Bàbá olóògbé HERBERT WIGWE, Alàgbà Shyngle Wigwe àti ọmọ rẹ̀ kan tó n jẹ́ CHUKWUKA WIGWE ti gbé gbé ọ̀rọ̀ ìpíngún ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́. Wọ́n n bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ tẹ̀lé òfin ìpíngún láti jẹ́ kí alábòjútó máa darí àtiṣètò ogún HERBERT WIGWE.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ ogún náà kàn ni UCHE WIGWE, AIGBOJE AIG IMOUKHIEDE àti ọmọ kan ṣoṣo tó gbẹ̀yìn tọkọ-taya olóògbé náà, ọ̀dọ́mọdébìnrin ọmọ ọdún mérìndínlọ́gbọ̀n tórúkọ rẹ̀ n jẹ́ OTUTOCHI CHANNEL WIGWE.
Gẹ́gẹ́ bí òfin, alábòjútó ogún ni ilé ẹjọ́ máa ń yàn láti ṣe àmójútó dúkìá òkú tí kò ní ìwé ìpíngún kí ọlọ́jọ́ tó ó dé tàbí tí ìfanfà bá wà nínú ètò ìpíngún.
Adájọ́ A.O ADÉYẸMÍ ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Èkó ló fi ìwé ìpẹ̀jọ́ náà rànṣẹ́.
Lóṣù kẹwàá ọdún 2024 la rí i kà pé pasitọ SHYNGLE WIGWE, ẹni àádọ́rùn-ún ọdún àti ẹbí rẹ̀ kò fi taratara faramọ́ ọ́n bí ètò ìpíngún ọmọ rẹ̀ ti lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pe ọ̀rọ̀ náà ní àhesọ̀ nígbà náà,síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ ti hàn ní gbàgede báyìí lórí ẹ̀rọ ayélujára nítorí ọmọ pàápàá kò fi ọ̀rọ̀ náà bò mọ́.
Lásìkò ìpẹ̀jọ́, àwọn agbẹjọ́rò rọ àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn kí wọ́n ṣe é ní bònkẹ́lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó rọ̀ mọ́ ẹ̀tọ́ àwọn èwe nílẹ̀ Nàìjíríà abala 128 tọdún 2007. Aṣojú àwọn tọ́rọ̀ kan_ AIGBOJE AIG IMOUKHIEDE,CHRIS WIGWE, OTUTOCHI WIGWE ní Adájọ́ àgbà PAUL USORO fọnmú pé dandan gbọ̀n kí àwọn fẹjú ẹjọ́ sí gbàgede fún aráyé gbọ́ èyí kò fi bẹ́ẹ̀ dùn mọ́ agbẹjọ́rò àwọn ẹbí nínú, ìyẹn agbẹjọ́rò àgbà A.O EGHOBAMIEN
Ọjọ́ kẹfà oṣù yìí ni Adájọ́ àgbà A.O ADEYEMI fagilé ìpẹ̀jọ́ CHRISTAIN WIGWE àti Alàgbà SHYNGLE WIGWE fún yíyan alábojútó fìdí hẹẹ́ Ogún. Bàbá àgbà ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé ìròyìn kan ti gbé e pé bóyá torí kín n le è lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdá lọ́nà ogún ọmọ mi ni mò ṣe n ṣe èyí ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Ikú olóògbé ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ ACCESS, HERBERT WIGWE bani lọ́kàn jẹ́ púpọ̀ nígbà tí a gbọ́ lọ́dún tó kọjá, kódà! ikú àgbọ́-sọgbánù lójẹ nílẹ̀ yìí. Ọ̀kàn lára àwọn ilé ìfowópamọ́ gbòógì ni ACCESS nílẹ̀ Nàìjíríà.
Àwọn mẹ́fà ni wọ́n jóná nínú bàlúù EC130 lọ́jọ́ kẹsàn án oṣù kejì ọdún 2024 ní ìlú Kalifóníà orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ènìyàn náà ni HERBERT WIGWE, ÌYÀWÓ, ỌMỌ, Ọ̀rẹ́ olóògbé àti àwọn awakọ òfurufú méjì ló jóná keérú lásìkò tí wọ́n ń darí bọ̀ láti pápákọ̀ òfurufú Palm Springs, ìran eré bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ ni wọ́n lọ wò ní Las Vegas.
Àjókù eérú olóògbé àti ẹbí rẹ̀ ni wọ́n sin sí ìlú rẹ̀ ní Isíokpo ìpínlẹ̀ Rivers lóṣù kẹsàn-án ọdún tó kọjá, gbajúgbajà oníṣòwò, ọ̀tọ̀kùlú, olóṣèlú pàápàá ọlọ́rọ̀ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Adúláwọ̀, Alinko Dangote péjú pésè láti ṣẹ̀yìn olóògbé, ó sì fi ọ̀pá ìfọpo rẹ titun sọrí olóògbé.
Ọdún 1989 ni olóògbé Herbert Wigwe dá ilé ìfowópamọ́ Access sílẹ̀ tí ó sì gbèrú dáadáa títí di ọdún 2018 nígbà tí ó bá pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ DIAMOND dòwò pọ̀.
Ilé ìfowópamọ́ Access ṣì n gbèrú lórílẹ̀ èdè Kenya, South Africa àti Botswana.
Hùn ùn! Rírò ni tènìyàn, ṣíṣe ń bẹ lọ́wọ́ Èlédùmarè, Herbert Wigwe ń gbà á lérò láti dá ilé ìfowópamọ́ mìíràn sílẹ̀ ní ilẹ̀ Asia kí ọdún 2024 tó ó parí ṣùgbọ́n ikú ló yọwọ́ rẹ̀ láwo