Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló bínú tán nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bode yìnbọn fún obìnrin kan lápá. Ìròyìn fi yé wa pé àwọn aṣọ́bodè Igbogbele ní Agbadarigi yìnbọn láìbìkítà ó sì ba obìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Hunsu Elizabeth lápá. Àpò ìbínú àwọn ọ̀dọ́ Igbogbele ni èyí bọ́ sí, wọ́n sọ iná sí ibùdó àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, èèfín ń ru tùù!
Àwọn èèyàn yìí tún kojú àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, wọ́n ń bèèrè lọ́wọ́ wọn ìdí tí wọ́n fi yìnbọn wọ́n sì tún mú wọn mọ́lẹ̀. Àwọn aṣọ́bodè bíi méje ni wọ́n mú mọ́lẹ̀ nínú fọ́nrán náà, wọn kò jẹ́ kí wọn ó wọ ọkọ̀ wọn débi tí wọn yóò le lọ.
Bákan náà ni a rí Hunsu lórí ibùsu-n nílé ìwòsàn tó ń japoró.
Sesi Whingan; ẹni tó jẹ́ aṣọ́bodè bu ẹnu àtẹ́ lu ìbọn tí àwọn aṣọ́bodè náà yìn, ó bá Hunsu kẹ́dùn ó sì tún ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tó burú jáì. Sesi wí pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ará Badagry máa kojú irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí.
Ó bá Hunsu dúpẹ́ pé ẹ̀mí rẹ̀ kò bá a lọ ó sì rọ àwọn ará àdúgbò láti ṣe sùúrù lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Ọ̀kan lèyìí nínú ogúnlọ́gọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àṣìta ìbọn tó ti ṣẹlẹ̀, díẹ̀ nínú wọn rèé.
Ọmọkùnrin ọmọ ọdún méjìlá kan ni àṣìta ìbọn ti ṣekú pa báyìí ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì ni wọ́n ń gbéná wojú ara wọn ní nǹkan bíi aago mẹjọ alẹ́ lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹta, oṣù Agẹmọ.
Wasiu; ìyẹn ọmọdékùnrin yìí lọ ra oúnjẹ lọ́dọ̀ olóúnjẹ kan tí wọ́n ń pè ní ìyá ìbejì ní ìsàlẹ̀ ilé rẹ̀ tó wà ní Olosha kí ó tó di pé ìbọn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà bà á tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Tale Amoo; ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò náà ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni àwọn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn, Wasiu sá sí abẹ́ isọ̀ kan nítorí ìpayà, ibẹ̀ náà ni ìbọn ti lọ bá a.
Amoo wí pé àwọn ọkọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà gbìyànjú àti sá lọ àmọ́ wọ́n rí mú nínú wọn.
Àwọn èèyàn tilẹ̀ ṣe aájò Wasiu dé ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó LUTH àmọ́ títì ni ilẹ̀kùn ilé ìwòsàn náà wà kó tó di pé ọmọ náà padà kú.
Àwọn ará àdúgbò wí pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ òkùnkùn máa yìnbọn pa èèyàn báyìí, wọ́n ké sí ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí i.
Kò tán síbẹ̀ o, jẹ́jẹ́ ni ọmọ kan jókòó sí iwájú ilé bàbá rẹ̀ kí ìbọn tó yà pa á.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra lẹ́yìn tí ìbọn bà á.
Òpópọnà Ifejike ní Gúùsù Onitsha ni èyí ti ṣẹlẹ̀. A gbọ́ pé ọmọkùnrin náà jókòó sí iwájú ilé àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí àwọn ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Agunechemba ń lé afurasí ọ̀daràn kan lọ, ọ̀kan nínú wọn yin ìbọn sókè àmọ́ ọmọ náà ló bà tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà fẹ́ sá lọ àmọ́ àwọn èrò àti àwọn ọlọ́jà ló dá wọn dúró tí wọ́n sì ní kí wọn ó gbé òkú ọmọ náà dandan. Wọ́n ní èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn ó yin ìbọn pa aráàlú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti mú àwọn afurasí méjì sí àhámọ́ báyìí.
Ìyẹn lápá kan, lápá kejì lórí ìbọn yìí kan náà, ọmọ ọlọ́pàá kan ṣèèṣì yìnbọn pa bàbá ẹ̀.
Ọmọdékùnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọdún mẹ́wàá lọ ti yìnbọn pa bàbá rẹ̀ tó jẹ́ rìpẹ́tọ̀ ọlọ́pàá.
Ìpínlẹ̀ Anambra ni èyí ti ṣẹlẹ̀, ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ọmọ náà ń fi ìbọn bàbá rẹ̀ ṣeré ni ìbọn náà bá yìn mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ba bàbá rẹ̀ lẹ́yìn ó sì tún ba àbúrò ọmọ yìí ní ọrùn ọwọ́.
Okolie Amechi ni orúkọ ọlọ́pàá yìí, nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, ó ti dágbére fáyé àmọ́ ọmọ kejì ṣì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra; Tochukwu Ikenga. Ó ṣe àlàyé pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra àti Nàìjíríà lápapọ̀ ń ṣe ìdárò ẹni ire tó lọ, ìyẹn Rìpẹ́tọ̀ Okolie Amechi tí ọmọ rẹ̀ ṣèèṣì yìnbọn pa nínú ilé rẹ̀.
Wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ìgbókùúsí wọ́n sì ti gba ìbọn náà pamọ́ fún àyẹ̀wò.
Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan ń fi ìbọn pààyàn, ọkọ̀ ni àwọn ẹ̀ka kan fi ń tẹ àwọn èèyàn pa lójú pópó.
Ti ìpínlẹ̀ Imo lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí burú jáì.
ỌKỌ̀ ÌJỌBA PA ÀWỌN EÈYÀN MÉJÌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ IMO.
Ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ẹ̀ka ètò àyíká ti ṣekú pa àwọn èèyàn méjì nígbà tí wọ́n ń sáré àsápajúdé.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Akachi ní Owerri, ìpínlẹ̀ Imo lọ́sàn-án ọjọ́ Ajé. À gbọ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ENTRACO náà sáré àsápajúdé ní èyí tó mú wọn kọlu ọ̀kadà kan àti èrò tó gbé, wọ́n mú wọn gùn mọ́lẹ̀ débi pé àwọn ẹni náà kú lójú ẹsẹ̀.
Chidiebube Okeoma; ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé pé àwọn ẹni náà ń lọ sí ọjà Alaba nígbà tí ọkọ̀ ENTARCO mú wọn gùn tó sì ṣekú pa wọ́n, ó wí pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú èyí máa ṣẹlẹ̀ àsìkò ti tó fún ìjọba láti wa egbò dẹ́kun fún àwo.n ẹ̀ka náà.
Nínú àwòrán ìjàm̀bá náà ni a ti rí ọ̀kan nínú àwọn ẹni náà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì wà nínú táyà ọkọ̀ nígbà tí orí èkejì fọ́ yángáyángá, inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni àwọn ẹni náà sùn.
Ẹ̀ka ENTRACO kò fèsì sí gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn aráàlú fi kàn wọ́n yìí wọn kò sì sọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà títí di àsìkò yìí.




