Ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ ti ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ìkìlọ̀ àti ìránnilétí fún àwọn ilé ìwé gbogbo pé wọn kò gbọdọ̀ na àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹgba.
Kọ́míṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Èkó; Ọ̀gbéni Jamiu Alli-Balogun ló sọ èyí nínú ìfọrọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ kan tó ń kọ ìròyìn. Ọ̀gbéni Jamiu wí pé òfin ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Èkó kò fi ààyè gba nína akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹgba.
Àwọn ọ̀nà tí wọ́n le gbà ṣe àtúnṣe ìwà náà ni gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú kí wọ́n sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè.
Ọ̀gbẹ́ni Jamiu ṣe àlàyé pé ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn kò fẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ó ní ìpalára látàrí níná tàbí pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ó wá dákú ni àwọn ṣe gbé òfin yìí kalẹ̀
Ó ṣe àfikún pé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá le díẹ̀ le kúnlẹ̀, ṣa ìdọ̀tí ọgbà, bó bá wá jẹ́ ìpátá, ó le gé oko ọgbà ilé ìwé.
Ọ̀gbẹ́ni Jamiu kò ṣàì má mẹ́nuba pé àwọn òbí ló fa èyí tó pọ̀jù nínú àwọn ìwà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń hù nípa pé wọn kò mójú tó wọn bó ti yẹ. Ó wí pé ìjọ́ba yóò máa sa ipá rẹ̀ láti bá wọn wí.
A kò le sọ pé ìjọba Èkó jayò pa lórí òfin yìí nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìfìyàjẹni tó ti wáyé sẹ́yìn láwọn ilé ìwé káàkiri. Ṣé ẹ rántí Monday Arijo, akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Obada tí ó gbẹ́mì mìn látàrí ìyà àjẹkúdórógbó tí olùkọ́ rẹ̀ fi jẹ ẹ?
A mú ìròyìn náà wá pé ‘Monday di èrò ọ̀run lẹ́yìn tí olùkọ́ rẹ̀ fìyà jẹ ẹ́ nítorí èsì tó fọ̀ fún ọ̀gá ilé ìwé. Bàbá rẹ̀ bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Gbeminiyi Arijo ṣe àlàyé bí ọmọ rẹ̀ ṣe di èrò ọ̀run làtàrí ìyà àjẹbólórí tí àwọn olùkọ́ ilé ìwé náà fi jẹ ẹ́.
Ìpele àgbà kejì SS2 ni Monday wà, lórí ìlà láàárọ̀ ọjọ́ náà, ìyẹn ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù ọ̀wàrà, ọ̀gá ilé ìwé ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀ pé kí wọn ó ṣe àmúlò àwọn asẹ́ ìdalẹ̀nù titun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà náà pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ fọ́ ọ. Akẹ́kọ̀ọ́ kan láti inú ìlà ìpele kejì wá fèsì pé ṣebí owó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni wọ́n fi rà á.
Èsì yìí ló bí ọ̀gá nínú, nígbà tí wọn kò sì le ṣe ìdámọ̀ ẹni tó jẹ́ nínú wọn, ọ̀gá pàṣẹ kí àwọn olùkọ́ ó na àwọn ọmọ náà.
Arijo ṣe àlàyé pé àwọn akẹgbẹ́ Monday ló ṣe àlàyé pé àwọn ki orí bọ inú táyà tí wọ́n ti ri ìdajì rẹ̀ mọ́lẹ̀, olùkọ́ mẹ́wàá ló na ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Nígbà tí olùkọ́ kan na àwọn obìnrin lẹ́gba méjì, mẹ́rin ni wọ́n na àwọn ọkùnrin. Tó já sí pé àwọn obìnrin jẹ ẹgba ogún àwọn ọkùnrin sì jẹ ẹgba ogójì.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n ní kí wọn ó máa tọ bíi ọ̀pọ̀lọ́, àádọta lọ́nà mẹ́rin ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe. Orí àádọta kẹta ni Monday wà tó fi ṣubú, ó fọ́ orí mọ́ kankéré nígbà tó ṣubú yìí. Kàkà kí wọn ó gbé e dìde, níṣe ni wọ́n ń ta á nípa mọ́lẹ̀ pé kó dìde kó yé díbọ́n. Ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀kà ikú ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn òbí rẹ̀.
Baba Monday wí pé bí òun bá mọ̀ pé ó fọ́ orí mọ́ kankéré ni, ọjọ́ náà lòun ò bá ti gbé e lọ ilé ìwòsàn. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí kò dẹ́kun igbe orí fífọ́ ni wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn, ibẹ̀ ni wọ́n ti ríi pé orí rẹ̀ ti dégbò sínú. Wọ́n ní kí wọn ó máa gbé e lọ ilé ìwòsàn ìjọba nítorí pé egbò náà pọ̀ gan-an, ọjọ́ kejì tó dé ilé ìwòsàn ìjọba ló kú ìyẹn ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù ọ̀wàrà kan náà.
Àlàyé tí ilé ìwé ṣe kò fara pẹ́ ohun tí àwọn ọmọ wí rárá, wọ́n ní Monday ní ìjàmbá ọkọ̀ láàárọ̀ ọjọ́ náà ni àwọn fi ránṣẹ́ sí òbí rẹ̀ kó wá gbé e.
Ìbéèrè tí wọn kò tíì dáhùn ni pé ṣé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù tí wọ́n ṣì ń gba ìtọ́jú náà ní ìjàmbá ọkọ̀ ni?
Àwọn ọlọ́pàá ti ṣe àyẹ̀wò òkú Monday, èsì kò tíì jáde àmọ́ wọ́n ti sin ín. Bákan náà ni Gómìnà Dapo Abiodun rán ikọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ bá wọn kẹ́dùn.
Ohun tó ṣe ni ní kàyéfì ni pé Olùkọ́ kan péré ni àwọn ọlọ́pàá gbé nínú àwọn mẹ́wàá náà, wọ́n ní àwọn yóòkù ti sá lọ’
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni ọ̀gbéni Gbeminiyi Arijo wí pé òun fi ọ̀rọ̀ náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́, ó bèèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n mú. Ibi tí ẹjọ́ náà forí tì sí nìyìí.
Kò bá dára bí àwọn ìpínlẹ̀ yòókù náà bá le fi irú òfin báyìí náà lẹ́lẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ na akẹ́kọ̀ọ́ tàbí fi ìyà àjẹbólórí jẹ akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé. Ìdí ni pé, ìkà ń gbé inú ẹlòmíràn.
Ṣé ẹ rántí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Ikorodu náà? Níbi tí olùkọ́ ti ń rọ̀jò akọ ìfọ́tí fún ọmọ ọdún mẹ́ta nítorí kò le kọ ẹẹ́fà.
A mú ìròyìn náà wá pé ‘Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti mú arábìnrin Stella Nwadigo; olùkọ́ tó gbá etí akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́ta sí àhámọ́ wọn.
Ẹ̀ka tó ń gbógun ti ìṣenimọ́kumọ̀ku sọ̀rọ̀ láti ẹnu akọ̀wé wọn; Titilola Vivour-Adeniyi pé arábìnrin Stella ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá, ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà, wọ́n sì ti mú ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú.
Ohun tí arábìnrin Stella Nwadigo ṣe náà ni pé ó gbá etí akẹ́kọ̀ọ́ ọmọdékúnrin létí léraléra nígbà tí ọmọ náà kò le kọ ẹẹ́fà (6) dáadáa.
Stella gbá etí ọmọ yìí kíkan kíkan nínú fọ́nrán náà.
Ọmọ ọdún mẹ́ta ni ọmọ yìí, ilé ìwé Christ Mitots tó wà ní Isawo, Ìkòròdú ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀.
Fọ́nrán yìí gbòde kan, abenugan verydarkman dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ó késí àwọn ẹ̀ka tí ọ̀rọ̀ kàn láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
Àwọn òbí faraya lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n béèrè fún ìdájọ́ òdodo.
Arábìnrin Titilola fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Stella ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá, wọ́n sì ti mú ọmọ náà; Abayomi Michael lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò. Abayomi yóò nílò àyẹ̀wò etí àti orí wọn yóò sì ṣe ṣètò olùgbaniníyànjú fún un’
Wọ́n gba onídùúró arábìnrin Stella, ẹnìkan sì fún ọmọ náà ní ẹ̀kọ́ òfẹ́.