Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ arákùnrin kan tó máa ń hú òkú tà ní ìlú Ìbàdàn.
Àwọn kan ló ta àwọn ọlọ́pàá lólobó tí wọ́n fi lọ ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ tó wà ní Muslim, oríṣìí nǹkan ni wọ́n bá nílé rẹ̀, wọ́n bá orí obìnrin kan àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrùn ọwọ́ àti àwọn eegun gbígbẹ mìíràn wọ́n bá nínú ike ọ̀dà tó tọ́jú ẹ̀ sí nínú ilé rẹ̀ tó ń gbé náà.
Okùnrin yìí jẹ́wọ́ wí pé òun ṣẹṣẹ̀ hú òkú obìnrin náà ní itẹ́ òkú kan tó wà ní Awa-Ijebu ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ijebu ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn ọlọ́pàá tẹ̀lé arákùnrin yìí dé itẹ́ òkú náà wọ́n sì ríi pé ibẹ̀ ló ti hú òkú obìnrin náà lóòótọ́.
Bákan náà ló ka èkejì rẹ̀ tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ náà.
Èkejì rẹ̀ yìí náà jẹ́wọ́ pé àwọn jọ ń hú òkú tà ni àwọn sì ní àwọn oníbàárà tó pọ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn aláṣẹ itẹ́ òkú Awa-Ijebu náà láti pèsè ààbò tó nípọn sí ibẹ̀, bákan náà ni wọ́n tari àwọn afurasí méjèèjì náà lọ sí ẹ̀ka tọ́rọ̀ kàn.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó fara pẹ́ èyí…
Èyí kìí ṣe ìròyìn àkọ́kọ́ nípa àwọn tí wọ́n ń hú òkú tà, kọ̀pẹ́kòpẹ́ yìí náà ni ọwọ́ tẹ Adelani tó jẹ́ ògbóǹtarìgí nínú iṣẹ́ wíwú òkú tà. Ìpínlẹ̀ Ogun ni Adelani tẹ̀dó sí, ibẹ̀ náà ni ó ti ń dábírà nínú wíwú òkú tà. A ríi gbọ́ pé ‘Adelani Oriyomi; ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé ìpínlẹ̀ Ogun So-safe tẹ̀ níbi tó ti hú orí òkú jáde nínú sàrê rẹ̀.
Itẹ́ òkú tó wà ní Kere, Obada oko ní Abeokuta tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun ni ọwọ́ ti tẹ Oriyomi o. Ní òru ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Ṣẹẹrẹ yìí ni Adelani kó àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ lọ sí itẹ́ náà láti ṣe bíi ìṣe rẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ So-safe kófìrí rẹ̀ wọ́n sì tẹ̀lé e, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ́ sàrê náà, ìgbà tó yá, ó dáwọ́ dúró nítorí ó fura pé àwọn kan ń ṣọ́ òun, nígbà tó ríi pé ilẹ̀ dá ló tẹ̀ síwájú tó sì hú orí òkú náà jáde.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ So-safe jáde síi, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ.
Adelani ní kí wọn ó má wulẹ̀ làágùn jinna, ẹ̀wọ̀n kìí ṣe àjojì sí òun, bíi ìgbà tí èèyàn lọ sí ẹsìkọ́ṣọ́nù ni ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣe jẹ́ fún òun nítorí pé òun ti ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méjì kan àti ọdún mẹ́fà kan rí lórí pé òun hú orí àwọn òkú yìí kan náà.
Adelani ṣe àlàyé pé àwọn oníbàárà òun ló béèrè fún ọjà ni òun ṣe lọ hú èyí mọ́ èyí tó wà nílẹ̀ láti le tàá fún wọn.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé òun kò mọ iṣẹ́ mìíràn ṣe ju kí òun ó hú orí òkú tà lọ. Ó ti pẹ́ tí ó ti ń ṣe é ó sì ti ta orí bíi mẹ́wàá láàrin ọdún tó kọjá sí ìsìn yìí.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ So-safe ti fa Adelani lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ pẹ̀lú orí òkú tó hú náà, wọ́n ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn onílé láti máa ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí àwọn ayálégbé tí wọ́n bá fẹ́ gbà sílé.
Nígbà tí wọ́n mú àwọn èyí nínú ọdún yìí, wọ́n mú arákùnrin kan náà lọ́dún tó kọjá, òkú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tiẹ̀ lòun lọ hú níbi tí wọ́n sin ín sí.
A gbọ́ pé Muyideen Raimi lọ sí sàrê ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Sulaiman Aromokun ní isale Ijebu, Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Inú ọgbà ilé mọ̀lẹ́bí Aromokun ni wọ́n sin ọmọ náà sí kí Raimi ó tó lọ hú u jáde tó sì gé orí rẹ̀ lọ. Ọ̀rẹ́ rẹ̀; Sumaila tí wọ́n jọ hú orí ọmọ náà fẹsẹ̀ fẹ́ẹ nígbà tí ọká fó.
Kò tán síbẹ̀ o, nínú ọdún tó kọjá yìí náà ni ọwọ́ tẹ Adekunle àti Lukman tó ṣe pé èèyàn ni àwọn máa ń pa tà ní Ìbàdàn.
Nínú oṣù Ògún ni wọ́n tan Adekola Sofiq lọ sí Moniya tí wọ́n sì pá á, wọ́n ta orí àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà fún Rashidat Akanji; ẹni tó ní ìsọ̀ sí ọjà Oje.
Nínú ilé Adekunle ni wọ́n ti bá àwọn ẹ̀yà ara Adekola tó kù níbi tó ṣe é lọ́jọ̀ sí. Adekunle jẹ́wọ́ pé òun ti gíríkì nínú iṣẹ́ apanità tó ṣe pé òun kò mọ nǹkan mìíràn ṣe mọ́.
Lára àwọn oníbàárà rẹ̀ tó dárúkọ ni Muniru Salawudeen, Rashidat Akanji àti Obaleye Sanmi. Wọ́n jẹ́wọ́ pé kọ́sítọ́mà dáadáa ni Adekunle, kò sí ẹ̀yà ara tí àwọn fẹ́ tí kò ní.
Iṣẹ́ apanità ti wá gbilẹ̀ síi láàrin àwọn èèyàn káàkiri, ẹnu lọ́lọ́ yìí ni ọwọ́ tẹ AbdulRahman náà tó sẹkú pa Hafsoh; ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ní Ìlọrin tó sì tún gé e níkěníkě.
AbdulRahman ti fojú ba ilé-ẹjọ́ lẹ́ẹ̀mejì báyìí àmọ́ kò tíì forí sọ ibi kan. Ojoojúmọ́ ni a ń gbọ́ nǹkan titun titun nípa bí ó ṣe pa ọmọ náà.
Àwọn òbí Hafsoh
Àwọn òbí Hafsoh ń fi ojoojúmọ́ béèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn Hafsoh. Ikú rẹ̀ wọ̀ wọ́n ní akinyemi ara.
Ọ̀rọ̀ AbdulRahman yìí ti mi orí ìkànnì ayélujára tìtì, àwọn èèyàn fẹ́ mọ ibi tí yóò yọrí sí, wọ́n sì ń retí ìdájọ́ òdodo láti ọ̀dọ ìjọba.
Ipò tí ìlú wa wà báyìí.
Kò sí ẹni tó mọ ẹní tó ń ṣe iṣẹ́ ibi nítorí pé wọn kò kọ ọ́ síwájú orí, ẹ jẹ́ ká máa ṣọra, a kò ní bọ́ sọ́wọ́ o, àmín.
4
Discussion about this post