Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì ti ilé ìwé gíga Niger Delta tó wà ní Amassoma ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣá láṣàápa báyìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn méjì yìí wà ní Gbarantoru ní Yenogoa, ìpínlẹ̀ Bayelsa, ìwé ìpè sí àgùnbánirọ̀ ni wọ́n ń retí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tó ṣá wọn pa.
Orúkọ èkíní ń jẹ́ Ayaokpe Sinclair nígbà tí a kò tíì mọ orúkọ èkejì. Ìrọ̀lẹ́ àná; Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Èbìbí ni wọ́n ṣá wọn pa.
Aláṣẹ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Bayelsa; Tolummbofa Johnathan ṣe àlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì yìí ń rìn lọ ní òpópónà ni àwọn kan pariwo láti inú ọkọ̀ pé “àwọn nìyẹn” wọ́n bọ́ sílẹ̀ tì àwọn méjì náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo “Aye, Aye” kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn ládàá.
Ayaokpe kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ èkejì rẹ̀ gbìyànjú àti sálọ, awakọ̀ tó gbé wọn wá ríi pé àbúrò òun ni ó sì gbé e lọ sínú ọkọ̀ kó le gbé é sálọ àmọ́ wọ́n ká wọn mọ́ inú ọkọ̀ náà wọ́n sì ṣá a pa.
Johnathan wí pé àwọn rí awakọ̀ náà mú àwọn sì ti fàá lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣá olórí wọn láṣàápa ní ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ kà báyìí pé:
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Bobos ti ṣekú pa olórí wọn; Olotu Omubo nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ipò náà.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé àwọn ọmọlẹ́yìn Olotu Omubo náà ni wọ́n pa á nítorí pé wọ́n fẹ́ fi èèyàn tiwọn sí ipò náà ní ẹni tí wọ́n lérò pé àsìkò rẹ̀ yóò san àwọn.
Ìdílé Nembe ni Omubo ti jáde wá, òpópónà Goodnews ní Azikoro, Yenagoa ni wọ́n pa á sí lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ìṣọ́wọ́paá nípakúpa tí wọ́n pa á kalẹ̀ ló tọ́ka sí pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni.
Bákan náà ni àwọn èèyàn rò o pé o ṣeéṣe kó jẹ́ àwọn ikọ̀ mìíràn ló pa á ní ìránró àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó ti pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìjà abẹ́nú wà nínú ẹgbẹ́ Bobos tí Omubo jẹ́ olórí wọn, wọ́n ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ló pa á lọ́nà tí yóò fi dàbí pé àwọn ikọ̀ mìíràn ni ó ṣekú pa á. Wọ́n ní ìdí ni pé wọ́n kò fẹ́ Omubo ní olórí wọn mọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àfikún pé oríṣìí ẹ̀sùn ni Omubo ní nílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀.
Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ni ti olóhun, Wọ́n rí òkú arákùnrin kan tí wọ́n mọ̀ ní gbajúmọ̀ olè tí wọ́n sun sí ilé ilẹ̀. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Òkú arákùnrin kan tí wọ́n ti dáná sun ni àwọn èèyàn rí láàárọ̀ yìí tí wọ́n sì ránṣẹ́ sí àwọn ọlọ́pàá.
Àwọn ará àdúgbò náà wí pé ọkùnrin náà gbóná pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀ nínú yíyọ bátìrì ọkọ̀ tí ọlọ́kọ̀ bá gbé kalẹ̀, wọ́n ní bí èèyàn gbé ọkọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lálẹ́ mọ́jú, agolo ni yóò bá láàárọ̀ ọjọ́ kejì nítorí ọkùnrin yìí àti ikọ̀ rẹ̀ ó ti tú gbogbo ẹ̀yà ara rẹ̀ lọ tó fi dé orí táyà.
Ohun tí wọ́n rò pé ó ṣẹlẹ̀ ni pé bóyá ọwọ́ bàá níbi tó ti ń tú ẹ̀ya ọkọ̀ lọ ni wọ́n ṣe dáná sun ún, kò sí ẹni tó ní pàtó ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀.
Agbègbè Iyiowa Odekpe ni èyí ti ṣẹlẹ̀ ní ijọba ìbílẹ̀ Ogbaru ní ìpínlẹ̀ Anambra.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé kí wọn ó fa afurasí lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ kí wọ́n ó yẹra fún ṣíṣe ìdájọ́ ọwọ́ fún afurasí.
Ní ìpínlẹ̀ Rivers:
Ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá kan tó gbé afurasí ni àwọn agbébọn ti dá lọ́nà tí wọ́n sì ti gbé afurasí inú rẹ̀ lọ. Tó bá ṣe pé èyí nìkan ni kò bá sunwọ̀n, wọ́n yìnbọn pa rìpẹ́tọ̀ ọlọ́pàá kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Christain Garatee.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Portharcourt sí Aba ni èyí ti ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìṣẹgun ọ̀sẹ̀ yìí.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ àbọ̀ alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, márùún ni àwọn ọlọ́pàá tó wà ninú ọkọ̀ náà pẹ̀lú afurasí yìí, nínú wọn ni Christain tí wọ́n pa yìí.
Wọ́n ti gbé òkú Christain lọ sí ilé igbókǔsí nígbà tí ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Bí a ṣe ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn mìíràn tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti Jigawa pé ọmọ kan ti ṣá bàbá rẹ̀ láṣàápa. A gbọ́ pé:
Muhammad Salisu; ẹni ogún ọdún ti ṣá bàbá rẹ̀; Salisu Abubakar ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Jigawa. Àlàyé tí a rí gbà ni pé nǹkan bíi aago mẹ́wàá àárọ̀ ni èyí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè Bakin Kasuwa, Sara, ìpínlẹ̀ Jigawa.
Lóòórọ̀ ọjọ́ Àìkú tó lọ yìí, Muhammad he àdá tó mú ṣáṣá ó sì fi ṣá bàbá rẹ̀ lápá, lọ́rùn àti léjìká. Ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Birnin Kudu ni wọ́n gbé Salisu lọ àmọ́ ó padà dágbére fáyé pé ó dìgbóṣe.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé Muhammad àmọ́ kò rí nǹkankan pàtó sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ju pé inú bíi lọ.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Jigawa; Shi’isu Adam pé ọwọ́ tó Muhammad Salisu tó ṣá bàbá rẹ̀ pa nítorí pé inú bíi, kò rí nǹkan mìíràn sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ju pé bàbá rẹ̀ múnú bíi lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti mú Muhammad sí àgọ́, wọ́n ní yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Discussion about this post