Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́; Ọ̀gbẹ́ni Olatunji Alausa ti ganu sí máìkì ṣe àlàyé lórí ọ̀rọ̀ tó ń jà ràìnràìn lórí afẹ́fẹ́ pé àwọn ti fagi lé ìpele ẹ̀kọ́ girama kékeré àti àgbà.
Àlàyé yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu adarí àtẹ̀jáde ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́; Folasade Boriowo pé àbá lásán ni mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ dá kò tíì di àṣẹ.
Ó ṣe àlàyé pé níbi àpérò kan tó wáyé lánàá ni ọ̀gbẹ́ni Olátúnjí Alausa ti dábàá pé kí wọn ó fagi lé ètò ẹ̀kọ́ tí a ń lò lọ́wọ́ ìyẹn ọlọ́dún mẹ́fà alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ọdún mẹ́ta sẹ́kọ́ndìrì kékeré, ọdún mẹ́ta sẹ́kọ́ndìrì àgbà àti ọdún mẹ́rìn ìwé gíga 6-3-3-4.
Àbá náà wí pé kí wọn ó sọ ètò ẹ̀kọ́ di ọdún méjìlá àti ọdún mẹ́rin ìwé gíga, 12-4.
Nípa báyìí, ìdánwò òpin ìpele sẹ́kọ́ndìrì kékeré láti wọlé sí sẹ́kọ́ndìrì àgbà kò ní wáyé mọ́.
Ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ ṣe àlàyé pé àbá lásán ni èyí lásìkò yìí kò tíì di mímúṣẹ kí àwọn èèyàn ó yé gbé e pòòyì ẹnu pé àwọn ti ṣe àtúntò ètò ẹ̀kọ́.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé kí àbá náà ó tó le wá sí ìmúṣẹ, àwọn ẹ̀ka tí ọ̀rọ̀ kan gbogbo yóò ṣe àpérò wọn yóò sì fi ọwọ́ síi, nítorí náà kí a jẹ́ kí ogun ó mí lórí àtúntò ètò ẹ̀kọ́.