Ilé ìwé gíga Unizik tó fìkàlẹ̀ sí Awka ní ìpínlẹ̀ Anambra ti jáwě fún Goddy-Mbakwe Chimamaka Precious lórí pé ó gbójú agan sí olùkọ́ ilé ìwé náà.
Àná ni wọ́n gbé ìwé gbélé ẹ náà jáde ní èyí tí agbaniwọlé ilé ìwé náà; ọ̀gbẹ́ni Victor Modebelu fi ọwọ́ sí.
Inú ìwé náà ni wọ́n kọ ọ́ sí pé Precious ti rú òfin ìwà ọmọlúàbí ilé ìwé náà nítorí náà, àwọn aláṣẹ ilé ìwé ti fi ẹnu kò lórí pé kó máa lọ ilé rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n pa á láṣẹ pé kí ó dá gbogbo nǹkan tó bá jẹ́ ti ilé ìwé ọwọ́ rẹ̀ padà.
Ohun tó fa èyí ni fọ́nrán kan tó lu síta, nínú fọ́nrán náà ni a ti rí Precious tó ń ká fọ́nrán ara rẹ̀, olùkọ́ yìí kọjá kò sì fẹ́ hàn nínú fọ́nrán náà, ó fi ọwọ́ tọ́ Precious pé kó yà lọ́nà àti pé kó pa ibi tí òun ti hàn nínú fọ́nrán náà rẹ́.
Ni Precious bá gbaná jẹ, ó tutọ́ sókè, ó sì fojú gbà á, ó ní olùkọ́ yìí fi ọwọ́ jẹ òun lára, ó sì fi tún gé e jẹ.
Gbogbo bí Precious ṣe ń ṣe yìí ni olùkọ́ yìí ń wò ó níran, àwọn èèyàn ká fọ́nrán náà wọ́n sì fi sí orí ìtàkùn ayélujára.
Ní báyìí, àwọn aláṣẹ ti fi orí okòó ṣọ̀ọ́dún, wọ́n ní kí Precious ó náà relé.
A ríi gbọ́ pé àgbà òṣìṣẹ́ ni ìyá àti bàbá Precious nílé ìwé náà, ṣé èyí kò ní pa isẹ́ wọn lára báyìí.