikàn nítorí pé òun kò le padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó ní kí wọn ó máa bá òun lọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP tí òun wà báyìí.
Ohun tó bí ọ̀rọ̀ yìí ni àbẹ̀wò tí El-Rufai àti àwọn àgbà olóṣèlú lọ ṣe sí Muhammadu Buhari lọ́jọ́ Ẹtì ní ilé rẹ̀ tó wà ní Kaduna. A rí igbákejì ààrẹ ìjẹrin; Atiku Abubakar tó ṣaájú àwọn èèyàn náà wọ inú ilé Buhari. Lára àwọn tí wọ́n jọ kọ́wọ̀ọ́ lọ ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀rí; Nasir El-Rufai, Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto tẹ́lẹ̀rí; Aminu Tambuwal, Mínísítà fún àtẹ̀jạde tẹ́lẹ̀rí; Isa Pantami, Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo tẹ́lẹ̀rí; Achike Udenwa, Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue tẹ́lẹ̀rí; Gabriel Suswam àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa tẹ́lẹ̀rí; Jibirlla Bindow.
Gbogbo wọn ní wọ́n ti di ipò òṣèlú mú tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n sì lọ ilé ààrẹ tẹ́lẹ̀rí, a kò mọ ohun tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀rí àmọ́ Gómìnà Kaduna tẹ́lẹ̀rí wí pé nǹkan kan kò tẹ́lẹ̀rí àbẹ̀wò náà.
Ohun tó fà á tí àbẹ̀wò yìí fi mú awuyewuye lọ́wọ́ ni kíkúrò tí El-Rufai kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́, ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP, wọ́n bèèrè pé ibi a bá ń lọ ló yẹ ká kọjú sí, èwo ni òṣákáláṣokolo?
Ní báyìí, El Rufai ti fúnra rẹ̀ fèsì pé kíkúrò tí òun kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ní kí Buhari ó má jẹ́ olùtọ́ni òun mọ́, kódà, Buhari fi ọwọ́ síi kí òun ó kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Muhammadu Buhari kò sọ ohunkóhun nípa ìṣípòpadà El Rufai, kò sọ bí òun fọwọ́ sí ẹgbẹ́ òṣèlú SDP àbí òun kò fọwọ́ sí i àmọ́ ó sọ yéké pé alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni òun lọ́jọ́kọ́jọ́.
Ìdí tí El-Rufai fi kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ẹ̀ṣẹ́ kìí déédé ṣẹ́, gbogbo wa la mọ̀ bẹ́ẹ̀, El-Rufai ṣe àlàyé ohun tó mú un kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́. Ó wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ iyán òun kéré, wọn ò tún fewé bò ó, ó wí pé òun wà lára àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun dọjọ́ alẹ́ láìmọ̀ pé ṣe ni wọn yóò já òun kulẹ̀ lójijì.
El-Rufai ní àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú náà kò ka àmọ̀ràn òun kún rárá, gbogbo ọ̀rọ̀ òun kò tà létí wọn, ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé ìlú tí wọn kò bá ti fẹ́ni, a kìí dárin níbẹ̀. Ìdí rèé tí òun fi digbá dagbọ̀n òun kúrò nínú ẹgbẹ́ náà lọ sí inú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun.
El-Rufai ṣe ìlérí pé òun yóò kó àwọn èèyàn jọ láti dìbò tako ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027.
Èsì ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọ̀rọ̀ yìí bọ́ sí àpò ìbínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọ́n fèsì pé yíyapa rẹ̀ ò tu irun kan lára wọn, wọ́n láwọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé èèyàn kúrò rárá.
Wọ́n wí pé kò sọ́rọ̀ nínú ohun tó sọ pé òun yóò kó àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú jọ láti dìbò tako ìyànsípò Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027, wọ́n lọ́rọ̀ rírùn ni.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé kò sí àwọn èèyàn tí El-Rufai le kó jọ tó le pa ìdìbò ọdún 2027 lára nítorí pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu náà ni yóò wọlé.
Wọn kò ṣàì má mẹ́nuba pé àmọ́ lọ̀rò El-Rufai kò mọ́ ara ẹran àti pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ rẹ̀, kò tó ohun tí àwọn ó máa wá yọ àdá sí.
Ọ̀rọ̀ yìí wá dà bí orin tí wọ́n máa ń kọ pé bí yó lọ kó lọ, ìgbà tí ò lọ kí ló ṣe?
Yípaya kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí, àwọn olóṣèlú tó ti digbá dagbọ̀n wọn kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC pọ̀ díẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola náà; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Òṣun ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ẹ̀sùn tí El-Rufai fi kàn ẹgbẹ́ náà ni Aregbesola náà fi kàn wọ́n.
Ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti jọba nínú ìdúnkokò mọ́ni, ìjẹgaba ati ìfìyàjẹni. Ìdí rèé tó fi kúrò nínú ẹgbẹ́ náà.
Ajá kìí lọ kí kolokolo rẹ̀ ó gbélẹ̀, ní kété tí Rauf Aregbesola fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ ni àwọn ajọ tó so mọ́ ọn náà ti káńgárá wọn kúrò.
Jandor; ẹni tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ AbdulAzeez Adediran náà ti ta kọ́sọ́ padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́yìn fà-n-fà díẹ̀ tó wáyé láàrín òun àti Bode George.
Jandor kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ díje dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, a kò le sọ pàtó ohun tó mú un padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC àmọ́ ohun tó dájú ni pá ààjò kò le dàbí ilé àti pé ilé baba ọmọ ni APC jẹ́ fún un, kò gbọdọ̀ bà á lẹ́rù.
Discussion about this post