Ọ̀kan nínú àwọn Ògúná gbòǹgbò tíí dátọ́ lẹ́nu ìgbín inú ẹgbẹ́ PDP; Olóyè Bọ̀dé George ti gbéná wo ojú Jandor tí í ṣe ẹni tí ó díje dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ áṣíà egbẹ́ òṣèlú PDP ní àkókò ètò ìdìbò tó kọjá. Bọ̀dé ní àbùkù ńlá ni fún òun pé irú Adeniran Ọlajide tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Jandor lè máa fi ẹ̀sùn kan òun lórí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ PDP ní Ìpínlẹ̀ Èkó.
A hú u gbọ́ pé Jandor tó kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP ní àìpẹ́ yìí fẹ́sùn àgàbàgebè Kan Olóyè Bọ̀dé George pé ó ń ṣe lòdì sí ọmọ oyè PDP. Ó ní Bọ̀dé George ń fi àtìlẹ́yìn rẹ̀ hàn fún ọmọ oyè sí ipò gómìnà nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn, ó sì ń yí àwọn ọmẹẹgbẹ́ lọ́kàn padà pé kí wọ́n má dìbò fún PDP.
Nígbà tí olóyè Bọ̀dé George ń fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn, tóun bá rí ti Jandor gbọ́, yóò mú kí òkìkí tí Jandor rò pé òún ni di yẹpẹrẹ lásán ni nílùú Èkó. Ó sọ eléyìí lánàá nígbà tó ń kópa nínú ètò kan lórí ẹ̀rọ rẹdiò 102.5 Fm ” Ọ̀rọ̀ tó ń lọ” lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bọ̀dé pe Jandor ní ọ̀lẹ olóṣèlú, tí kò fi tọkàn-tara ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ ẹgbẹ́ kankan rí.
Bọ̀dé sọ ọ́ débi pé :
‘ Mo ti pé ọmọ ọgọ́rin ọdún, ọmọ ọwọ́ sì ni Jandor tí kò tí ì kọjá àgbékọ́rùn roko. Ọjọ́ la bí àkàrà rẹ̀ tó fẹ́ máa bímọ ẹnu? Kí ló mọ̀ nípa ẹgbẹ́ yìí ( PDP!)? Ọmọ ọwọ́ tí kò tíì já lẹ́nu ọmú ni Jandor tó bá kan ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Kí n sọ ọ́ ní pàtó, mo kà á sí àrífín àti àfojúdi gbáà! Ọmọ tí mo bí kì í ṣe ẹgbẹ́ rẹ̀ dànù dànù. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ìpèdè Látìn kan tí a mọ̀ sí *Infradig * nígbà tí a wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama, ” Èyí tí a lè túmọ̀ sí èkúté ilé tó fi àkọ̀ sílẹ̀, tó ń jẹ ọ̀bẹ tẹnu ẹni ló fẹ́ẹ́ gbọ́” – ( èrò tiwa)
Nínú àlàyé Olóyè George, ó ní Jandor kò ní òye nípa bí ẹgbẹ́ ṣe rí, síbẹ̀ wọ́n gbà á láàyè láti jẹ́ ọmọ oyè fún ipò gómìnà, èyí tó mú kí ojúgbà rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ LP, ìyẹn Gbádébọ̀ Vivour-Rhode gbà láti yẹ̀bá, tó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ alátakò – PDP rẹ̀.
Olòyè ní onítìjú òun tóun ò leè kọ ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu ló mú Jandor wá, tó sì díje pẹ̀lú ẹnìkan tó gbọ́n, tó kàwé, tó sì ti Ìwọ̀ oòrùn Èkó tó ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá wá. Ó ní ẹni náà fíírì Jandor bí ìgbà tí ẹgbàá fíírì oókan.
Ègbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí a ti ń pàkan ni ọ̀kan ń rú. A kò tíì fi orí ìṣẹ̀lẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tì síbi kan, ọ̀rọ ti Mudashiru Obasa ṣì wà nílé ẹjọ́, ṣé ẹ ò gbàgbé pé El-Rufai náà ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC? A mú ìròyìn náà fún yín pé ‘Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti sọ̀rọ̀ lórí yíyapa tí El-Rufai yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP. Wọ́n wí pé kò tu irun kan lára wọn, wọ́n láwọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé ó kúrò rárá.
Wọ́n wí pé kò sọ́rọ̀ nínú ohun tó sọ pé òun yóò kó àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú jọ láti dìbò tako ìyànsípò Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027, wọ́n lọ́rọ̀ rírùn ni.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé kò sí àwọn èèyàn tí El-Rufai le kó jọ tó le pa ìdìbò ọdún 2027 lára nítorí pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu náà ni yóò wọlé.
Wọn kò ṣàì má mẹ́nuba pé àmọ́ lọ̀rò El-Rufai kò mọ́ ara ẹran àti pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ rẹ̀, kò tó ohun tí àwọn ó máa wá yọ àdá sí.
Ọ̀rọ̀ yìí wá dà bí orin tí wọ́n máa ń kọ pé bí yó lọ kó lọ, ìgbà tí ò lọ kí ló ṣe? —-
Ọ̀sẹ̀ yìí ni El-Rufai, ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tó sì tún jẹ́ èèkan nínú ẹgbẹ́ náà kọ̀wé ìyapa ṣọwọ́ sí ẹgbẹ́ náà pé òun kò bá wọn ṣe mọ́, ó tó gé, àlubàtá kò tún gbọdọ̀ máa dárin. El-Rufai wí pé òun ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP níbi tí òun yóò ti ní àǹfààní àti gòkè àgbà.
Ẹ̀sùn tó fi kan ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni pé wọn kọ iyán òun kéré, wọn ò tún fewé bò ó, ó wí pé òun wà lára àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun dalẹ́ láì mọ̀ pé ṣe ni wọn yóò já òun kulẹ̀. Ó ní àwọn adarí ẹgbẹ́ náà kò ka àmọ̀ràn òun kún rárá, gbogbo ọ̀rọ̀ òun kò tà létí wọn, ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé ìlú tí wọn kò bá ti fẹ́ni, a kìí dárin níbẹ̀. Ìdí rèé tí ó fi yapa lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun.
El-Rufai ṣe ìlérí pé òun yóò kó àwọn èèyàn jọ láti dìbò tako ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti wá fèsì báyìí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò le mu àwọn lómi nítorí pé balùwẹ̀ rẹ̀ tó fẹ́ kún ju odò lọ, irọ́ lásán ni’
A ń pe ọ̀rọ̀ yìí lọ́wẹ̀, ó ti ń lọ́wọ́ kan àáró nínú. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, inú ẹlẹ́dẹ̀ ti ń wọgbà, àwọn ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC sì ń yo.̀ wẹ́n pé kí wọ́n wá kọ́ ìṣelú lọ́dọ̀ àwọn.
Arítẹnimọ̀-ọ́n-wí, tiwọn náà ti bẹ́ sílẹ̀ báyìí ó sì fẹ́rẹ̀ burú ju ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ, ojúmọ́ kan, wàhálà kan ni.
Ó ṣe pàtàkì láti mẹ́nuba pé Obasa, Meranda àti àwọn ẹmẹ̀wàá wọn tọ́rọ̀ kàn ti wà lọ ṣe ìpàdé ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú Tinubu ní Abuja lórí ohun tó ń rùn nílẹ̀ yìí náà ni.