Ọlọ́pàá kan ni ó ṣàdédé yìnbọn pa ara rẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá nasarawa.
Ọjọ́ kẹrin, oṣù Ebìbí yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ. Ọlọ́pàá náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Dogala Akolo Moses lọ sí ibi tó ti ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ náà ló wà tó sì ń lọ tó ń bọ̀ ní agọ́ ọlọ́pàá Mada tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Eggon ní ìlú Nasarawa.
Ẹ̀ẹ̀kan náà ni àwọn ọlọ́pàá ẹgbẹ́ rẹ̀ gbọ́ ìró ìbọn gbàù! Nígbà tí wọn yóò dé inú yàrá tí ìró náà ti jáde, Akolo wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú ìbọn rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ohun tó le mú kí ó yin ìbọn pa ara rẹ̀ kò yé ẹnikẹ́ni bẹ́ẹ̀ sì ni kò kọ ìwé kankan sílẹ̀.
Ẹnìkan tó wà ní àgọ́ ọlọ́pàá lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé àwọn èèyàn ń gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn lọ́jọ́ ni wọ́n gbọ́ ìró ìbọn, nígbà tí wọn yóò fi dé inú yàrá tí ìbọn ti dún, Akolo Moses ni wọ́n bá tó ti yìnbọn pa ara rẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Ọ̀gbẹ́ni Rahman Nansel fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé Akolo yìnbọn pa ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́, kàyéfì ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ nítorí pé kò fu ẹni kankan lára tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, àìkọ̀wé sílẹ̀ rẹ̀ tún mú kí ọ̀rọ̀ náà ó ta kókó.
Nansel ṣe àlàyé pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti rídìí òkodoro lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ Kejì nínú ọdún yìí nìkan. Ọ̀sẹ̀ yìí náà la mú ìròyìn igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger tó pa ara rẹ̀ wá.
Ọjọ́ àbámẹ́ta ni bàbá Shafiu Bawa wọ yàrá ọmọ rẹ̀ tó sì bá a tó ń mì dirodiro lójú okùn.
Bàbá yìí ké gbàjarè, àwọn ọlọ́pàá ẹgbẹ́ rẹ̀ dé lẹ́yẹòsọkà, wọ́n tú Bawa kúrò lójú okùn wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Kontogora.
Ibẹ̀ ni Dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Bawa ti dágbére fáyé.
Usman Bawa; ẹni tíí ṣe bàbá Shafiu Bawa ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí tí wọ́n sì dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ohun tó le mú kí Shafiu ó pa ara rẹ̀ kò yé ẹnikẹ́ni kódà kò yé bàbá rẹ̀ gan-an.
Àwọn ọlọ́pàá ti yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀ kí wọ́n le ṣètò ìsìnkú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀sìn mùsùlùmí.
Ọdún tó kọjá náà ni igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá nni; Gbolahan Oyedemi pa ara rẹ̀ sínú ilé rẹ̀ ní Oyo.
Alágbọn ní èkó ni àgọ́ Gbolahan, ó máa ń lọ sí ilé rẹ̀ àti ilé mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní Oyo lọ ṣe ọdún Àjínde.
Àmọ́ ní oṣù Igbe ọdún tó kọjá yìí, Gbolahan dé sí ilé rẹ̀ ní Oyo gẹ́gẹ́ bíi ìṣe rẹ̀ ó sì yẹ kó lọ sí ilé mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àmọ́ ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọn ó máa lọ ilé wọn.
Èyí kò ṣẹlẹ̀ rí àmọ́ wọn kò le béèrè ìdí, oníkálukú wọn gba ilé wọn lọ tán ni Gbolahan wọ inú ìyẹ̀wù rẹ̀ lọ tó sì pokùn so.
Ohun tó le mú kí Gbolahan ó gba ẹ̀mí ara rẹ̀ kò yé ẹnikẹ́ni kódà kò yé àwọn ẹbí rẹ̀ gan-an.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nígbà náà wọ́n sì wí pé ìwádìí yóò lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá náà ti ń gba ẹ̀mí ara wọn, ọdún 2020 ni ọlọ́pàá kan náà pòkun so sínú àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Okon Essien ni orúkọ ọlọ́pàá yìí, òun àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta kan mú àwọn afurasí mẹ́rin tí ní ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote tó wà ní Akodo, afurasí ni àwọn èèyàn yìí àmọ́ níṣe ni Okon yìnbọn pa ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Hassan Stanley.
Wọ́n mú Okon sí àhámọ́ ní Pàntí, inú àhámọ́ yìí náà ló ti fi ṣòkòtò ìdí rẹ̀ pokùn so.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn máa ń gba ṣòkòtò àwọn afurasí torí kí wọ́n má baà fi pokùn so àmọ́ àwọn fi Okon sílẹ̀ láìmọ̀ pé yóò pokùn so.
Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ti pa ara wọn yálà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nílé kìí ṣe kèremí, ó yẹ kí ìjọba ó wá nǹkan ṣe síi.
Ọ̀rọ̀ ti Akolo yìí rí bákan lára àwọn ẹbí àti akẹgbẹ́ rẹ̀, ó dé sí ibi iṣẹ́ ó sì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Kò sí ẹni tó fura pé nǹkan kan ń da ọkàn rẹ̀ láàmú.
Ohun tó wá le mú kí ó yin ìbọn pa ara rẹ̀ ṣe àwọn èèyàn ní kàyéfì, ìgbà tí yóò rú gbogbo rẹ̀ lójú, kò kó ìwé kankan sílẹ̀ tó le ṣe ìrànwọ́ fún ìwádìí náà.
Ẹnìkan tó wà ní àgọ́ ọlọ́pàá lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé àwọn èèyàn ń gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn lọ́jọ́ ni wọ́n gbọ́ ìró ìbọn, nígbà tí wọn yóò fi dé inú yàrá tí ìbọn ti dún, Akolo Moses ni wọ́n bá tó ti yìnbọn pa ara rẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Ọ̀gbẹ́ni Rahman Nansel fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé Akolo yìnbọn pa ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́, kàyéfì ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ nítorí pé kò fu ẹni kankan lára tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, àìkọ̀wé sílẹ̀ rẹ̀ tún mú kí ọ̀rọ̀ náà ó ta kókó.
Nansel ṣe àlàyé pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá yóò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ láti ríi dájú pé ejò kò lọ́wọ́ nínú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.