Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pàṣẹ kí ilé ìwé gíga aládàáni Nok ótó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna ó paradà di ti ìjọba àpapọ̀ lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀.
Àná ni ìkéde yìí jáde láti ilé iṣẹ́ ààrẹ pé ìlérí tí ààrẹ ṣe ló ti mú ṣẹ yìí o.
Agbègbè Kachia ní Gúúsù ìpínlẹ̀ Kaduna ni ilé ìwé Nok yìí wà. Igbákejì ààrẹ; Kashim Shettima ló kó àwọn ìwé ìgbẹ́sẹ̀lé náà fún àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ní ààfin ààrẹ tó wà ní Abuja lánàá.
Ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní Abuja ló pàṣẹ kí ilé ìwé gíga Nok náà ó di ti ìjọba àpapọ̀, ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi òǹtẹ̀ lùú. Ààrẹ pàṣẹ kí wọ́n yí orúkọ ilé ìwé náà padà kúrò ní Nok varsity sí Federal University of Applied sciences lẹ́kẹ̀sẹsẹ̀.
Shettima ṣe àfikún àlàyé pé ìṣèjọba tó wà lóde nísìn yìí kò fààyè gba rẹ́dẹrẹ̀dẹ.
Igbákejì ààrẹ kò ṣàì má dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹni bí ẹni èèyàn bí èèyàn tí wọ́n jẹ́ kí àtúntò náà ó wáyé, àwọn náà ni ajagunfẹ̀yìntì Martin Luther Agwai, Alàgbà Matthew Kukah, adájọ́ Kumai Akaahs àti sínétọ̀ Sunday Marshall.
Shettima gbé oríyìn fún àwọn èèyàn náà lórí ipa wọn láti mú kí àlàáfíà ó jọba ní agbègbè náà.
Bákan náà ló ké sí mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ láti mú àṣẹ ààrẹ ṣe nípa ṣísètò àbá ìṣúná fún sáà titun èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Ọ̀wẹ̀wẹ̀ ọdún yìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tí yóò gbà wọlé.
Ó kù nìbọn ń ró, ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni nínú àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tí ó ti ṣètò kalẹ̀ fún ìpínlẹ̀ Kaduna. Kódà, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ lórí àwọn títì ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna náà ganu sí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ṣáà ní fárí lẹ́yìn olórí. Gómìnà Uba Sani dúpẹ́ ribiribi lọ́wọ́ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ilé ìwé gíga titun yìí. Gómìnà Sani wí pé òun dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Shettima fún mímọ̀ rírì iṣẹ́ tí òun ṣe ní ìpínlẹ̀ Kaduna. Ó ṣe àlàyé pé òun yóò tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ọ̀gá ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa, Ọ̀gágun Musa Christopher wí pé òṣùbà ràbàǹdẹ ló yẹ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ìgbésẹ̀ akọni yìí, ó wí pé ilé ìwé yìí kìí ṣe fún àǹfààní àwọn ará Kaduna nìkan, gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni yóò ní anfààní láti kàwé ní ilé ìwé ìjọba yìí.
Ọ̀gágun Musa fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní ìfẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí dọ́kàn, ẹ̀rí kan pàtàkì ni ilé ìwé yìí jẹ́.
Kìí ṣe òní ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti máa ń fi han àwọn ọmọ Nàìjíría pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, kìí sì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n, ìfẹ́ àtọkànwá ni ààrẹ ní sí wa.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí nìgbà tí nǹkan yi bóbó fún àwọn ọmọ Nàìjíría, ààrẹ fi wá lọkàn balẹ̀ pé ìkòkò tí yóò jata, dandan ni kí ìdí rẹ̀ ó jata. Ọ̀rọ̀ tí ààrẹ sọ náà ni pé gẹ́gẹ́ bíi adarí tí ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú rẹ̀ jẹ lógún tó sì mumú láyà rẹ̀, ààrẹ ní gbogbo ohun tí ó ń lọ nílǔ ni òun mọ̀ o.
Lórí owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí ààrẹ yọ; Tinubu ní òun kò kábàámọ̀ rárá pé òun gbọn owó ìrànwọ́ náà yọ. Ìdí ni pé àwọn aláṣẹ lórí epo bẹntiróòlù ń lọ ta epo bẹntiróòlù wa ní àwọn orílẹ̀-èdè tó tì wá lówó pọ́ọ́kú nítorí pé ìjọba Nàìjíría ti san owó ìrànwọ́.
Tinubu sàlàyé pé ohun tó dára fún Nàìjíría lásìkò yìí ni oun ṣe o, ìdí ni pé àwọn owó tí ó yẹ kí Nàìjíría fi dàgbà sókè ló ti fi san owó ìrànwọ́ orí epo láìní àdápamọ́ kankan fún ìran tó ń bọ̀.
Ààrẹ wí pé lóòótọ́ ni nǹkan gbówó lérí làtàrí owó ìrànwọ́ ti òun yọ yìí, ohun tí àwọn ọmọ Nàìjíría nílò ni láti kọ́jú mọ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì fún ìgbé ayé kí wọn ó fi afẹfẹyẹ̀yẹ̀ a ń kọ́lé ogún a ń ra ọkọ̀ ọgbọ̀n sílẹ̀ náà. Ó ya ààrẹ lẹ́nu bí àwọn èèyàn ṣe ń ra àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnnì olówó iyebíye lásìkò tí Nàìjíría ń bọ́ sípò yìí.
Tinubu kò ṣàì má mẹ́nuba ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹnipa tó wáyé ní Ibadan, Anambra àti Abuja. Ààrẹ bá àwọn tí wọ́n pàdánù èèyàn wọn kẹ́dùn ó sì dá àwọn tí wọ́n ṣe ètò rẹ̀ lẹ́bi pé bí wọ́n bá ní ètò ni, irú ìjàmbá náà kò ní wáyé. Ó ṣe àpẹẹrẹ pé ó ti lé ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tí òun ti ń fún àwọn èèyàn ní oúnjẹ àti owó nílé òun, ṣé ẹ gbọ́ pé ìtẹnipa wáyé rí? Nítorí pé àwọn ní ètò ni.
Wọ́n bi ààrẹ léèrè pé báwo ni ìgbógun ti ìwà àjẹbánu ṣe ń lọ sí? Èsì tí ààrẹ fọ̀ ni pé ìṣèjọba òun yóò ríi dájú pé ìwà àjẹbánu di ohun ìgbàgbé, kò sí ààyè fún ìwà jẹgúdújẹrá, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ajeegunjẹran kò ní anfààní nínú ìṣèjọba tó wà lóde nísìn yìí.
Lára àwọn ọ̀nà tí ààrẹ fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti má baà hùwà ìbàjẹ́ ni ṣíṣe àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́, ètò ẹ̀yáwókàwé, àdínkù nínú owó oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣé ẹ̀yin náà wá ríi pé kò sí ìdi fún ẹni kankan láti hu ìwà àjẹbánu?
Ààrẹ gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé bí yóò bá fi di ọdún tó ń bọ̀, àwọn ètò tí àwọn gbé kalẹ̀ fún iṣẹ́ ọ̀gbìn yóò ti so èso rere, oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ẹ ó sì máa jẹ àjẹbì.
Ṣé ẹ̀yin náà wá ríi pé kìí ṣe nípa oúnjẹ nìkan ni ààrẹ yóò fi mú ayé rọrùn fún wa, tó fi dé orí ètò ẹ̀kọ́ ni ààrẹ yóò pèsè fún àwọn ọmọ Nàìjíría.