Àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti tako àwọn òfin àti agbára Máyẹ̀ bíi márùn-ún tí Trump fẹ́ lò nínú ìjọba rẹ̀. A ó rántí pé gbàrà tí Trump gba ìjọba ló ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tó kàmọ̀mọ̀. Ó sì ń lo agbára Ààrẹ Máyẹ̀ tí òfin fààyè gbà á.
Àmọ́ báyìí, àwọn adájọ́ ti tà kò ó pé kò leè máa lo irú òfin Máyẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ìlú kì í ṣe oko.
Ògbójú lọ́ọ́yà nnì, tó tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn-an ló pe àkíyèsí awon adájọ́ ilẹ̀ Naijiria sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ṣé wọ́n ní ohun tó bá jọ ohun là fi í wé ara wọn. Ó ní kò sí bí ìnàkí ti ṣe tí ọ̀bọ ò ṣe o. Alàgbà Fẹ́mi Fálànà ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó ń ìfọ̀rọ̀jẹ̀wọ̀ pẹ̀lú wọn ní ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán ti Channel lọ́jọ́ Ajé tó kọjá yìí.
Agbẹjọ́rò àgbà náà tọ́ka sí ohun tí àwọn adájọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe, tí ò wo ojú Wúsè, tí wọ́n sì lòdì sí àwọn òfin ìdágìrì tí Trump fọwọ́ sí láti fi ṣe ìjọba rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Fálànà sọ, márùn-ún nínú òfin Máyẹ̀ yìí ni àwọn adájọ́ ti fi ọwọ́ òsì taari dànù, nítorí pé àwọn adájọ́ gbójú agan sí i. Fálànà wá ń pàrọwà fáwọn adájọ́ ilẹ̀ yìí kí wọ́n wo àwòkọ́se adajo ilẹ̀ Amẹ́ríkà káwọn náà lè jẹ́ kó rọrùn fún mẹ̀kúnnù láti ṣe àmúlò ilé ẹjọ́ fún ìyànjú ìṣòro wọn; bí a bá sì rí èèyàn tàbí àjọ tó fẹ́ lòdì sí ètò ìjọba, kí wọn lè ṣẹ é láìbẹ̀rù.