Wàhálà burúkú kan tún ti bẹ́ sílẹ̀ ní àgbègbè Ifọ́n-òròlú àti Ìlobùú níbi tí káńsẹ́lọ̀ kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fara pa yánnayànna. Ọ̀rọ̀ ààlà ilẹ̀ ló fa yánpọnyánrin láàrin àwọn ìlú mejeeji náà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun. Àwọn ìlú méjèèjì yìí sì mú ilé ti ara wọn ni láti ọjọ́ tó tí pẹ́.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé àti dúkìá àwọn ènìyàn ló ti ṣòfò dànù ní àkókò gbódó-n-róṣọ yìí. Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ademola Adélékè ti pàṣẹ fáwọn agbèfọ́ba báyìí láti pèsè ààbò tó nípọn lágbègbè náà lẹ́yẹ-kò-sọkà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn aráàlú. Wọ́n sì ti pàṣẹ kónílé-gbélé láti aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ di aago mẹ́fà ìdájí ọjọ́ kejì báyìí.
Káńsẹ́lọ̀ kan tẹ́lẹ̀rí láti Ifọ́n-òròlú tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Azeez ni a gbọ́ pé ó ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn báyìí. Ní báyìí, bí olóògbé yìí ṣe rìn pàdé ikú òjìji yìí kò tí ì di mímọ̀, àmọ́ olùgbé kan ní Ifọ́n-òròlú, tó ní ká forúkọ bo òun lásìírí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Azeez ti gbẹ́mìí mì ní ilé ìwòsàn ìjọba ní ìlú Òṣogbo ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹta, ọdún 2025.
Olóyè Ọ̀tún Jagun ti Ìlobùú, Olóyè Adégoke Ogunṣolá sọ pé àwọn ará Ifọ́n-òròlú ló kọ́kọ́ dojú ìjà kọ àwọn ará Ìlobùú. Ó ní àwọn sì ti fi tó àwọn Ọlọ́pàá létí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ó ní láàrin ọjọ́ kẹtàlá sí ogúnjọ́ oṣù kẹta ọdún yìí 2025, àwọn ti kọ ìwé ẹ̀sùn sí gómìnà àti àwọn aláàbò ìlú. Ó ní lójijì, lọ́gànjọ́ òru àná, ọjọ́ Àlàmísí, ogúnjọ́ oṣù yìí, ní deede aago mọ́kànlá alẹ́ ni àwọn ń gbúròó ìbọn tó ń dún lákọlákọ; tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó ilé, tí wọ́n ń sùn dúkìá.
Olóyè ṣàlàyé síwájú sí I pé àwọn àdúgbò bíi Akinponroro, Odò-òjé àti àwọn ààlà to wà lágbègbè ni ọwọ́ ìjà náà ti dunlẹ̀, tí wọ́n sì ti sọ di eérú ; kódà wọ́n jó ilé-iṣẹ́ ètò ìlera alábọ́dé tó jẹ́ ti ìjọba tó wà lágbègbè náà pẹ̀lú. Gómìnà Adélékè ti pàrọwà báyìí pé kí wọ́n jẹ́ kí àlàáfíà padà jọba, lẹ́yìn tó ti gbé ìgbésẹ̀ ààbò àti dúkìá ẹ̀mí àwọn ará ìlú.
Nígbà tí ogun ti fẹ́rẹ̀ kó Ilobu àti Ifon lọ tán lápá kan, lápá kejì ni a ti rí ìròyìn tó sọ nípa Ebube tí wọ́n lù pa ní ìpínlẹ̀ Ebonyi.
Ó kà báyìí pé ‘Aṣọ́gbà ni Ebube Igboke ní ilé ìwé gíga ìpínlẹ̀ Ebonyi. Ọmọ ìlú Ezamma ní ìjọba ìbílẹ̀ Gúsù Ezza ni Ebube ṣe.
Ẹnu ìṣẹ́ rẹ̀ ló wà gẹ́gẹ́ bí aṣọ́gbà ilé ìwé gíga Ebonyi nígbà tí àwọn kan kó ìbóm̀bó tìí lóru tí wọ́n sì lù ú pa.
Alukoro fún ile iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi; Joshua Ukandu ṣe àlàyé pé àwon ti mú àwọn afurasí mẹ́ta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àlàyé tí àwọn afurasí náà ṣe ni pé àwọn rí Ebube níbi tó ti ń jí àwọn ẹrù kan ni àwọn ṣe lù ú kí àwọn tó gbé e lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá wọ́n sì ní kí àwọn ó gbé e lọ sílé ìwòsàn. Kété tí wọ́n dé ilé ìwòsan ni Ebube gbé ẹ̀mí mì.
Àwọn ẹbí Ebube ti kọ̀wé ìfisùn ṣọwọ́ sí kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi; Adaku Uche-Anya, wọ́n bèèrè fún ìdájọ òdodo.
Agbẹjọ́rò mọ̀lẹ́bí náà; D.I Njoku ló bu ọwọ́ lu ìwé ìfisùn náà.
Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìpàníyàn kejì nínú ọ̀sẹ̀ yìí nìkan, ṣé ẹ rántí ìròyìn tí a mú wá fún yín lánàá nípa ìpínlẹ̀ Ebonyi yìí kan náà? A kọ ọ́ pé ‘Ìjà ilẹ̀ àtọdún márùn-ún tún gbérí ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ní èyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti bọ́ lórí rẹ̀. Ìròyìn tí ọwọ́ wa tẹ̀ náà ni pé àwọn ará abúlé Umuobor-Akaeze àti àwọn ará Ishiagu tún ti bá ara wọn wọ̀yá ìjà, ìjọba ìbílẹ̀ Ivo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ni àwọn abúlé méjì yìí wà.
Ilẹ̀ Elueke tó pa àwọn abúlé méjéèjì yìí pọ̀ ni wọ́n ń jà sí. Ó ti lé ní ọdún márùn-ún tí wọ́n ti wà lẹ́nu rẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti sùn lórí ìjà ilẹ̀ yìí.
Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí ni ó tún burẹ́kẹ nígbà tí wọ́n dá ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n ń lọ lórí ilẹ̀ yìí dúró tí wọ́n sì pa wọ́n, èyí ló tún mú kí àwọn ará kejì dìde ogun tí ọpọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àti dúkíà sì ti ṣòfò lórí rẹ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi; Francis Nwifuru ti kéde ilẹ̀ náà ní àìwọ̀ fún àwọn ará abúlé méjéèjì báyìí ó sì tún gbé ikọ̀ dìde láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Joshua Ukandu pé àwọn kò gba ìfisùn ìpànìyàn Kankan láti ọ̀dọ ẹnikẹ́ni.
Kí la máa rí tí a kò ní fi tó o yín létí? Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa ìkọlù tó wàyé ní ìpínlẹ̀ Plateau? Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé àwọn àgbẹ̀ abúlé Shimankar ní ìjọba ìbílẹ̀ Shendam, ìpínlẹ̀ Plateau ké tantan lórí bí àwọn Fulani ṣe run oko wọn pátápátá.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ẹ̀ya Fulani tako orò tí àwọn onílùú ṣe, èyí ló bí wọn nínú tí wọ́n fi ya wọ oko wọn, wọ́n gé ọdẹ inú oko náà lọ́wọ́ féú wọ́n sì ti iná bọ gbogbo oko náà. Wọ́n lọ káàkiri àwọn ilẹ̀ oko lọ ṣe ọṣẹ́ yìí tó fi já sí pé kò sí àgbẹ̀ kan tó rí nǹkan kan mú lóko rẹ̀.
Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe èyí tán ni wọ́n tún lọ ká àwọn ará abúlé náà mọ́lé, wọn kò pa ẹnikẹ́ni àmọ́ wọ́n sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara.
Tobias; ọ̀kan lára àwọn àgbẹ̀ abúlé Shimankar bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé gbogbo oko elégédé òun ló jóná gúrúgúrú, àti oko rẹ̀ àti ti àwọn ẹbí rẹ̀ méjì mìíràn ló jóná kanlẹ̀.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau; Emmanuel Olugbemiga Adesina fi ọ̀rọ̀ ìdákànró ránṣẹ́ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà pé òun ti ṣètò gbogbo alàkalẹ̀ láti mú kí àlàáfià ó padà sí ìlú. Ó rọ àwọn èèyàn náà láti gba àlàáfíà láàyè.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau náà fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn ará abúlé náà.
Ogun lọ́tùn-ún ìjà ilẹ̀ lósì, àwọn agbésùnmọ̀mí náà ń ṣọṣẹ́ tiwọn lọ ní pẹrẹu, àfi kí Elédùmarè ó bá wa dáwọ́ ìtẹ̀jẹ̀ẹ́lẹ̀ dúró, amin’
Discussion about this post