Austin; ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó jẹ́ onígbàjámọ̀ tó sì tún máa ń ṣe fọ́nrán àwàdà ni àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ kó ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣá ládàá pa báyìí.
Ní òwúrọ̀ àná ni wọ́n lọ ká a mọ́ ilé rẹ̀ tó wà ní Lakowe, Ibeju-lekki ní ìpínlẹ̀ Èkó, wọ́n wọ́ ọ jáde wọ́n sì ṣá a láṣàápa.
Àwọn ará àdúgbò wí pé àwọn rí àwọn géńdé ọkùnrin ní òwúrọ̀ àná tí wọ́n ń wá èèyàn kan láti ojúlé sí ojúlé, nígbà tí wọ́n lọ tán ni ìròyìn kàn pé wọ́n ti ṣá Austin pa tí wọ́n sì tún gé ọwọ́ rẹ̀ lọ.
Àwọn ọ̀rẹ́ Austin náà ṣe àlàyé pé Austin ti fura pé wọn yóò pa òun nítorí pé ó kọ ọ̀rọ̀ ìdágbére sí ojú òpó rẹ̀ ní ìjẹta.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWỌN ÀGÙNBÁNIRỌ̀ NÍṢEKÚṢE.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ Agunechemba ya wọ ilé ìgbé àwọn àgùnbánirọ̀ obìnrin ní ìpínlẹ̀ Anambra, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára tí a mọ̀ sí yàhú ni wọ́n ń ṣe.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí na àwọn àgùnbánirọ̀ náà wọ́n tún já ọ̀kan sí ìhòhò.
Àwọn àgùnbánirọ̀ yìí fi káàdì ìdámọ̀ wọn han àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí àmọ́ wọn kò bìkítà, wọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú.
Orúkọ àgùnbánirọ̀ tí wọ́n fìyà jẹ jù tí wọ́n tún já sí ìhòhò ni Jennifer Elobor.
Àná ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, fọ́nrán náà gbòde kan ní kíákíá.
Nínú fọ́nrán yìí ni a ti rí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tí wọ́n jẹ́ mẹ́jọ níye, wọ́n lu àwọn àgùnbánirọ̀ obìnrin yìí lálùbami àmọ́ Jennifer ni wọ́n lù jù.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwuma Soludo ti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó pàṣẹ kí wọn ó gba aṣọ lọ́rùn àwọn mẹ́jọ náà kí wọn ó sì fà wọ́n lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
ATẸ́GÙN ÒJÒ DA Ọ̀PỌ̀ ILÉ WÓ NÍ ÌPÍNLẸ̀ PLATEAU.
Òjò tó rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Plateau fẹ́ atẹ́gùn tó le débi pé ó da ọ̀pọ̀ ilé wó ó sì tún fa géètì ilé ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Jos ya.
Agbègbè Bukuru ni èyí ti ṣẹ̀ lónìí, ọ̀pọ̀ ilé ni atẹ́gùn náà fa òrùlé rẹ̀ yọ tó sì tún dà wó.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Jos, Silas Dung wí pé atẹ́gùn náà le gidi gan-an tó fi yọ igun géètì ilé ìjọba ìbílẹ̀ náà mẹ́rẹ́ẹ̀rin, ó da géètì náà wó lulẹ̀, àwọn òpó tó gbé e ró náà ṣẹ́ lórí òró.
Dung ṣe àbẹ̀wò sí agbègbè náà, ilé mẹ́fà ló wó lulẹ̀ nígbà tí ó yọ òrùlé àwọn yòókù.
AWAKỌ̀ ỌKỌ̀ ÀDÁNI KAN PÀDÉ IKÚ ÒJIJÌ LÁÀÁRỌ̀ ỌJỌ́ AJÉ.
Awakọ̀ ọkọ̀ àdáni kan ló ṣe àgbákò ikú láàárọ̀ kùtù nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ kọlu ọkọ̀ korope kan tó ń kó èrò lọ́wọ́.
Agbègbè Mile 2 lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Badagry ni ìjàmbá náà ti wáyé lówǔrọ̀ kùtù, ọjọ́ Ajé.
Àwọn tí ìjàmbá náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé ọkọ̀ àdáni náà ń sáré àsápajúdé ló fi pàdánù ìjánu rẹ̀, ó kọlu ọkọ̀ korope kan tó ń kó èrò lọ́wọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, ìjàmbá yìí ló ṣokùnfà ikú awakọ̀ ọkọ̀ àdáni yìí lójú ẹsẹ̀.
Olalekan Bakare-Oki; ẹni tó jẹ́ adarí àjọ LASTMA bu ẹnu àtẹ́ lu ìjàmbá náà, ó bá àwọn ẹbí awakọ̀ náà kẹ́dùn ó sì rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé.
ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ GBA ỌMỌ ỌDÚN MẸ́FÀ KALẸ̀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN AJÍNIGBÉ.
Àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti gba ọmọ ọdún mẹ́fà kan kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó jíi gbé.
Ìpínlẹ̀ Anambra ni wọ́n ti jí ọmọ náà gbé wá sí ìpínlẹ̀ Ondo, ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi tọpasẹ̀ àwọn ajínigbé méjì náà wá sí Ondo tí wọ́n sì mú wọn.
Ọmọ náà ti padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ báyìí nígbà tí àwọn ajínigbé náà yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
ỌKÙNRIN KAN GÚN OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ LỌ́BẸ PA NÍTORÍ Ó FURA PÉ Ó NÍ OLÓLÙFẸ́ MÌÍRÀN.
Ọkùnrin kan tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Doctor ni ó ti fi ọ̀bẹ gún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa nítorí pé ó fura pé ó ní ọ̀rẹ́kùnrin mìíràn.
Ima ni orúkọ ọ̀rẹ́bìnrin Doctor, ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ bíi ìjà nígbà tí Doctor kojú Ima pé ó ní ọ̀rẹ́kùnrin mìíràn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà le tó fi di pé Doctor yọ ọ̀bẹ tó sì kì í bọ Ima níkùn.
Àwọn ará ilé wọn péjọ láti wo ìran ni kò sí ẹni tó gbìyànjú àti gbé Ima lọ sí ilé ìwòsàn títí tó fi da gbogbo ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ tán.
Alámòójútó ilé náà ló lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá létí tí wọ́n sì wá mú afurasí ọ̀daràn náà.
ỌKỌ̀ AKÉRÒ KAN JÁBỌ́ SÍNÚ ODÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ TARABA.
Ọkọ̀ akérò kan tí ó kó èrò kún bámú ti jábọ́ lórí afárá sínú odò Namnai ní ìpínlẹ̀ Taraba.
A gbọ́ pé afárá náà kò dúró ṣinṣin tẹ́lẹ̀, ó ti dẹnu kolẹ̀ àmọ́ ìjọba kò tíì tún un ṣe, nígbà tí ọkọ̀ yìí gun orí afárá yìí ni ọwọ́ rẹ̀ yẹ̀ níbi tó ti ń pẹ́ afárá náà gùn tó sì jábọ́ sínú odò náà.
Gbogbo awọn èrò inú rẹ̀ àti awakọ̀ ló dágbére fáyé.
Àwọn ará àdúgbò náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, wọ́n ṣe àlàyé pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkọ̀ máa jábọ́ lórí afárá náà, wọ́n ní ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ni afárá náà ti gbà.
Wọ́n ní àwọn ti ké sí ìjọba àmọ́ wọn kò ṣe nǹkankan síi.
ONÍṢẸ́ INÁ KÚ IKÚ INÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.
Bàbá ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta kan ti gbẹ́mì mì lásìkò tí ó ń ṣe iṣẹ́ lori òpó iná kan ní agbègbè Shasha, ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé iná gbé bàbá yìí lásìkò tí ó ń so àwọn wáyà iná mọ́ orí òpó náà.
Wọ́n ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn àmọ́ àwọn dọ́kítà wí pé ó ti kú.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀,Ó wí pé àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú ọkùnrin náà.



