ỌKỌ̀ IṢU TẸ KẸ̀KẸ́ MARUWA NÍ Ẹ̀PẸ́, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ – èèyàn kan kú nígbà tí àwọn mẹ́ta wà ní ẹ̀sẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run nínú ìjàm̀bá tó wáyé ní oríta Aiyetoro ní Ẹ̀pẹ́, ìpínlẹ̀ Èkó.
Ìjàm̀bá náà wáyé láàrin ọkọ̀ àjàgbé kan tó kó iṣu àti kẹ̀kẹ́ maruwa kan, ọkọ̀ àjàgbé yìí tẹ kẹ̀kẹ́ maruwa náà fẹ́rẹ̀ tán pátá, ojú ẹsẹ̀ ni èèyàn kan ti kú nígbà tí àwọn mẹ́ta yòókù fi ara pa yánnayànna.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ adarí ọ̀rọ̀ ìlú àjọ LASTMA ni pé kẹ̀kẹ́ náà wà ní ibùdó tó ń kó èrò nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé náà pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ wó o mọ́ ibùdó tó ti ń kó èrò tirẹ̀ jẹ́jẹ́.
Àwọn èrò mẹ́rin ló wà nínú kẹ̀kẹ́ náà, kí awakọ̀ ó darapọ̀ mọ́ wọn kí wọ́n sì máa lọ ni ìjàm̀bá náà wáyé. Àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ LASTMA tó wà ní ìtòsí ni wọ́n mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ FRSC náà darapọ̀ mọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, àwọn panápaná náà kò gbẹ́yìn, wọ́n yọ àwọn mẹ́ta náà láàrín èérú irin tí wọ́n há sí.
Ilé ìwòsàn ìjọba Ẹ̀pẹ́ ni wọ́n kó wọn lọ fún ìtọ́jú nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA darí ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní oríta náà.
Ọ̀gá àgbà àjọ LASTMA; Olalekan Bakare-Oki fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn ẹni tó farapa àti ẹni tó kú náà.
Ó wí pé ìwádìí yóò wáyé lórí ìjàm̀bá náà òfin yóò sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.
ỌKỌ̀ IṢU TẸ KẸ̀KẸ́ MARUWA NÍ Ẹ̀PẸ́, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ
Ìjàm̀bá mìíràn tó tún burú bíi èyí ni ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH mẹ́fà tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn:
Ilé ìwé gíga Ladoke Akintola LAUTECH tó wà ní Ogbomoṣo ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ báyìí látàrí pé wọ́n pàdánù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoṣo.
Nínú àtẹ̀jáde tí Olùgbaniwọlé ilé ìwé náà; Olayinka Balogun bu ọwọ́ lù ni ó ti ṣe àpèjúwe ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bíi ọ̀fọ̀ àti àdánù ńlá fún ilé ìwé LAUTECH lápapọ̀.
Orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni Shehu Hamza, Idris Jamila, Abdulraheem Hamza, Blessing Kevwe, Owoicho Elizabeth àti Aroke Victoria. Àwọn mẹ́fẹ́ẹ̀fà jọ wọ ọkọ̀ láti ìpínlẹ̀ Niger ni lọ sí Ogbomoṣo àmọ́ ọkọ̀ náà ní ìjàm̀bá nígbà tó kọjá Ilorin sí ojú ọ̀nà Ogbomoṣo, gbogbo wọn ló pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ni àwọn mẹ́fà náà wà nílé ìwé, wọ́n sì tún wà ní ìpele tó gbẹ̀yìn. Ìdánwò ìparí ẹ̀kọ́ wọn tí wọn yóò kẹ́kọ̀ọ́ parí ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe tí wọ́n fi pàdé ikú òjijì náà.
Nínú ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dun ni Olayinka ti sọ pé òun bá àwọn òbí àti ẹbí àwọn ọmọ náà kẹ́dùn, yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́, wọ́n ní ìrètí ní ọjọ́ ọ̀la láti máa ṣe ìtọ́jú àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa dóòlà ẹ̀mí àmọ́ ikú fi wọ́n dá wa lóró.
Balogun bá àwọn òbí wọn kẹ́dùn ó sì gbà á ládùúrà pé Ọlọ́run yóò rọ́ wọn lójú.

Itokasi Aworan : PunchNG
Ìjánu ọkọ̀ nígbà gbogbo, ìjàm̀bá tí ìjánu ọkọ̀ ti fà kìí ṣe díẹ̀, kò tíì ju ọ̀sẹ̀ kan lọ tí ìjàm̀bá kan wáyé ní oríta ekoro, a mú ìròyìn náà wá pé:
Nígbà tí àwọn èèyàn ṣì ń japoró ìjàm̀bá ọkọ̀ agbépo tó wáyé ní ẹnu ìloro ìpínlẹ̀ Ogun lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọkọ̀ agbépo mìíràn tú tẹ àwọn èèyàn pa ní oríta Ẹkọ̀rọ̀, ojú ọ̀nà Meirn ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ agbépo náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ni ó bá rọ́ lu àwọn ìsọ̀ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ojú pópó náà, gbogbo àwọn tí wọ́n ń ta ọjà ní ìtòsí ibẹ̀ ni ó fara gbá nínú ìjàm̀bá náà.
Nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Ẹtì ni ìjàm̀bá náà wáyé ní oríta Ẹkọ̀rọ̀, ọkọ̀ agbépo náà kọ́kọ́ tẹ ọkọ̀ Corolla kan kí ó tó wọ́ ọ mọ́ àwọn ìsọ̀ náà.
Ìjàm̀bá náà pọ̀ gan-an tí àwọn ìsọ̀ náà wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, èèyàn kan ló kú lójú ẹsẹ̀ àmọ́ àwọn tó farapa lé ní mẹ́rin.
Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ adarí ẹ̀ka ọ̀rọ̀ ìlú ilé iṣẹ́ LASTMA ló ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ ní kíá, wọ́n gbé òkú èèyàn kan wọ́n sì yọ àwọn mẹ́rin mìíràn tí wọ́n há sínú àwọn èérún ọkọ̀ àti ìsọ̀ náà. Ó gbà wọ́n lómi díẹ̀ kí wọ́n tó rí àwọn èèyàn náà yọ níbi tí ìjàm̀bá náà burú dé. Kò dájú pé àwọn ẹni náà yóò fi ẹsẹ̀ wọn rìn lọ́dún yìí níbi tó burú dé.
Ọ̀rọ̀ Taofiq tẹ̀síwájú pé àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA darí ọkọ̀ ní agbègbè náà láti dín súnkẹrẹ-fàkẹrẹ̀ ọkọ̀ kù, wọ́n ṣe ìtọ́jú òkú ẹni tó kú náà wọ́n sì tún ṣe ìtọ́jú àwọn tó farapa ṣáájú kí ọkọ̀ agbáláìsàn tó dé.
Lẹ́yìn tí ọkọ̀ agbáláìsàn kó àwon ẹni náà lọ sílé ìwòsàn ni wọ́n wọ́ ìyókù ọkọ̀ agbépo náà kúrò lójú pópó tí wọ́n sì kó ìyókù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, òun kò fẹ́rẹ̀ ṣẹ́kù tààrà ní tirẹ̀, ìtẹ̀kutẹ̀ ni ọkọ̀ agbépo náà tẹ̀ ẹ́.
Ọ̀rọ̀ yìí dé etígbọ́ adarí àgbà àjọ LASTMA; Olalekan Bakare-Oki, ó banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó sì bá àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n pàdánù èèyàn wọn kẹ́dùn.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Bakare rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ wọn kí wọ́n tó gbé e sí ojú pópó, ó ní púpọ̀ nínú àwọn ìjàm̀bá báyìí ló jẹ́ pé awakọ̀ ló dágúnlá àwọn àpẹẹrẹ tí ọkọ̀ náà ti ń fún un.
Ó ṣe ìlérí pé àwọn yóò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìjàm̀bá náà, ẹni tí aje rẹ̀ bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ojú winá òfin.




