Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti sọ̀rọ̀ lórí yíyapa tí El-Rufai yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP. Wọ́n wí pé kò tu irun kan lára wọn, wọ́n láwọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé ó kúrò rárá.
Wọ́n wí pé kò sọ́rọ̀ nínú ohun tó sọ pé òun yóò kó àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú jọ láti dìbò tako ìyànsípò Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027, wọ́n lọ́rọ̀ rírùn ni.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé kò sí àwọn èèyàn tí El-Rufai le kó jọ tó le pa ìdìbò ọdún 2027 lára nítorí pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu náà ni yóò wọlé.
Wọn kò ṣàì má mẹ́nuba pé àmọ́ lọ̀rò El-Rufai kò mọ́ ara ẹran àti pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ rẹ̀, kò tó ohun tí àwọn ó máa wá yọ àdá sí.
Ọ̀rọ̀ yìí wá dà bí orin tí wọ́n máa ń kọ pé bí yó lọ kó lọ, ìgbà tí ò lọ kí ló ṣe? —-
Àná ni El-Rufai, ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tó sì tún jẹ́ èèkan nínú ẹgbẹ́ náà kọ̀wé ìyapa ṣọwọ́ sí ẹgbẹ́ náà pé òun kò bá wọn ṣe mọ́, ó tó gé, àlubàtá kò tún gbọdọ̀ máa dárin. El-Rufai wí pé òun ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP níbi tí òun yóò ti ní àǹfààní àti gòkè àgbà.
Ẹ̀sùn tó fi kan ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni pé wọn kọ iyán òun kéré, wọn ò tún fewé bò ó, ó wí pé òun wà lára àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun dalẹ́ láì mọ̀ pé ṣe ni wọn yóò já òun kulẹ̀. Ó ní àwọn adarí ẹgbẹ́ náà kò ka àmọ̀ràn òun kún rárá, gbogbo ọ̀rọ̀ òun kò tà létí wọn, ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé ìlú tí wọn kò bá ti fẹ́ni, a kìí dárin níbẹ̀. Ìdí rèé tí ó fi yapa lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun.
El-Rufai ṣe ìlérí pé òun yóò kó àwọn èèyàn jọ láti dìbò tako ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti wá fèsì báyìí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò le mu àwọn lómi nítorí pé balùwẹ̀ rẹ̀ tó fẹ́ kún ju odò lọ, irọ́ lásán ni.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́nu lọ́lọ́ yìí le díẹ̀, ọ̀rọ̀ ìyọnípò Obasa kò tíì yanjú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti dá a padà sípò náà, ẹjọ́ ṣì wà níle ẹjọ́ gíga ti Ìkẹjà ní ìlú Èkó.
Adájọ́ Oluwakemi Pinheiro ti fi ìgbẹ́jọ́ lórí ẹjọ́ tí Olóyè Ọbasá tí í ṣe abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ Așòfin Ìpínlẹ̀ Èkó pè sí ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún yìí, 17th March, 2025. Ọ̀rọ̀ yìí wá dà bí egbìnrìn ọ̀tẹ̀; bí a ti ń pàkan nìkan ń rú, a ní ká jèkuru ọ̀ràn kó tán láwo , a tún ń gbọn ọwọ́ rẹ̀ sínú àwo. Ọbasá ti pe ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án kí wón tóó yọ ọ́ nípò abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ Așòfin.
Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan abẹnugan náà ni ìwà jẹgúdú-jẹrá; Ọwọ́ líle ; ṣíṣí ipò lò àti ọ̀kẹ́ àìmọye ìwà burúkú mìíràn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ní abẹnugan Ọbasá ń hù. Àwọn tí Olùpèjọ́ fẹ̀sùn kàn ni àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ Așòfin ; abẹnugan tẹ́lẹ̀, ìyẹn Mojísọ́lá Meranda. Ohun ìyanu tó tún ṣẹlẹ̀ ní kóòtù ni pé Olóyè Ọbasá kàn ṣàdédé pààrọ̀ agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fún un láìtẹ̀lé ìlànà tó tọ́ àti ìlànà tó yẹ.
Èyí ló fún Olúṣọlá Ìdòwú lóore-ọ̀fẹ́ láti kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣojú fún ilé ìgbìmọ̀ Așòfin nínú ìgbẹ́jọ́ náà. Àmọ́, èyí gbún Fálànà nínú, tó sì mú un tako ìgbésẹ̀ tí Ọbasá gbé yìí. Nínú èrò rẹ̀, Fálànà ní ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn fààyè gba kí adájọ́ ilé-ẹjọ́ gbọ́ àwíjàre tó ní í ṣe pẹ̀lú àyípadà amòfin kan tó ń ṣojú ẹlẹ́jọ́ kí ó tó di pé wọ́n tún lè fààyè gba àwíjàre mìíràn.
Adájọ́ Oluwakemi Pinheiro wáá fòté lé e pé kí gbogbo àwọn tí Ọ̀rọ́ kàn ó pèsè ìwé àwíjàre wọn, kí wọ́n sì fi í ṣọwọ́ sí ilé-ẹjọ́ kó tóó di ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ gan-an, ìyẹn ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹta ọdún 2025 yìí.
Ti Obasa òkan, ṣebí ẹ mọ̀ pé Rauf Aregbesola náà ti ganu kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn, ohun tí a ń gbọ́ nígboro ni pé ó fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria èyí tí Rabiu Musa Kwankwaso dá sílẹ̀.
Ìdí ni pé ó ṣe ìpàdé ìdákọ̀kọ̀ pẹ̀lú Rabiu Kwankwaso nílé rẹ̀ tó wà ní Èkó. Ohun tí wọ́n jọ sọ níbi ìpàdé náà kò hàn síta, àwọn èèyàn fura pé bóyá Aregbesola fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ni.
Ẹnìkan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun wí pé ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìdàgbàsókè náà ni wọ́n jọ sọ.
Ohun tó fàá tí àwọn èèyàn fi ń lẹtí mọ́ ìgànná lórí ìpàdé náà ni pé Aregbesola ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwọn ikọ̀ rẹ̀ náà bíi Ọmọlúàbí Progressive group ti yapa kúrò lára ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ohun tí ó fẹ́ ṣe báyìí.
Ohun tí ó fàá tí Aregbesola fi kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ sẹ́yìn ni ìdúkokòmọ́ni, ìjẹgàba àti ìfìyàjẹni tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà.
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun; Dọ́kítà Tosin Odeyemi fún àwọn akọ̀rọ̀yìn ní àwọn àwòrán ìpàdé náà níbi tí Aregbesola àti Kwankwaso ti jókòó pọ̀. Odeyemi wí pé kí Nàìjíría ó le dára náà ni wọ́n sọ̀rọ̀ lé lórí.
Ó jọ gáté kò jọ gáté, ẹsẹ̀ méjéèjì ló fi lélẹ̀ gátegàte. Àwọn tó ń yapa wí pé wọ́n ń fara ni àwọn, àwọn adarí wí pé kò rí bẹ́ẹ̀, ẹ gbọ́, báwo ló ṣe rí?