Èmi ò- jù- ọ́, ìwọ ò- jù- mí , ibí ni mo fẹ́ jókòó, èmi ò fẹ́ ibí, jókòó síbẹ̀, mi ò jókòó ló dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ wa láàrín Olórí kẹta ilẹ̀ Nàìjíríà , Sẹnẹtọ GOODSWILL AKPABIO àti Sẹnẹtọ tó n ṣojú ìpínlẹ̀ Kogí, Arábìnrin NATASHIA AKPOTI-UDUAGHAN láìpẹ́ yìí títí tí awuyewuye pé ṣé GOODSWILL AKPABIO wá kéré nínú ayé ni, ìkọlù-kọgbà ni òkò ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ sí NATASHIA AKPOTI ni òun náà bá bọ́ ohùn pé níṣe ni GOODWILL AKPABIO n fi òwò nàbì lọ òun ìdí nìyí tí kò fi jẹ́ kí òun mí nílé ìgbìmọ̀ àṣofìn àgbà ilẹ̀ wa. Ìyàwó Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO bá gbé NATASHIA lọ sí ilé ẹjọ́ fún ìkà àbùkù tó nà sí ọkọ rẹ̀, ó ní ọkọ òun kìí ṣe onírìnkurìn kìí ṣe oníṣekúṣe ọkùnrin rárá, owó ìtanràn bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógójì ló ní kí NATASHIA san fún ìbanilórúkọ jẹ́. Lọ́jọ́ kẹfà oṣù yìí ni gbogbo ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà bá ní kí Sẹnetọ NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN lọ rọ ọ́ kún sílé fún oṣù mẹ́fà gbáko látàrí fí fẹ ìdí ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofìn síta èyí tó lòdì sí òfin ọdún 2023. Sẹnetọ NATASHIA AKPOTI gbé ẹrù rẹ̀, ó jáde kúrò nílé ìgbìmọ̀ àṣofìn lẹ́yìn tí Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO ti dá a lọ́wọ́ kọ́. Ìpèdè tí NATASHIA AKPOTI-UDUAGHAN sọ gbẹ̀yìn ní pé ‘Èké kò lérè, Òtítọ́ ni yóò lékè’.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ nígbà kan rí nílẹ̀ Nàìjíríà, ọ̀mọ̀wé OBY EZEKWESILI ti sọ̀rọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí Sẹnetọ NATASHIA AKPOTI sọ kí ó tó le è fi ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sílẹ̀ lẹ́yìn tí Sẹnetọ̀ GOODSWILL AKPABIO ti sọ pé kó lọ́ọ rọọ́kúnlé, OBY ni lóòtọ́ èké ò lérè, òtítọ́ sì ni yóò borí, àwọn tí adé ìwà láabi náà bá ṣí mọ́ lórí nínú àwọn àṣofin , ẹ̀rí ọkàn yóò máa jẹ́ wọn títí tí òtítọ́ yóò fi ojú hàn. OBYEZEKWESILI ni ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ní Sẹnẹtọ NATASHIA sọ, àwọn ọlọ́gbọ́n ló sì yé, àwọn ọ̀mọ̀ràn ni yóò mọ̀ ọ́n, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì le è yé àwọn aláìmọ̀kàn-mọkàn ẹ̀dá tó wà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin títí di ìgbà tí òtìtọ́ yóò fojú hàn.
Aya Ààrẹ, obìnrin àkọ́kọ́ nílẹ̀ Nàìjíríà Sẹnetọ OLÚRẸ̀MI TINUBU ti dá sí yánpọnyánrin tó n jà ranyinrayin nílé aṣòfin ilẹ̀ wa nípa Sẹnetọ NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN tó n ṣojú fún ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi bí gbogbo ilé ti ni kó lọ rọọ́kún fún oṣù mẹ́fà gbáko tí ẹ̀tọ́, àjẹmọ́nú àti owó ọ̀yà òun àti àwọn ẹmẹ̀ẹ̀wá rẹ̀ kò ní jẹ́ sísan fún gbogbo àkókò yìí. Òfin tún de NATASHIA AKPOTI láti dásẹ̀ wọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin títí di ìgbà tí oṣù mẹ́fà rẹ̀ yóò fi pé gbáko, wọn ò gbọdọ̀ rí éégún rẹ̀ tó n jẹ́ Àjíkẹ́ fún oṣù mẹ́fà náà. Aya Ààrẹ REMI TINUBU wí pé ‘ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kò kéré rárà, kìí ṣe ibi tí ẹnìkan le è tàbùkù kàn tàbí yí mọ́ ẹrẹ̀, àṣẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gbọ́dọ̀ múlẹ̀ dáradára. Sẹnetọ REMI TINUBU tún tẹ̀ síwájú pé ‘àwa obìnrin ni kí a jẹ́ àwòkọ́ṣe rere tó ṣe é fọkàn tán, ká a gbájúmọ́ ohun tá a bá n ṣe kódà bí wọ́n bá fẹ́ gbé e súnmọ́ wa, ẹ̀tọ́ wa ni kí a dáwọn lẹ́kun, kí àwa obìnrin yé é ta ara wa lọ́pọ̀’.
Igbákejì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà nígbà kan rí tó tún figa-gbága níbi ètò ìdìbò ọdún 2023 kó tó di pé Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU, ALHAJI ATIKU ABUBAKAR náà dásí yánpọnyánrin tó n lọ lọ́wọ́ nílé ìgbìmọ̀ àṣofìn, ó bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe ní kí NATASHIA lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà gbáko. Nínú àtẹ̀jáde ọjọ́ keje oṣù yìí ni ALHAJI ATIKU ABUBAKAR ti sọ pé èyí kù díẹ̀-kààtó, kò tọ̀nà rárá àti pé ó tàbùkù sí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà. ALHAJI ATIKU ABUBAKAR ní ìgbésẹ̀ yìí n dá àwọn obìnrin ní ó tóó, ó pawọ́n lẹ́nu mọ́, kò le è jẹ́ kí wọ́n fohùn síta àgàgà bí ó bá jẹmọ́ ìfipábánilòpọ̀, èyí yóò tún dènà àwọn obìnrin níbi fífọhùn síta, ìgbésẹ̀ náà kò ní jẹ́ kí a máa gbọ́ wọn níbi ìdarí ètò ìjọba, èyí yóò túbọ̀ tẹ ẹ̀tọ́ obìnrin mọ́lẹ̀, ó ba ni lójú jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ àgàgà lásìkò tí ayẹyẹ àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé tọdún yìí tí n kan ilẹ̀kùn gbọ̀ngbọ̀n.
ALHAJI ATIKU ABUBAKAR fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn sí gbogbo Akínkanjú obìnrin, àwọn abo-bí-akọnibìnrin tí kò sú tí kò sì káàrẹ̀ nígbà gbogbo. ALHAJI ATIKU ABUBAKAR gbé òṣùbà káre láí fún àwọn obìnrin, ó ní àwọn gan an ni iyọ̀ ayé, láìsí obìnrin rere, kò sí àwùjọ. ALHAJI ATIKU ni gbòngbò àwùjọ tí kìí kọ́ni lẹ́sẹ̀ láwùjọ ni àwọn obìnrin. Ipa pàtàkì ni àwọn obìnrin n kó nínú ilé, níbi iṣẹ́ àti ìṣètòjọba. ATIKU ní kí gbogbo obìnrin pátápátá fún ìdàgbàsókè àwùjọ nítorí kí àwùjọ le è dùn ún gbé. ALH. ATIKU ní ìtàbùkù gbá à ni òfin gbọmọgbọmọ tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin aláwọ̀ pupa gbé lórí ọ̀rọ̀ Senetọ NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN, ìyànnijẹ gbáà ni kò papọ̀ mọ́ ètò takọ-tabo rárá. ATIKU ní kí a kún àwọn obìnrin lọ́wọ́ lásìkò tí wọ́n bá n ṣe ìṣejọba, kí a má ṣe fún pinpin mọ́ wọ́n lásìkò tí wọ́n bà wà ní ipò adarí. Ní àyájọ́ abo tọdún yìí lágbàáyé ni ALHAJI ATIKU ní kí a dáàbò bo ètò àbò láwùjọ wa nílẹ̀ Nàìjíríà nítorí àwùjọ á ní ìlọsíwájú, àwùjọ á dùn ún gbé bí a bá gba àwọn obìnrin láàyè láti le è kó ipa tó lààmì-laka.,Ẹ kú ayẹyẹ ọdún yìí, ojú a rá a rọ́dún’.