A Kò Rẹ́ni Ra Ohun Tí A ń Tà- Awọn Oníṣòwò Kastina Figbe Ta. Àwọn oníṣòwò Kastina ké tantan síta pé àfi bí ìgbà tí wọ́n bá da òkùtà sáàrin ọjà ni àwọn kò tilẹ̀ rí eṣinṣin débi èèyàn kó bèèrè pé kín ni ẹ ǹ tà níbẹ̀ yẹn.
Nígbà tí wọ́n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ilẹ̀ kún.
Lára àwọn ohun tí wọ́n sọ náà ni pé ṣáájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà ni ọjà kò ti yá déédéé.
Tó ṣe pé kò jọ ìtàkùtà, kò jọ kó má gbówó lọ làwọn ń tà.
Amọ́ láti ọjọ́ tí ìfẹ̀hónúhàn náà ti bẹ̀rẹ̀, àwọn kò tilẹ̀ rí ẹyẹ lọ́jà pé gbogbo àwọn ọjà tí kò le pẹ́ nílẹ̀ bíi tòmátò ló ti bàjẹ́ tí ó sì ti di gbèsè.

Itokasi – Katsina Govt
Adam, ọ̀kan lára àwọn oníṣòwò náà ṣe àlàyé pé ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí òun ti ń ta èso lọ́jà Jikan Hajiya pé kò tíì sí ìgbà tó burú tó báyìí tí òun kò ta horo èso kan ṣoṣo lójúmọ́ kan.
Ó fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn pé àwọn èso náà ti ń bàjẹ́ tí yóò sì di gbèsè.
A Kò Rẹ́ni Ra Ohun Tí A ń Tà- Awọn Oníṣòwò Kastina Figbe Ta
Ẹlòmíràn tó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ṣe àlàyé pé lọ́fínda tí òun ń tà Kò tilẹ̀ rí ẹni mọ́ ọn lójú.
Ebi ń pani ọlọ́ṣẹ ń polówó ni ọ̀rọ̀ tòun pé ohun tó kàn ń dun òun ni pé owó tí òun tùjọ fún ìlò ọjọ́ iwájú lòun fi ń jẹun lásìkò yìí ná.
Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwe kọ́bọ̀, gbogbo wọn ló ní ohun kan tàbí òmíràn láti sọ nípa bí àìtà ọjà náà ṣe kàn wọ́n.
A Kò Rẹ́ni Ra Ohun Tí A ń Tà- Awọn Oníṣòwò Kastina Figbe Ta