Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti fèsì sí fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan, nínú fọ́nrán yìí ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kùnrin ti ń fa kàná tí wọ́n sì ń fìkan rànkan.
Àwọn ọmọ yìí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama Excel tó wà ní Ejigbo, inú ilé ìgbé ni wọ́n wà tí wọ́n bọ́ aṣọ lọ́rùn, wọ́n ń bẹ́ná sí kàná wọ́n sì tún ń kọ́ àwọn tí kò tíì mọ ẹnu rẹ̀ láàrin wọn.
Inú oṣù Igbe, ọdún yìí ni wọ́n ṣe èyí gẹ́gẹ́ bíi déétì tó wà lórí fọ́nrán náà.
Àwọn òbí faraya lórí fọ́nrán yìí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu ilé ìwé náà fún kíkùnà láti mójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Olohundare Jimoh ti pàṣẹ fún ẹ̀ka aṣèwádìí Panti láti gba ẹjọ́ náà lọ́wọ́ àgọ́ ọlọ́pàá Ejigbo, wọ́n ti ránṣẹ́ sí ọ̀gá ilé ìwé náà fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àlàyé pé ọ̀gá ilé ìwé náà tó sì tún jẹ́ pé òun ló ni ilé ìwé náà sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú fọ́nrán náà ti kẹ́kọ̀ọ́jáde.
Adebisi wí pé ilé ìwé Excel fi ọwọ́ sòwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
‘A kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé ó níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la àti ìwà ọmọlúàbí. A fi àkókò yìí ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn adarí ilé ìwé láti ṣe àmójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn’ – ilé iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó:
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti dá iṣẹ́ dúró ní ilé alájà mẹ́fà tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpópónà Saka Tinubu, Victoria Island lẹ́yìn tí àwọn ará àdúgbò ké gbájarè.
Ìṣọwọ́ tí wọ́n fi kọ́ ilé yìí lòdì sí ààbò àwọn tó wà ní agbègbè náà ó sì ti ń mú ìpalára bá àwọn ilé tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Àwọn ará àdúgbò náà ló ké gbájarè tọ ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn lọ pé ilé alájà mẹ́fà yìí le dà wó nígbàkûgbà ní èyí tó le mú ìpalára bá àwọn ará ilé tó yíi ká, yàtọ̀ sí èyí, igi àti àwọn nǹkan mìíràn ń jábọ́ láti orí ilé náà sí orí òrùlé, inú ọgbà àti orí ọkọ̀ tó yíi ká.
Wọ́n ké sí ìjọba láti ṣe àbẹ̀wò sí ilé yìí kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.
Ìjọba Èkó ti gba ọ̀rọ̀ wọn yẹ̀wò báyìí wọ́n sì ti pàṣẹ kí wọn ó dá iṣẹ́ dúró ní ilé náà.
Ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom:
Joseph Eren; ẹni ọdún márùndínlógójì ti ṣá ará ilé rẹ̀ ládàá pa nígbà tí aáwọ̀ ṣẹlẹ̀ láàrín wọn.
A gbọ́ pé Ekopimo Moses ni olórí ọ̀dọ́ agbègbè náà, ọ̀rọ̀ ṣe bí ọ̀rọ̀ láàrin òun àti Joseph tí Joseph sì fi àdá ṣá a títí tó fi kú.
Ọjọ́bọ, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni èyí ṣẹlẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ibesikpo, Akwa-Ibom.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom; Timfon John ló ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè nípa àwọn méjì náà àti bí Joseph ṣe fi àdá ṣá Moses.
Wọ́n gbé Moses dé ilé ìwòsàn àmọ́ kò yèé.
Ìròyìn àwọn afipábọ́mọlò:
Aṣọ́gbà ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan tó wà ní Ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin tó jẹ́ ọmọ ilé ìwé náà lò.
Josiah Ayomide ni orúkọ aṣọ́gbà yìí, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni pẹ̀lú.
Ìròyìn fi yé wa pé lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ògún tó kọjá yìí ni Josiah ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ tó sì fipá já ìbálé rẹ̀.
Ọmọ yìí sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé ojú ara ń dun òun, nígbà tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ nínú ló ṣe àlàyé pé aṣọ́gbà ilé ìwé bọ́ pátá òun lọ́jọ́ kan tó sì ki nǹkan bọ̀ ìdí rẹ̀.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn Eleyele fi hàn pé ìbálé ọmọ náà ti já, ojú ara rẹ̀ sì tún dégbò.
Josiah náà kò jiyàn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá, ó jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni òun fipá bá ọmọ náà lò.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Josiah yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Adewale Osifeso; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Bàbá ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta kan náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanuel George ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi ipá gba ìbálé ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé nínú keke maruwa tí bàbá yìí ń w ni ó ti já ìbálé ọmọ náà.
Ọjọ́ kẹfà, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní agbègbè Mini Orlu ní Portharcourt tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.
Ọmọbìnrin yìí ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wá lo ìsinmi lọ́dọ̀ rẹ̀ rán níṣẹ́ nígbà tí Emmanuel fi ipá wọ́ ọ sínú keke rẹ̀, ó fi aṣọ díi lẹ́nu ó tún so ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kó tó fi ipá já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sálọ.
Ọmọ yìí délé ròyìn fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ìtọpinpin awọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ gbé Emmanuel níbi tó lọ farasin sí, kò tilẹ̀ jiyàn, pẹ̀lú sùúrù ló fi jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọ náà lò lóòótọ́.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀.
Bákan náà ni Aliyu Musa; ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi tìpǎtìkûkú já ìbálé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni ìjọba ìbílẹ̀ Mubi, ìpínlẹ̀ Adamawa.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa; Suleiman Nguroje lọ sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé nínú akitiyan láti gbógun ti ìwà ìfipábánilò, àwọn mú Aliyu tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lò pọ̀.
Ọjọ́ kejìlá, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, ọmọbìnrin náà sá fún òjò nínú ìsọ̀ Aliyu ni ó fi bá a lájọṣepọ̀.
Aliyu tan ọmọ náà wọ inú ìṣọ̀ inú lọ níbi tó ti já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ló fún un ní owó tó sì tún ṣe ìlérí fún un pé òun yóò ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fún un.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa; Dankombo Morris bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ kí wọn ó sì tari rẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́
yìí di mímọ̀ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.




