Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fèsì sí ọ̀rọ̀ Mirabel tó ń jà rànìnrànìn nílẹ̀ pé àwọn kò mú Mirabel sí àgọ́ wọn ní àtakò sí ohun tí àwọn èèyàn ń sọ pé Mirabel wà lákàtà wọn.
Mirabel ni ọ̀dọ́bìnrin tó fi fọ́nrán kan léde pé aráalé òun fi ipá bá òun lò pọ̀. Ó ṣe àlàyé nínú fọ́nrán náà pé aráalé òun náà bèèrè fún òǹkà ìbánisọ̀rọ̀ òun àmọ́ òun kò fún un. Lọ́sàn-án ọjọ́ náà, òun gbọ́ tí ẹnìkan kan ilẹ̀kùn òun, nígbà tí òun ṣí i, ọkùnrin aráalé náà ló já wọ ilé, ó ti òun lu fírísà òun sì dákú, nígbà tí òun máa lajú, òun báa lórí òun tí ó ń fi ipá bá òun lò. Lẹ́yìn náà ni ó fi abẹ ya ojú ara rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló faraya lórí ẹ̀rọ ayélujára tí wọ́n sì ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ni Mirabel tún fi fọ́nrán mìíràn léde pé òun mu ‘sniper’ nítorí pé òun kò le fi ara da ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ní ọ̀rẹ́ òun ló gbé òun lọ sílé ìwòsàn ni ikú fi yẹ̀ lórí rẹ̀.
Gbogbo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ń lọ ni àwọn kan ti ń sọ pé irọ́ ni Mirabel ń pa nítorí kò le mu ‘sniper’ kí wọn ó sì dá a sílẹ̀ lọ́jọ́ kejì. Wọ́n bèèrè fún ẹ̀rí láti ilé ìwòsàn tí ó ní òun ti gba ìtọ́jú.
Bákan náà ni àwọn aráalé Mirabel wí pé ko sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ẹnìkankan kò bá Mirabel sùn, ó kàn ń wá ojú àánú ni. Wọ́n ní Mirabel sọ fún àwọn pé ìyá rẹ̀ kú àwọn sì dá owó fún, ẹ̀yìn ìgbà náà ni àwọn padà mọ̀ pé ìyá rẹ̀ ti kú tipẹ́.
Wọ́n ní ọjọ́ tí Mirabel ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, kò sí ẹni tó wọlé tàbí jáde lọ́jọ́ náà àti pé àwọn kò gbọ́ nǹkankan àfi ìgbà tí àwọn dé orí ẹ̀rọ ayélujára.
Gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ń lọ ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ gbà irọ́ ni Mirabel ń pa, wọ́n rọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá láti ṣe ìwádií.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ló kọ́ fèsì, wọ́n ní Ogijo tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀ ti kúrò ní Èkó, ìpínlẹ̀ Ogun ni agbègbè náà nítorí náà, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ni yóò ṣe ìwádìí náà.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Oluseyi Babaseyi tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà pé àwọn kò fi ofin mú Mirabel, fúnra rẹ̀ ló fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn wá sí àgọ́ wọn ní Ogijo wá fi ẹjọ́ sùn lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù Èrèlé.
Wọ́n gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ àmọ́ ipò àìlera rẹ̀ kò jẹ́ kí ó le ṣe àlàyé délẹ̀, wọ́n sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú tó péye títí ara rẹ̀ yóo fi yá láti ṣe àlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún àhesọ ọ̀rọ̀ lóró òrọ̀ Mirabel yìí.
Ọ̀kan tún ni èyí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilò, bí ti Mirabel kò bá padà jẹ́ òọ́tọ́ nígbẹ̀yìn, lára àwọn tó ti jẹ́ òótọ́ sẹ́yìn ni ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Adekunle Ajaasin tí wọ́n bá akẹgbẹ́ wọn lò ní tìpátìkúùkú:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti tẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin méjì tí wọ́n fipá bá akẹgbẹ́ wọn lájọṣepọ̀.
Olushola Ayanlade; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn ẹni náà tan ọmọbìnrin ẹni ogún ọdún náà lọ sí ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ wọn nílé ìwé náà. Ọmọbìnrin yìí ti mọ Queen Sodo; ẹni ọdún mọ́kàndínlógún láti ilé ìwé girama ó sì lọ kíi nígbà tó wọ ilé ìwé gíga tí òun náà wà.
Nígbà tó dé ilé Queen, ó mu nǹkan mímu láì mọ̀ pé Queen ti fi òògùn olóró sínú rẹ̀, nígbà tí obìnrin yìí sùn lọ, Queen bọ́ síta ó sì pe ọkùnrin náà wọlé láti bá a lájọṣepọ̀.
Aráalé Queen ló gbọ́ ohun tí kò fanimọ́ra láti inú yàrá Queen ló yọjú wo inú ilé náà, ó ṣí ilẹ̀kùn yàrá náà ó sì bá ọkùnrin náà lórí ọmọ yìí.
Wọ́n ṣe aájò ọmọ yìí dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Àwọn afurasí méjéèjì jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni àwọn fún un ní òògùn olóró mu àti pé kìí ṣe tirẹ̀ ni àkọ́kọ́.
Ayanlade wí pé àwọn afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí ó sì rọ àwọn òbí láti máa gba àwọn ọmọ wọn níyànjú lóòrèkóòrè.
Bákan náà ni bàbá kan fi ipá gba ìbálé ọmọ ọdún méjìlá:
Bàbá ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanuel George ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi ipá gba ìbálé ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé nínú keke maruwa tí bàbá yìí ń w ni ó ti já ìbálé ọmọ náà.
Ọjọ́ kẹfà, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní agbègbè Mini Orlu ní Portharcourt tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.
Ọmọbìnrin yìí ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wá lo ìsinmi lọ́dọ̀ rẹ̀ rán níṣẹ́ nígbà tí Emmanuel fi ipá wọ́ ọ sínú keke rẹ̀, ó fi aṣọ díi lẹ́nu ó tún so ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kó tó fi ipá já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sálọ.
Ọmọ yìí délé ròyìn fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ìtọpinpin awọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ gbé Emmanuel níbi tó lọ farasin sí, kò tilẹ̀ jiyàn, pẹ̀lú sùúrù ló fi jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọ náà lò lóòótọ́.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.




