ỌKÙNRIN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN LÓ BÁ ÌYÀWÓ MI LÒ PỌ̀- ÌJỌBA LANDE
Ganiyu Morufu, adẹ́rìn-ínpòṣónú nnì ti ju bọ́ḿbù titun sílẹ̀ nípa ìyàwó rẹ̀; Dara.
Lande gẹ́gẹ́ bíi orúkọ ìtàgé rẹ̀ wí pé oníkànǹga àjípọn nìyàwó òun. Ó wí pé gbogbo àwọn ọkùnrin òṣèré tíátà ni wọ́n ń mú un balẹ̀, bí o bá kàá léní, èjì, ẹ̀ta, ó ti lé ní ọkùnrin mọ́kànlélógún tó ti pọnmi lódò ìyàwó òun.
Yàtọ̀ sí Baba Tee tí Lande ti dárúkọ tẹ́lẹ̀, ó wí pé àwọn gbajúgbajà òṣèrékùnrin ni wọ́n ti jẹ ìyàwó òun bíi iṣu.
Baba Tee kọ́kọ́ jiyàn pé òun kò bá ìyàwó rẹ̀ sùn pé tó bá dáa lójú kó mú ẹ̀rí jáde tàbí kó fojú ba ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́. Nígbà tó ríi pé ẹ̀rí wà ló yíhùn padà pé òun bá obìnrin náà lò pọ̀ lóòótọ́ àmọ́ òun kò mọ̀ pé ìyàwó rẹ̀ ni, ó ní kí Lande ó má bínú.
Baba Tee kò ṣàì má ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́, ó wí pé lọ́jọ́ náà, MaryGold; ọ̀rẹ́ Dara tó sì tún jẹ́ máníjà Lande ló mú Dara wá sílé òun, wọ́n bèèrè fún ọtí, lẹ́yìn náà ni àwọn ṣe eré mo tó bẹ́ẹ̀ – mi ò tó bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọtí àmupara. Nínú eré náà ni MaryGold ti fún òun ní ìbálòpọ̀ ẹnu tó sì wí pé kí òun ó bá Dara lò látẹ̀yìn, ó ní òun mú ọ̀rá ìdáàbò-bò òun sì ṣe é ní fẹ́rẹ́jógí. Baba Tee wí pé òun kò tẹ àtèkanlẹ̀ rárá kódà òun kò damira. Ó wí pé òun kò mọ bí Lande ṣe ní fọ́nrán náà nítorí kò sí ẹlòmíràn níbẹ̀.
Dara tí a fẹ̀sùn kàn náà fèsì o, ó kọ́kọ́ wí pé irọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà pé òun kàn jókòó lé Baba Tee lẹ́sẹ̀ lásán ni òun kò bá a ṣe nǹkan kan. Àmọ́ o, nígbà tí ẹ̀rí jáde pẹ̀lú ẹsẹ̀ méjì digbí nílẹ̀, ó wí pé ó ṣeé ṣe kí Baba Tee ó bá òun sùn kí òun ó má mọ̀.
Ijoba Lande kò gba àlàyé tí Baba Tee ṣe yìí wọlé o, ó wí pé lẹ́yìn tó fún ní fẹ́rẹ́jógí pé ó padà mú un lọ sí ìyẹ̀wù rẹ̀ níbi tó ti tẹ àtèkanlẹ̀. Ó ní ó fara balẹ̀ ki Dara bíi ìbọn ni pé kò kánjú ṣe é rárá.
Lande kò dúró níbẹ̀ o, ó wí pé kìí ṣe Marygold ló ń gbé ìyàwó òun fún ọkùnrin nítorí pé àwọn fọ́nrán mìíràn tí òun ní lọ́wọ́, kò sí Marygold níbẹ̀ fúnra ìyàwó òun ló ń gbé oúnjẹ alẹ́ òun fún olóńgbò jẹ.
Ó wí pé inú òun bàjẹ́ gidi nígbà tí òun wo àwọn fọ́nrán bí wọ́n ṣe ń ku ìyàwó òun bíi aṣọ òfì tí wọ́n ń lọ̀ ọ́ bí ata tí wọ́n ń gbo ó bíi aṣọ tí wọ́n tún ń gún bí iyán. Lande tẹ̀síwájú pé àwọn bọ́tìnì tí òun ò tẹ̀ rí lára ìyàwó òun ni wọ́n tit ẹ̀ bàjẹ́ lára rẹ̀. Inú ìbànújẹ́ yìí lòun wà láti bíi oṣù mẹ́rin tí ìyàwó òun ti lọ.
Marygold náà ganu sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí, ó wí pé òun kò fẹ́ tú àṣírí Dara ni pé onínàbì gidi tààrà níí ṣe. Marygold wí pé ìwà nàbì yìí náà ló mú kí ọkọ àárọ̀ rẹ̀ ó kọ̀ọ́ sílẹ̀.
Ó gbìyànjú àtifọ ara rẹ̀ mọ́ pé òun kọ́ ló ń mú Dara lọ pàdé àwọn ọkùnrin nílé ìtúra káàkiri.
Dara náà fèsì o, ó wí pé òun kìí ṣe onínàbí pé ìjókòó lásán lòun jókòó lé Baba Tee lẹ́sẹ̀, bóyá ó wá bá òun sùn, òun kò mọ̀. Dara wí pé Marygold ló mú òun mọ Baba Tee nínú oṣù Agẹmọ ọdún tó kọjá, ó mú òun lọ sí ilé Baba Tee lọ́jọ́ náà nítorí fíìmù rẹ̀ tó fẹ́ gbé jáde. Baba Tee kò ní ọtí nílé, Marygold àti dereba Baba Tee jọ lọ ra ọtí wá
Dara wí pé ibi tí òun jókòó sí tó fi lọ náà ló dé bá òun pé òun àti Baba Tee kò tahun síra.
Ní báyìí, Lande wí pé fọ́nrán bíi mẹ́jọ ló wà lọ́wọ́ òun níbi tí wọ́n ti fi okó dábírà fú Dara ìyàwó òun tí òun náà sì ń gbádùn rẹ̀, o ní òun yóò fi fọ́nrán yìí léde.
Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ìkànnì ayélujára pàápàá Tiktok ti sọ ọ̀rọ̀ yìí di báàmíì, àwọn abọ́lọ́rọ̀ yanjú-ẹ̀ gbogbo, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń pé jọ ganu sí ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí àwọn kan dá Margold lẹ́bi pé òun ló ń ti Dara, àwọn kan wí pé Dara kìí ṣe ọmọdé pé ó ti tójú bọ́. Wọ́n bá ijoba Lande kẹ́dùn òfò owó àti ìfẹ́ tó ṣe nítorí àwọn ọmọ tí Dara ti bí tẹ́lẹ̀ tó ń tọ́jú, wọ́n yìn ín fún ipa rẹ̀ lórí àwọn ọmọ tí kìí ṣe tirẹ̀ tó ń tọ́jú.
Ọ̀rọ̀ yìí ti dá awuyewuye sílẹ̀ lórí ìtàkùn gbogbo, àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn obìnrin adọ́mọtọ́ àti àwọn òṣèrébìnrin pé kò sí ìyàtọ̀ láàárin ọmọ ọwọ̀ pé irú kan náà ni gbogbo wọn. Èyí bọ́ sí àpò ìbínú àwọn kan pé kìí ṣe gbogbo obìnrin adọ́mọtọ́ ni ó ń ṣe nàbì, wọ́n ní amúnibuni lásán ni Dara tó kó irú ẹrẹ̀ báyìì yí àwọn lára.
Ọ̀rọ̀ rèé o ẹ̀yin ará, ta ló jẹ̀bi ta ló jàre? Ṣé Lande tó fẹ́ obìnin adọ́mọtọ́ ni àbí Marygold tó pilẹ̀ erépá? Àbí Dara tí kò mọ ìgbà tí wọ́n bá a sùn? Bó sì ṣe olókó kòmọ̀-ọ́n-kọ̀ tíí jẹ́ Baba Tee ni ká dá lẹ́bi, ẹ jẹ́ ká mọ èrò yín nínú àríwísí?