Wàhálà ńlá ló ti gbilẹ̀ kan-an báyìí ní Ìpínlẹ̀ Rivers nítorí ìjọba pàjáwìrì tí Ààrẹ Tinúubú kéde rẹ̀ níbẹ̀ láìpẹ́ yìí. Ìkéde náà wáyé nítorí àwọn ẹ̀sùn kàbìtì-kàbìyì; àwọn ‘gbékunmì’ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan gómìnà Fubara ti Ìpínlẹ̀ Rivers náà.
Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ní pé òun ló ṣe okùnfà bí wọn ṣe wó ilé ìgbìmọ̀ Așòfin ìpínlẹ̀ náà tó sì kùnà láti tún un kọ́ láti bí ọdún kan.
Șé wọ́n ní ẹni a tìràn mọ́ kò gbọdọ̀ adákẹ́, kíá ni Fubara náà dá ẹ̀sùn padà síbi tó ti wá, ni ewúrẹ́ rẹ̀ bá bojú wẹ̀yìn, tó sì fi ẹ̀sùn fún ẹlẹ́sùn. Nínú àwíjàre rẹ̀; Fubara ní wíwó tí wọ́n wó ilé ìgbìmọ̀ Așòfin kò ní ọwọ́ òṣèlú tàbí ẹ̀tanú nínú rárá, bí àwọn kan ṣe ń gbé e káàkiri tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ náà di bámìíì. Ó ní ògiri ilé ìgbìmọ̀ Așòfin náà tí di pàkúté ikú, ó sì nílò káwọn tún un ṣe dáadáa kó bá tòde-òní mu.
Gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn tá a gbọ́, Fubara tẹnu mọ́ ọn pé gbogbo ìgbésẹ̀ tóun gbé lórí atúnkọ́ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin náà, fún àǹfààní ará ìlú ni; kì í ṣe nítorí àtigbẹ̀san ìjà òṣèlú gẹ́gẹ́ bí àwọn gbékèé-dìde ṣe ń gbé e káàkiri, tí wọ́n sọ òrọ́ náà dorin, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ káàkiri òréré.
Ó ní ó ṣe òun láàánú pé ojú burúkú ni àwọn kòlọ̀rọ̀sí kan fi ń wo ìṣèjọba òun; tí wọ́n sì ń fi ẹnu àbùkù tojọ́ òun kiri. Ó ní bẹ́ẹ̀ látìgbà yìí wá ni ìjọba òun ti fààyè gba ìfikùnlukùn pẹ̀lú ará ìlú tó bá ní ohun kan láti sọ fóun. Ó ní gbagada ni ilẹ̀kùn ìṣèjọba òún ṣí sílẹ̀
Fubara tẹ̀ síwájú nínú àlàyé rẹ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni pé lójú ọ̀tá ẹni, a ò lè pòdù ọ̀yà. Ó ní Nyesom Wike tóun gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ ni Èṣù lẹ́yìn ìbejì ìjọba, tó sì gbin irúgbìn wàhálà òṣèlú láti sọ òun di aláìmọ̀-ọ́n-ṣe mọ́. Ó ní Wike fàgbò féégún lóòótọ́, àmọ́ kò jọ̀wọ́ okùn rẹ̀ rárá ni. Ó ní Wike fẹ́ẹ́ máa gbé Abuja, kó tún jẹ́ aláṣẹ ìjọba Rivers bákan náà.
Fubara ní èyí gan-an ló ń jẹ́ kí iná ìjọba òun ń kúregbé, kúregbè, tó sì dà bí ẹni pé òun ò fẹ́ rí ìjọba náà se dà bí àrà.
Fubara gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé orísun wàhálà ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers ni ojú ìmàle Wike tí ò kúò lọ́tí. Ó ní Wike kò fààyè gba olórí titun láti ṣèjọba bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. Ó ní èyí gan-an ló ń fa rúkè-rúdò bá ojú ọjọ́ òṣèlú àti ìṣèjọba Ìpínlẹ̀ Rivers lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.
Gbogbo rúgúdù yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kédé ìpínlẹ̀ Rivers ní ìpínlẹ̀ pàjáwìrì tó sì pàṣẹ kí ìjọba ológun ó gbadé. A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kéde ìpínlẹ̀ Rivers ní ìpínlẹ̀ pàjáwìrì lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. Oṣù mẹ́fà ni ààrẹ wí pé kí Gómìnà Similayi Fubara ó lọ lò nílé pẹ̀lí igbákejì rẹ̀ Ngozi Odu àti gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà.
Ààrẹ sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìgbésẹ̀ yìí pọn dandan láti mú kí gbogbo hílàhílo tó ń ṣẹlẹ̀ ní láàrin Gómìnà àti àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ó rodò lọ mumi.
Ìlú kò le wa kò má ní olórí, nígbà tí Siminalayi Fubara ó máa fitan ewúrẹ́ jiyan jẹkà pẹ̀lú àwọn ebi rẹ̀ lágbàlá rẹ̀, Ibot-Ette Ibas ni ààrẹ yàn láti máa delé dè é. Ajagunfẹ̀yìntì ni Ibas, òun ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers fún oṣù mẹ́fà náà.
Ní kété tí Ààrẹ Tinubú kéde ìjọba pàjáwìrì ní Ìpínlẹ̀ Rivers ni gómìnà Ìpínlẹ̀ náà gbé e bẹ́, tó sì di àwátì, tí èèyàn ò lè sọ pàtó ibi tó wà báyìí. Ṣé gẹ́rẹ́ tí ìjọba Gómìnà Siminalayi Fubara bẹ̀rẹ̀ ní Rivers ni òun pẹ̀lú Wynson Wike Ọ̀gá rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìforí-gbárí, tí nǹkan ò sì fara rọ nítorí fànfà tó wà láàárín Fubara àti Wike tó jẹ́ Mínístà fún Olú ìlú ilẹ̀ yìí tó wà ní Àbújá. Fànfà náà tí ń lọ sí ibi tí àgbá tí fẹ́ẹ́ bú; tí kugú fẹ́ẹ́ bẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìjọba pàjáwìrì yìí ni Tinubú kéde, èyí tí ó ti fòpin sí ìṣèjọba gómìnà Fubara; ìjókòó àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin àti àwọn alákòóso ijoba rẹ̀ gbogbo. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi yé wa pé ìpàdé ni gomina Fubara ń ṣe lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àlejò kan nígbà tí ìkéde náà dé bá a. Kíá náà ni Fubara ṣe páá-pàà-páá, tó fòpin sí ìpàdé náà, tó sì fi ilé ijoba sílẹ̀ láìsọ pàtó ibi tó forí lé. Òun àti àwọn abẹ́sinkáwọ́ rẹ̀ ló sì jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn jáde.
Ní kété tí wọ́n kéde ètò ìṣèjọba pàjáwìrì náà ni a rí í tí wọ́n yára pààrọ̀ gbogbo àwọn Ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó wà nílè ìjọba ; a ò sì tí ì mọ awọn tó pàṣẹ irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. A sì tún gbọ́ ọ pé àwọn òṣìṣẹ́ EFCC tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ijoba kọ̀ọ̀kan lórí gbogbo fànfà tó gba ètò ìjọba Fubara náà. Gbogbo nǹkan ló gbóná janjan báyìí ní Ìpínlẹ̀ Rivers kò fara rọ rárá’
Tọ̀, Fubara ti wí tẹnu rẹ̀ báyìí, ibò lẹ rò pé yóò bá yàrá já?
Discussion about this post