Àwọn Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn fi ìwé ìwáni síta pé àwọn ń wá ọmọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ HABEEB ỌLÁLỌMÍ tí ìnagijẹ rẹ̀ n jẹ́ Portable, ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, kò ga púpọ̀, ó dúdú, ibi tí wọ́n ti kó fìrí rẹ̀ gbẹ̀yìn ni ilé ọtí ódóógú ní ìlú Ọ̀tà.
Párá! HABEEB ỌLÁLỌMÍ,Wèrè Olórin Portable bá bọ́ sórí ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́, ó n kígbe ‘Ẹ gbà mí oooo gbogbo ọmọ Nàìjíríà, Èwo ni wíwá kiri láì kí n ṣe olè tàbí ọ̀daràn, iṣẹ́ orin ni mò n ṣe ooo’. Igbe yìí ló gbẹnu Portable kan, ìyẹn olórin tàkasúfèé lónìí lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn fi ìwé ìjẹ́jọ́ síta.
Portable wí pé ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, mo nílò ìrànlọ́wọ́ yín , Ẹ gbà mí, Ẹ ràmí kalẹ̀, a ti n pe ọ̀rọ̀ yìí lọ́wẹ̀, ó ti n láàáró nínú oooo, Aláànú èèyàn ni mí, Ẹ jà fún mi. Àjò kò dàbí ilé àmọ́ àwọn ẹni ibi ló pọ̀jù ní ilé. Ó ṣe jẹ́ èmi lòníì, Portable lánàá bí ẹkùn àpọkọjẹ, ṣé èmi nìkan ni? Kílódé gan-an? Gbogbo ìgbà ni ìjọba Nàìjíríà n fi imú mi dánrin. Kí lẹ̀ n wá mi fún báyìí? Olórin ni mí, mi kìí jalè, mi ò pààyàn, mi ò ṣenìkan ni ibi, òòre Ọlọ́run ni mò n retí, Nínú ohun ti Ẹlẹ́dàá fún mi ni mo fi n ṣàánú, mi ò kí n fa wàhálà tàbí ìjọ̀gbọ̀n, àwọn ènìyàn ni kìí fẹ́ ẹ rí imi mi láàtàn.
Ẹ má gbàgbé pé láìpẹ́ yìí, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn, ẹ̀ka táún pilaanì tó n ṣe ìmójútó ilé àti àyíká lọ sí ilé HABEEB ỌLÁLỌMÍ, lọ́sẹ̀ tó kọjá, wọn rí i pé ilé rẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ni kò ní ìwé àṣẹ ìkọ́lé, Bàbá rẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba bá níbẹ̀, kíá! Portable àti àwọn jàndùkú bí i mẹ́sàn án lu àwọn òṣìṣẹ́ ní ànà dojú-bolẹ̀. Mẹ́ta nínú wọn ló farapa yánnayànna tí wọ́n gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.
Ilé àti ilé ọtí rẹ̀, ODÓÓGÚ padà di dídàwó lulẹ̀ gbìì, Portable ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ báyìí. Àwọn Ọlọ́pàá ti n wá a, wọ́n ní kí àwọn èèyàn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàwárí rẹ̀, kí ó le è wá jẹ́jọ́ òfin tí wọ́n fi kàn án nítorí òfin kò mẹni ọ̀wọ̀.
Ìyàwó Pọ́tébù, Àṣàbí Simple náà ń ké lórí ẹ̀rọ ayélujára sí àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́, kó má le è kú sí ìgbèkùn ìjọba nítorí ẹni ire ni HABEEB ỌLÁLỌMÍ. Ọ̀kan lára àbúrò Portable náà ni ogun ló n jàá, àwọn orogún ìyá rẹ̀ ló n ṣe é, kí ìjọba ṣíjú àánú wò ó.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, Bàbá Adébóyè, Olùṣọ́ àgbà fún ìjọ RÌDÍÌMÙ ní ọdún ẹ̀san ni ọdún 2025, ọdún yìí yóò le gan an, ojú ọ̀pọ̀ èèyàn yóò bó. Pàrà! Portable ti bọ́ sórí ayélujára pé kí bàbá gbẹ́nu sọ́hùn-ún, irọ́ lásán ni gbogbo ìran rẹ̀, kò rí nǹkankan, kò sí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, ojú òun àti olólùfẹ́ kò ní bó.
Àmọ́ ní báyìí, Portable ní, ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, mo nílò ìrànlọ́wọ́ yín, Ẹ gbà mí, Ẹ ràmí kalẹ̀, a ti n pe ọ̀rọ̀ yìí lọ́wẹ̀, ó ti n láàáró nínú oooo, Aláànú èèyàn ni mí, Ẹ jà fún mi.
Ẹ̀yin ará, Ẹ ò ri bí? ó jọ gáte, kò jọ gáte, ó fẹsẹ̀ méjéèjì lélẹ̀ gáte-gàte. Ìríran ti n jà lórí Portable ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún titun báyìí.
Òun yìí kannáà yìí náà n ló n bu ẹnu àtẹ́ lu Aláàfin àná, ikú bàbá yèyé, Olóògbé Ọba Làmídì Adéyẹmí bí o ti n jẹṣẹ́ olorì Dámilọ́lá. Ó tún ni àwọn ará Ìbàdàn kò lówó, àkúṣẹ̀ẹ́ ni gbogbo wọn, kò sí ilé gidi kan níbẹ̀, ìgbà pípẹ́ sì ni ó fi tàbùkù wọn lórí ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́.
Ọwọ́ ti tẹ aláṣejù rẹ̀, òkété rẹ̀ gbàgbé ìbòsí, ó dé igbá alátẹ, ló bá ká ọwọ́ mọ́ orí. ÈDÙMÀRÈ JỌ̀WỌ́, MÁ JẸ KÍ A RÍ ÌJÀ AYÉ.