Òṣìṣẹ́ ilé ìtajà ìgbàlódé kan tó gbajúmọ̀ àmọ́ tí a kò ní anfààní àti dárúkọ rẹ̀ ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá tó kún ilé ìtajà ìgbàlódé káàkiri kò ṣèèṣì bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn adarí ilé ìtajà náà mọ̀ pé àwọn ọjà náà ti ré kọjá.
Ẹni yìí ṣe àlàyé pé ẹ̀rí ọkàn a máa jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àmọ́ àwọn kò gbọdọ̀ sọ fún àwọn oníbàárà tàbí fu wọ́n lára.
Bí ọjà kan bá ti ré kọjá tó sì yẹ kí àwọn ó kó wọn dànù gẹ́gẹ́ bí òfin, ọ̀gá yóò pàṣẹ kí wọn ó to irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ sì àtẹ ẹ̀dínwó.
Nígbà mìíràn, ọ̀gá náà pàṣẹ kí wọn ó lẹ ìwé pélébé mọ́ ojú déétì ọjà náà.
Bí àwọn òṣìṣẹ́ bá gbìyànjú àti tako èyí tàbí ta oníbàárà lólobó, iṣẹ́ rẹ̀ tán nìyẹn.
Mariam Kuranga; ẹni tó jẹ́ aṣèwádìí oúnjẹ bu ẹnu àtẹ́ lu àjọ NAFDAC pé lábẹ́ igi imú wọn ni àwọn ọjà báyìí ti gba gbogbo ilé ìtajà kan, Mariam ṣe àfiwé àjọ NAFDAC gẹ́gẹ́ bíi ajá tó ń gbó àmọ́ tí kò le bu èèyàn jẹ.
Ọ̀rọ̀ Mariam tẹ̀síwájú pé àwọn ilé iṣẹ́ omi inú ọ̀rá ni àjọ NAFDAC ń lé kiri tí àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé sì ń ta májèlé fún àwọn èèyàn nígboro.
Bí a bá wọ àwọn ilé ìtajà, ọ̀pọ̀ àwọn ohun mímu àti jíjẹ ni kò ní òǹkà ìforúkọsílẹ NAFDAC tí yóò fi hàn pé kò léwu, síbẹ̀ àjọ NAFDAC kò ṣe nǹkankan síi.
Kuranga wí pé àwọn mìíràn a máa ha nọ́ḿbà kan kúrò nínú déétì ọjà náà láti rú u mọ́ oníbàárà lójú.
Gbogbo àwọn ọjà yìí ló le fa àisàn sí àgọ́ ara tí yóò sì pa ìlera àwọn èèyàn lára.
Odunayo Sunday, ẹni tó jẹ́ onímọ̀ oúnjẹ náà ṣe àlàyé pé àwọn ọjà báyìí ti di májèlé nítorí pé àwọn èròjà inú rẹ̀ kò ní ṣe ara lóore mọ́, wọn yóò fa àwọn kòkòrò àìfojúrí sínú ara.
Awon kòkòrò yìí ni yóò ṣarajọ fa àisàn tàbí ba àwọn ẹ̀yà ara jẹ́.
Arábìnrin Odunayo rọ àwọn èèyàn láti yẹra fún àwọn ọjà ẹ̀dínwó kí wọn ó sì máa wo gbèdéke ọjọ́ àwọn ọjà tí wọ́n bá fẹ́ rà.
Èyí jẹyọ lẹ́yìn tí ìròyìn kàn nípa bí àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé ṣe ń ta àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá fún àwọn èèyàn jẹ.
Ìròyìn náà lọ báyìí:
Àwọn ilé ìtajà ńláńlá káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó ń ta àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti kọjá fún àwọn oníbàárà, ohun jíjẹ ló pọ̀ nínú àwọn nǹkan yìí ní èyí tó mú ìpalára bá ìlera àwọn
Àwọn tí wọ́n ṣe àgbákò àwọn oúnjẹ yìí ṣe àlàyé ohun tí ojú wọn rí fún àwọn akọ̀ròyìn, wọ́n ṣe àlàyé pé àwọn ilé ìtajà yìí yóò kó àwọn ọjà náà sí apá kan pé àwọn ń ṣe ètò ẹdínwó, ẹ̀dínwó yìí kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn ó yẹ ọjà náà wò tàbí wo gbèdéke rẹ̀ tí wọn yóò fi rà á, ìgbà tí wọ́n bá dé ilé tàbí tí inú bá bẹ̀rẹ̀ sí ní run wọ́n ni wọ́n tó máa ń mọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ ọjà náà ti ré kọjá.
Díẹ̀ ló kù kí Daniel Olanrewaju ó pàdánù àwọn ọmọ méjì nígbà tó fún wọn ní ketchup jẹ láìmọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti kọjá láti ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn.
Daniel ṣe àlàyé pé òun yà sí ilé ìtajà kan tó gbajúmọ̀ ní Ikeja òun sì ra ketchup náà fún akeem ọmọ òun, nígbà tó dé ilé, ó dín iṣu fún àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ́ẹ̀ta ó sì bu ketchup náà síi fún wọn.
Àkọ́bí rẹ̀ tu oúnjẹ náà dànù pé ó ti kan àmọ́ Daniel kò kọbi ara síi, ó rò pé ọmọ náà kò fẹ́ jẹun ni.
Inú rírun ló jí àwọn ọmọ méjì tó jẹ oúnjẹ náà láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìgbà náà ni Daniel yẹ ketchup náà wò tó sì ríi pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti kọjá láti ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn!
Dìgbàdìgbà ló di àwọn ọmọ náà dé ilé ìwòsàn, fún ìtọ́jú.
Ìrírí Daniel rèé gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe àlàyé, ó wí pé òun rò pé àìtà ọjà ló máa ń mú àwọn ilé ìtajà ṣe ètò ẹdínwó ni, òun kò mọ̀ pé ọjà tó le mú ìpalára bá ìlera àwọn èèyàn ni wọ́n ń tà ní gbàǹjo,
Daniel gba àwọn èèyàn lámọ̀ràn pé kí wọn ó máa yẹ ohun tí wọ́n bá rà wò fínífíní.
Temitope Ogunsanya náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí nílé ìtajà ìgbàlódé kan tó wà ní Ijegun, ó ṣe àlàyé pé òun bá ìyàwó òun ra ìpekeré inú agolo (Pringles) ní ilé ìtajà ìgbàlódé kan tó gbajúmọ̀ dáadáa.
Nígbà tí ó fẹ́ sọ agolo ìpekeré náà nù ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ló ṣe àkíyèsí gbèdéke ọjọ́ tí wọ́n kọ sí ara rẹ̀ tó sì ríi pé ó ti kọjá láti oṣù kan sẹ́yìn.
Àyà rẹ̀ já nítorí pé ìyàwó rẹ̀ kò tíì jí láàárọ̀ ọjọ́ náà, ó sáré wọ ìyẹ̀wù láti jíi, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nígbà tí ìyàwó rẹ̀ jí pẹ̀lú àlàáfíà.
Temitope ní òun kò le rò ó pé ilé ìtajà náà le ta irú ọjà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ilé ìtajà náà lórúkọ káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé àwọn èèyàn yìí ló ta àwọn ikọ̀ dìde láti lọ ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìtajà káàkiri, àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá ni wọ́n tò sí orí atẹ ẹ̀dínwó lóòótọ́.
Àwọn ohun jíjẹ bíi Bisikí, tíì, mílíkì, ìpàdánù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló wọ́pọ̀ nínú àwọn ọjà yìí.
Àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé tó wà ní Lekki, Abúlé Ẹ̀gbá, Ishaga àti Ọgbà ni àwọn ikọ̀ yìí ṣe àbẹ̀wò sí.
Nílé ìtajà Renne tó wà ní Lekki, gbogbo àwọn ọjà tó wà ní orí àtẹ ẹ̀dínwó ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Wọ́n ta Chicco D’oro ní ẹgbẹ̀rún márùún náírà dípò ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà dín igba tí wọ́n ń tà á, wọ́n ta Bristol Decaf náà ní ẹgbẹ̀rún márùún náírà dípò ẹgbẹ̀rún méje, àwọn èèyàn ń ti ara wọn láti ra àwọn ọjà yìí láìmọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti ré kọjá.
Bákan náà lọmọ ṣorí nílé ìtajà Medzie tó wà ní Abúlé Ẹ̀gbá, White Dats àti Pune cocoa tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá ni wọ́n tò sí orí igbá.
Ilé ìtajà Everbest tó wà ní Iju-Ishaga ló burú jù, àwọn ọjà tó ti ré kọjá láti inú oṣù kẹrin ọdún ni wọ́n ń tà fún àwọn èèyàn ní ẹ̀dínwó.
Ketchup, mílíkì Dano, ìfọyín, tíì lóríṣiríṣi ni wọ́n ń tà fún àwọn èèyàn tí kò fura.
Nílé ìtajà So-Rite tó wà ní Ishaga náà, tó fi dé orí bisiikí ni ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Ikọ̀ yìí dé ilé ìtajà Market Square tó wà ní Lekki, gbogbo àwọn ọtí ẹlẹ́rìnròdò tí wọ́n ń tà níbẹ̀ ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá. Ọtí ẹlẹ́rìnròdò Schweppes, Brand Rubicon àti àwọn ohun mímu mìíràn ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Gbogbo àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé tí àwọn ikọ̀ yìí lọ kò yàtọ̀, gbogbo ọjà tí wọ́n dínwó rẹ̀ ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Ikọ̀ yìí ṣe àkíyèsí pé ẹ̀dínwó yìí ni kò jẹ́ kí àwọn èèyàn ó yẹ àwọn ọjà náà wò tí wọ́n fi ń rà á , wọ́n ní bóyá nítorí bí gbogbo nǹkan ṣe gbowó lérí ló fàá.
Ikọ̀ yìí ti fi àbájáde wọn ṣọwọ́ sí àjọ NAFDAC, ìgbésẹ̀ ni a ń retí báyìí.




