Ọjọ́ mẹ́sàn-án gbáko ni wòlíì Peter Ekweli lò ní àkàtà àwọn ajínigbé kó tó di pé ó dé padà ní ìrọ̀lẹ́ àná.
Ilé ìjọsìn Àgùdà ti St Peter tó wà ní Ivukwa ní ìjọba ìbílẹ̀ ìlà òòrùn Etsalo, ìpínlẹ̀ Edo ni èyí ti ṣẹ̀.
Wòlíì Peter Andrew tí wọ́n jí gbé pẹ̀lú rẹ̀ kò tíì dé o, Peter Ekweli ṣe àlàyé pé wọ́n ní kí gbogbo àwọn ó díjú, lẹ́yìn náà ni àwọn gbúrǒ ìbọn, nígbà tí wọn yóò lajú, wòlíì Peter Andrew ni wọ́n bá tó ń japoró.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ló gba àwọn èèyàn náà sílẹ̀ pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ń bọ̀ lọ́nà.
Nígbá tí a ń dúró de àlàyé àwọn ọlọ́pàá, ẹ jẹ́ a ṣàṣàrò lórí ìjínigbé tó ti wá di eegun ẹja sí wa lọ́rùn nílẹ̀ yìí. ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gan-an kò le sọ ní pàtó iye àwọn èèyàn tí wọ́n jí gbé lọ́jọ́ kan, owó tùùlùtuulu ni àwọn ẹbí ẹni tí wọ́n bá gbé fi ń gbára kí èèyàn wọn le padà wálé ìyẹn ò tún wá ní kí wọn ó fi ẹni náà sílẹ̀ láàyá. Ọ̀rọ̀ yìí ń fẹ́ àmójútó kíákíá, kí ìjọba ó tètè gbé ìgbésẹ̀ tó nípọn.
Ṣé ẹ rántí agùnbánirọ̀ tí wọ́n gbé ní Ore lẹ́nu lọ́lọ́ yìí, ìwé ìròyìn yorùbá kọ ọ pé ‘Àgùnbánirọ̀ ni Rofiat Lawal, ìlú Ogbomosho ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó ti ń sin ilẹ̀ bàbá rẹ̀, Ogbomosho náà ló ń lọ tí àwọn ajínigbé fi gbé e lójú ọ̀nà Benin sí Ìbàdàn.
Rofiat lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo, Ogbomosho níbi tó ti ń sìnlú ló ń padà sí tí àwọn ajínigbé fi gbé e lọ.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agbakwara ṣe àlàyé pé Rofiat pe òun láti àkàtà àwọn ajínigbé náà pé kí òun ó bá òun wá ogún mílíọ̀nù náírà owó ìtúsílẹ̀.
Agbakwara ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn òbí Rofiat kò là bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ṣagbe, ìbo ni kí wọ́n ti rí adúrú owó náà?
Aminat Lawal, ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Rofiat bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé Rofiat pè lórí aago tó sì ń sunkún pé kí wọn ó bá òun tu owó ìtúsílẹ̀ náà. Ogún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n bèèrè fún àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ ti gba sí mílíọ̀nù márùn-ún náírà.
Aminat rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíría láti má dá àwọn dá èyí kí wọn ó dákun dábọ̀ fi iye tí wọ́n bá ní ránṣẹ́ kí wọn ó le gba Rofiat kalẹ̀.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé nínú ọ̀rọ̀ tí Rofiat sọ ni wọ́n ti ríi dì mú pé awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajinigbe lọ́wọ́.
Èrò Ìbàdàn ni ọkọ̀ náà kó láti Benin, bó ṣe dé Ore ló dúró tí àwọn ajinigbe ọ̀hún sì jáde láti inú igbó. Fúnra awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́ tó sì bá tirẹ̀ lọ.
Aminat ṣe àlàyé pé àwọn ti kàn sí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ èsì tí àwọn gbà náà ni pé Rofiat kò gba ìyànda tó fi lọ sí ilé, wọ́n ní àwọn ti ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn àgùnbánirọ̀ láti máa gba ìyànda bí wọ́n bá fẹ́ lọ sí ilé tàbí rin ìrìnàjò kankan’
Nínú ọ̀sẹ̀ náà ni wọ́n tú Rofita sílẹ̀ lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ mílíọ́nù márùn-ún, ẹnu rẹ̀ kọ ìròyìn ohun tí ojú rẹ̀ rí, ó ṣe àlàyé pé inú igbó ni wọ́n kó àwọn wọ̀, ìrìn àrìnwọ́dìí ni wọ́n rìn ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n fi wà níbẹ̀, gààrí sì ni wọ́n ń fún wọn jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Rofiat wí pé bí wọ́n ṣe lu àwọn yòókù tó, ìwọ̀n ìyà díẹ̀ ni òun jẹ. Ìdí ni pé ọ̀kan nínú wọn fẹ́ràn òun ó sì wí pé òun ó fẹ́ òun lọ sí Sokoto.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àjọ agùnbánirọ̀ pé kí wọn ó fún òun ní àkókò díẹ̀ láti sinmi àti láti gba ìtọ́jú kí òun tó padà sí ẹnu iṣẹ́.
Ṣebí ẹni tó bá bọ̀ á gbégbá ọpẹ́, mélòó làwọn tí wọn ò ní àǹfààní àtibọ̀? Bí wọ́n sì ṣe ń ṣe é ni wọ́n ń mú un jẹ, kódà, àpò owó ilé ìfowópamọ́ ni wọ́n fi ń gba owó ìtúsílẹ̀, ṣé ẹ̀yin náà wá rí i pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́, lóńgẹ́ fúnra rẹ̀ ewu ni.
Nígbà tí àwọn ajínigbé tó wà nígboro ń ṣọṣẹ́ lọ, ìjọba àpapọ̀ tún dáríji Evans ògbóǹtarìgì ajínígbé tó wà lẹ́wọn. Ṣé ó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀? Ṣé lásìkò tí ìjínigbé ń lọ lọ́tùn-ún lósì ni ìjọba tún ń dá ògbóǹtarìgì sílẹ̀, kí àrá le ran bọ́ḿbù lọ́wọ́ kọ́ yẹn?
Agbẹjọ́rò rẹ̀ tilẹ̀ gbìyànjú, ó wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n gbére ni ìjọba àpapọ̀ dà fún Evans fún ẹ̀sùn ìjínigbéṣowó àti ẹ̀wọ̀n ọdún mérìnlá fún dída omi àlááfíà ìlú rú, wọ́n ti dá òun sílẹ̀ nígbà tí òun ti ronúpìwàdà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Evans ní òun ti kẹ́kọ̀ọ́gboyè Olùkọ́ni , òun ti gba ìwé ẹ̀rí (NCE) ti ilé ẹ̀kọ́ gíga tàwọn olùkọ́ni ti ìlú Yewa. Ẹ̀kọ́ nípa ọrọ̀ ajé ni òun kọ́, òún sì yege lọ́dún mẹ́ta ẹ̀kọ́ náà. Evans tún ti ń kàwèé síi ní ifáfitì NOUN tí Ààrẹ Olúṣẹgun Ọbásanjọ́ dáálẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjìríà.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ ní kí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó dá a sílẹ̀ nítorí kí ó le è lọ lo ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tuntun rẹ̀ fún ànfàáni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Nígbà tí Evans bá padà sí ìlú, bóyá ladìyẹ máa ṣẹ́kù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé òun yóò máa ṣe iṣẹ́ olùkọ́ nísìn yìí ni pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè iṣẹ́ olùkọ́ lásìkò tóun wà lẹ́wọ̀n, ṣé a máa tán lára dìgbòlugi kó má rí nǹkan dẹ́rù bọ́mọ ni? Ṣé kìí ṣe pé àwọn ọmọ ilé ìwé ó máa pòórá bíi isó ni báyìí? Ẹ gbọ́ ná, ǹjẹ́ ẹ̀yin le fi ọmọ tiyín sí ilé ìwé tí Evans ti jẹ́ olùkọ́?