Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti fèsì sí ọjà Festac tí wọ́n wó ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, wọ́n ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé àwọn èèyàn kan le dá irú rẹ̀ láṣà. Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu wí pé òun kò mọ̀ nípa bí wó.n ṣe wó ọjà náà.
Mukaila Sanusi; ẹni tó jẹ́ adarí ẹka ọ̀rọ̀ ìlú ní ilé iṣẹ́ ètò ìlú ló bu ọwọ́ lu àtẹ̀jáde náà tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Ọ̀wàrà.
Nínú rẹ̀ la ti kà á pé ohun tí àwọn ń gbọ́ kiri nígboro kò rí bẹ́ẹ̀ o, Gómìnà Babajide Sanwoolu kò mọ nǹkankan nípa bí wọ́n ṣe lọ ó gbogbo ọjà náà kanlẹ̀ kódá, ẹ̀ka ètò ìlú gan-an kò mọ̀ nípa rẹ̀, ó ya àwọn gan-an lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò le ṣàdédé wó dúkìá àwọn èèyàn, gbogbo ohun ló létò lábẹ́ òfin, nítorí ìdí èyí, a kò mọ̀ nípa wíwó ọjà náà – Oluyinka Olumide
Olumide bá àwọn tí wọ́n pàdánù dúkíà wọn kẹ́dùn, ó wí pé ọwọ́ Babajide Sanwoolu rèé funfun.
Inú oṣù tó kọjá yìí náà ni àwọn ará Oworonshoki fi ẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó yìí kan náà pé:
Àwọn ará Oworonshoki fi ẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó pé wọ́n da ilé wọn wó lẹ́yìn tí àwọn ti gba gbogbo ìwé ilẹ̀ lábẹ́ òfin.
Òru ọjọ́ kan nínú oṣù kẹwàá ni wọ́n kó àwọn katakata dé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wó ilé mọ́ àwọn èèyàn lórí, èérún bíríkì ló jí ẹlòmíràn lórí ibùsùn rẹ̀.
Alága agbègbè náà; Balogun Jamiu ṣe àlàyé lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tún àwọn ilé wọn kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fún àwwọn ní ìwé pé kí wọn ó tún àwọn ilé náà kọ́, àfi bí wọ́n ṣe kó katakata dé tí wọ́n sì wó gbogbo ilé lọ.
Obìnrin kan tilẹ̀ ta ilé rẹ̀ tó wà ní Ikorodu láti tún èyí tó wà ní Oworonshoki ṣe, ilé ìwòsàn ló balẹ̀ sí nígbà tí wọ́n wó ilé náà.
Balogun wí pé tó fi dé orí ìwé C of O ni gbogbo àwọn ti gbà, síbẹ̀, wọ́n wó àwọn ilé náà.
Femi Badewa; ẹni tí òun náà jẹ́ olùgbé Oworonshoki náà ṣe àlàyé pé òru ni wọ́n dé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wó ilé mọ́ àwọn èèyàn lórí. Ọlọ́pàá mẹ́rin ni wọ́n kó wá, kò sì sí nọ́ḿbà lára ọkọ̀ wọn. Ó wí pé àwọn ajagungbalẹ̀ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà.
Obìnrin kan náà ṣe àlàyé pé wọ́n sọ fún àwọn pé kí àwọn ó tún àwọn ilé náà kọ́ sí ti ìgbàlódé, kí àwọn ó kọ́ àwọn ilé náà kó rẹwà pé wọn kò fẹ́ ilé àtijọ́ ní ibẹ̀ mọ́, ìdí nip é Oworonshoki súnmọ́ afárá Third Mainland.
Obìnrin yìí wí pé ìwé ẹ̀rí òun nìkan ni òun rí mú jáde, gbogbo ẹrù rẹ̀ ni wọ́n wó mọ́ ilé.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó fèsì láti ẹnu Oluyinka Olumide pé ìjọba kò ní fún àwọn èèyàn náà ní owó gbà-má-bínú nítorí pé wọn kò ní ìwé àṣẹ fún àwọn ilé náà.
Ó wí pé ó ṣe pàtàkì fún àwọn láti wó àwọn ilé náà nítorí pé wọ́n ń dí ṣíṣàn omi lọ́wọ́ ní èyí tó le fa ewu.
Lórí ilẹ̀ gbígbà yìí náà ni àwọn obìnrin ìlú Ilaje ṣe tú jáde níjọsí, a mú ìròyìn náà wá pé:
Àwọn obìnrin ìlú Ìlàjẹ tú jáde lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó pẹ̀lú oríṣìí àkọlé lọ́wọ́, wọ́n ké sí agbẹnusọ ilé náà ìyẹn Mudashiru Obasa àti àwọn aṣòfin lápapọ̀ láti kìlọ̀ fún àwọn ọba tí wọ́n di ajagungbalẹ̀, wọ́n ní àwọn ọba yìí ń lé àwọn kúrò ní orí ilẹ̀ tí àwọn tẹ̀dó sí wọ́n sì ń ta àwọn ilẹ̀ náà.
Àwọn obìnrin yìí wí pé àwọn yóò ṣe ìwọ́de ní ìhòhò bí èyí kò bá dópin.
Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ifagbemi bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣe àlàyé pé àwọn ni ìran tó tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà láti ìgbà tí aláyé ti dáyé, àwọn ọba tí ó ń jẹ lásìkò yìí ń lé àwọn kúrò lórí ilẹ̀, wọn yóò gbé katakata wá wó ilé wọn nígbà tí wọ́n bá ta ilẹ̀ náà mọ́ wọn lórí.
Orúkọ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní àwọn ọba yìí máa ń dá, wọ́n á ní Tinubu ló pàṣẹ kí wọn ó gba ilẹ̀ náà.
Àwọn obìnrin yìí kóra jọ sí iwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó nínú òjò wẹliwẹli náà, wọ́n ní àwọn mọ̀ pé àwọn ọba yìí kàn ń fi orúkọ Tinubu rẹ́ àwọn jẹ lásán ni òun kọ́ ló rán wọn.
Wọ́n wá fi lé e pé bí èyí kò bá dópin, àwọn yóò ṣe ìwọ́de ní ìhòhò ọmọlúàbí.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Ìlàjẹ; Rafael Irowainu náà sọ̀rọ̀, ó wí pé orílẹ-èdè Nàìjíríà nìkan ni òfin kò ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, àwọn ọba ń jẹ ayé fàmílétè-n-tutọ́, wọ́n ń gbé ilẹ̀ onílẹ̀ tà kò sì sí oníbàáwí fún wọn.
Iroiwanu wí pé púpọ̀ nínú àwọn ọba yìí kìí ṣe ọmọ Èkó, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Èkìtì ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá tí wọ́n sì fi èèrú dé orí ipò ọba náà.
Wọn yóò kàn gbé katakata dé sínú àdúgbò wọn yóò sì máa wó ilé láìsí ìwé àṣẹ láti ilé ẹjọ́, àwọn èèyàn yóò di aláìnílélórí láìrò tẹ́lẹ̀, wọ́n ní gbogbo èyí tó gẹ́.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn wá láti wá fi ẹ̀dùn ọkàn wọn tó Gómìnà Babajide Sanwoolu létí àti àwọn aṣòfin Èkó kí wọn ó wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.
Bákan náà ló wí pé wíwó ilé onílé kún ohun tó ń fa ìwà ọ̀daràn nítorí pé àwọn tí kò nílé lórí mọ́ náà yóò padà darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀daràn níbi tí wọ́n bá ti ń wọ̀sùn kiri.
Wole Adewusi tí òun náà jẹ́ olùwọ́de sọ wí pé àwọn obìnrin àti ọmọ ti di asùnta ní Ìlàjẹ látàrí bí àwọn ọba ṣe ń wó ilé yìí, ó ní wọ́n tún ń sun àwọn dúkìá tí wọn kò bá tètè kó, ó ké sí Sanwoolu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn.
Alága ẹgbẹ́ ọmọ Ìlàjẹ; Ọmọba Oluwajimusu bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà yìí, ó wí pé kò sí bí wọn yóò ṣe kọ ìtàn ìpínlẹ̀ Èkó tí wọn kò ní dárúkọ ìran Ìlàjẹ, ìjọba fẹ́ pa orírun Ìlàjẹ run ni gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí.
Oluwajimusu wí pé ṣíṣe àyípadà orúkọ òpópónà Ìlàjẹ tó wà ní Bariga sí Sunny Ade jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí wọ́n fẹ́ gbà pa ìtàn Ìlàjẹ rẹ́.
Ṣé gbogbo èyí náà nì ìjọba Èkó kò mọ̀ sí?




