Àádọ́ta nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n kó ní ilé ìwé ST Mary tó wà ní ìpínlẹ̀ Niger ti dé o.
Wòlíì ìjọ Aguda, ẹ̀kun Kontagora; Bulus Yohnna ló kéde èyí pẹ̀lú alága àjọ àwọn ẹlẹ́sìn kírísìtẹ́nì ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger.
Wòlíì Yohanna wí pé àwọn ṣe àbẹ̀wò sí àwọn òbí ọmọ náà ni àwọn bá àwọn ọmọ náà pẹ̀lú wọn tí wọ́n ti sá wálé.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó dín ní àádọ́jọ (150) ni ó kú báyìí tí wọ́n fẹ́ gbà kalẹ̀.
Bákan náà ni àwọn olùjọsìn ilé ìjọsìn CCA Kwara tí wọ́n kó lọ náà ti padà dé.
Ó tó láti kí àwọn olùjọ́sìn ilé ìjọsìn Eruku tí wọ́n jí gbé kú oríire nítorí pé kò wọ́pọ̀ nínú àwọn tó bọ̀ bẹ́ẹ̀.
Rafiu Ajakaye; ẹni tó jẹ́ akọ̀wé àtẹ̀jáde fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ló kéde lọ́jọ́ Àìkú pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsùn ati iṣẹ́ àṣekára àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, òun láyọ̀ láti kéde pé àwọn olùjọ́sìn méjidínlógójì tí wọ́n kó nílé ìjọsìn CAC, Eruku ti gba òmìnira báyìí.
Gómìnà AbdulRahman gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lórí ipa tó kó lórí àtibọ̀ àwọn ẹni náà.
Bí kìí bá ṣe ààrẹ tó tètè gbé ìgbésẹ̀ ni, ó sẹ é ṣe kí wọ́n má bọ̀.
Ọ̀rọ̀ yìí kan ìpínlẹ̀ Kebbi náà:
Alága ìjọba ibílẹ̀ Danko Wasagu ní ìpínlẹ̀ Kebbi; Hussaini Aliyu Bena ké tantan pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti kó àwọn àgbẹ̀ mẹ́jọ lọ nínú ìkọlù titun.
ó ní òun ti tọ àwọn ọmọ ogun lọ wọ́n sì ti fọ́n sígbó láti wá àwọn àgbẹ̀ náà.
Sani; àgbẹ̀ tí òun náà wà nínú oko lásìkò náà ṣe àlàyé pé àwọn ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ nínú oko ni àwọn agbébọn náà dé tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ẹnìkan, mẹ́jọ ni gbogbo àwọn tí wọ́n kó lọ nígbà tí àwọn yòókù móríbọ́.
Ó ní òun fura pé ìpínlẹ̀ Zamfara ni wọ́n ń lọ pẹ̀lú ọ̀nà ibi tí wọ́n yà sí. Ó ní inú fu àyà fu ni àwọn fi ń lọ sí oko lásìkò yìí kí ìjọba gbà wọ́n.
Wàyí o, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi yí ọ̀rọ̀ náà dànù, wọ́n ní kò sí ìkọlù kankan tó wáyé kí àwọn aráàlú ó fi ọkàn balẹ̀.
Gbogbo àwọn ìkọlù yìí ti gba oorun lójú ààrẹ, kódà àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin pàápàá kò lójú oorun:
Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ wa; Garba Maidoki ṣe àpèjúwe ọ̀sẹ̀ tó lọ yìí ní ọ̀sẹ̀ tó burú jáì látàrí àwọn ìkọlù tó wáyé pàápàá ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí wọ́n kó lọ.
Ẹ̀kun gúúsù Kabbi ni Garba ń ṣojú, ó ní àwọn agbébọn náà ti gbé ìkọlù wọn dé ààrin gbùngbùn ibi tí òun ń ṣojú òun kò sì ní gbà kí ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èyí ó dà bíi ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok ìjọ́sí.
Ìkọlù tí Garba ń sọ náà ni ti ilé ìwé girama àwọn obìnrin ti ìjọba tó wà ní Maga, ìpínlẹ̀ Kebbi níbi tí wọ́n ti pa ọ̀gá iléèwé náà; Hassan Yakubu Makuku tí wọ́n sì kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lọ.
Garba ní òun ti ṣe àbẹ̀wò sí àwọn òbí ọmọ náà ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé wọn yóò gbà wọ́n kalẹ̀.
A ti ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò lórí bí àwọn ọmọ náà ó ṣe padà wálé – Garba Maidoki.
Nínú gbogbo làásìgbò yìí, aya ààrẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run:
Obìnrin àkọ́kọ́ nílẹ̀ yìí, ẹni tó jẹ́ aya ààrẹ Bola Ahmed Tinubu; Oluremi Tinubu ti ṣe àlàyé pé gbogbo làásìgbò àti ìdààmú tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí kò le tu irun kan lára ìṣọ̀kan Nàìjíríà. Digbí ni orílẹ̀-ède wa wà kò sí ìpínyà tí yóò wáyé.
Níbi ayẹyẹ ìdúpẹ́ tó wáyé ní ilé ìjọsìn Methodist Unity Cathedral, Abuja ni aya ààrẹ ti sọ èyí.
Ó wí pé ìṣọ̀kan àti ìdúróṣinṣin orílẹ̀-èdè yìí wà ní ọwọ́ Ọlọ́run kò sí lọ́wọ́ àwọn adàlùrú, nítorí náà kí ẹ kún fún àdúrà àti ààwẹ̀ kí ẹ ké pe Ọlọ́run.
Pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnú ni a ó fi ṣe ayẹyẹ kérésì tó ń bọ̀ yìí, kò sí ifòyà kankan – Oluremi Tinubu.
Ààrẹ náà ti gbé ìgbésẹ̀:
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pàṣẹ kí ọ̀gá ọlọ́pàá yányán ó ṣe ìdápadà àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú ìlú.
Ààrẹ wí pé kí eṣinṣin wọn ó yé tẹ̀lé màlúù kí wọn ó padà sí ìdí iṣẹ́ ààbò tí a gbà wọ́n fún gan-an. Iye àwọn ọlọ́pàá yìí ń lọ bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún.
Níbi ìpàdé àpérò pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá ẹ̀ṣọ́ aláàbò ni ààrẹ ti pàṣẹ yìí, ó wí pé kí àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n yàn tẹ̀lé àwọn olówó ọlọ́rọ̀ ó padà sí àgọ́ láti gbógun ti ìwà ọ̀daràn tó ń lọ yìí nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé NSCDC ni yóò máà tẹ̀lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú báyìí.
Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró:
ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́BÌNRIN MẸ́Ẹ̀DỌ́GBỌ̀N NI ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ KÓ LỌ.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó móri bọ́ lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe àlàyé ohun tí ojú wọ́n rí lọ́jọ́ kan tí wọ́n lò náà.
Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí ni àwọn agbésùnmọ̀mí ya wọ ilé ìwé àwọn obìnrin t ìjọba tó wà ní Maga, Danko ní ìpínlẹ̀ Kebbi, àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni wọ́n kó lọ tí wọ́n sì tún ṣekú pa ọ̀gá iléèwé náà; Hassan Makuku.
Àwọn òbí àti olùkọ́ ti pàdé láti mọ bí wọn yóò ṣe rí àwọn ọmọ náà. Láti ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ìlú náà ti kan gógó, àwọn aráàlú kóra jọ wọ́n sì ń gbìyànjú ipá wọn lórí rírí àwọ́n ọmọ náà.
Ipa ìjọba:
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pàṣẹ fún àwọn ológun láti wá àwọn ọmọ náà jáde, ìròyìn padà tẹ̀ wá lọ́wọ́ pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti dá àwọn ológun náà lọ́nà wọ́n sì ti fi ìbọn ṣe wọ́n léṣe báyìí.




