Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì ní abúlé Obelle ní ìjọba ìbílẹ̀ Emohua ní ìpínlẹ̀ Rivers, èèyàn mọ́kàndínlógún ló pàdánù ẹ̀mí wọn láìròtẹ́lẹ.
Ẹgbẹ́ òkùnkùn Deybam àti icelanders kọlu ara wọn lọ́jọ́ Ọjọ́rú àti ọjọ́ àìkú lórí pé èmi jù ọ́ ìwọ kò jù mí, ìjà náà burẹ́kẹ ó sì mú ẹ̀mí lọ.
Abúlé Omelle dá páropáro, àwọn èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Ìròyìn fi yé wa pé ìjà àgbà yìí ti rodò lọ mumi láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn, ó kàn tún dédé gbéra sọ lọ́jọ́rú nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kìíní pa méje nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kejì.
Èyí ni àwọn aráàlú ṣì ń rán lọ́wọ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n pa lára wọn fi ya wọ abúlé náà lọ́jọ́ àìkú láti rán oró, wọ́n pa tó èèyàn méjìlá lọ́jọ́ náà, gbogbo ìlú kan bóbó.
Ará abúlé kan tó pe orúkọ rẹ̀ ní Kingsley sọ ohun tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kingsley ṣe àlàyé pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Deybam àti icelanders ti máa ń ja ìjà àgbà lágbègbè náà tipẹ́, èyí tó ṣẹlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí lé kenkà.
Ọjọ́ àìkú ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n pa lára wọn lọ́jọ́rú ya wọ abúlé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ inú ilé àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kejì.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kejì náà tú jáde, ìbọn ń ró lákọlákọ bíi ti ogun kírìjí ìgbà náà lọ́hǔn.
Àwọn aráàlú ké gbàjarè sí ìjọba àti àwọn ọlọ́pàá láti gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò yìí, wọ́n pè fún ìdásí ìjọba nínú ọ̀rọ̀ náà.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers, agbẹnusọ wọn; Grace Iringe-koko wí pé àwọn gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ṣe àlàyé pé owó tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ìfọpo tó wà ní ìlú náà ló fa ìjà náà. Àwọn ọlọ́pàá wí pé àwọn kò tíì mú ẹnikẹ́ni àmọ́ àwọn ti wà ní ibẹ̀ láti pẹ̀tù síi.