Innocent Idibia; Olórin tàkasúfèé tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Tuface ti gbé olólùfẹ́ rẹ̀ titun, ẹni bí ọkàn rẹ̀, ààyò tí jẹyin òṣùpá lọ sí Vodi; ibi tí wọ́n ti ń ta àwọn aṣọ ìgbàlódé.
Tẹ̀rín tẹ̀yẹ ni Oluwaseyi Adekunle; ẹni tó ni Vodi fi gba Tuface àti Natasha káàbọ̀ sí ilé ìtaṣọ rẹ̀. Nínú fọ́nrán tí wọ́n fi léde náà la ti rí Natasha tó ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó ń yẹ àwọn aṣọ náà wò ó sì fi èyí tí yóò wọ̀ lọ́jọ́ Ajé lọ sí ìjókòó ilé hàn wá.
Ẹ má gbàgbé pé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ìpínlẹ̀ Edo ni Natasha, òun ló ń ṣojú ẹ̀kun Egor nílé ìgbìmọ̀ aṣofin.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn ẹbí Tuface kò dunú sí ìfẹ́ òun àti Natasha, ẹni tí Natasha ń bá nájà ló kọjú mọ́ ní tirẹ̀, kò jísòró rárá.
Kódà, nígbà tí iná ìfẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, ìyá Tuface ké gbàjarè. A mú ìròyìn náà wá pé ‘A kìí ní igi lóko ká má mọ èso rẹ̀, ìyá tó bí gbajúgbajà olórin nnì Tuface ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Natasha pé kó dákun dábọ̀ tú ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tó dè é mọ́.
Arábìnrin Rose Ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nínú fọ́nrán kan tó gbòde pé ọmọ òun ìyẹn Innocent tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Tuface kìí ṣe irú ọmọ bẹ́ẹ̀ pé dájúdájú ejò lọ́wọ́ nínú.
Àlàyé ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ni pé Innocent ti jáwě ìkọ̀sílẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀ Annie.
Oríṣìí àwọn ẹ̀sùn bíi àìbìkítà ni Innocent fi kan Annie ìyàwó rẹ̀.
Orí ìkọ̀sílẹ̀ yìí ni òun àti Annie wà tí Tuface fi fi fọ́nrán òun àti Natasha léde. Nínú fọ́nrán yìí ni òun àti Natasha ti ń dáfẹ̀ẹ́ tí ó sì fún un ní òrùka ìfẹ́.
Àwọn ọ̀rẹ́ wọn wà ní ibẹ̀, wọ́n bá wọn dáwọ̀ọ́ ìdùnú pẹ̀lú.
Oríṣìí ìhà ni àwọn èèyàn kọ sí fọ́nrán yìí, àwọn àríwísí tí a rí gbà ni pé Natasha ni eku ẹdá tó dá wàhálà sílẹ̀ láàrin Innocent àti ìyàwó rẹ̀. Wọ́n ní òun ni túlétúlé tó tú ilé Tuface kó le rí ibẹ̀ wọ̀. Kò sí orúkọ tí wọn kò pè é tán, láti orí túlétúlé tó fi dé orí gbọkọgbọkọ.
Èsì tí àwọn èèyàn fọ̀ yìí kò tẹ́ ọkọ ìyàwó lọ́rùn, ó ṣe fọ́nrán mìíràn tó ti ṣe àlàyé pé Natasha kìí ṣe gbọkọgbọkọ o, ó ní òun kọ́ ló da aarin òun àti Annie rú o pé kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.
Innocent ṣe àlàyé pé òun nífẹ̀ẹ́ Natasha dọ́kàn ni òun sì fẹ́ fi ṣaya. Ó ṣe àpèjúwe Natasha bíi arẹwà, ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ tó gbá múṣé ó sì wí pé òun nífẹ̀ẹ́ Natasha ni o òun yóò sì fi ṣe aya.
Ta ni Natasha?
Natasha Osawuru ni àpèjá orúkọ arábìnrin yìí. Ó jẹ́ olóṣèlú, inú oṣù igbe ọdún 2023 ni wọ́n dìbò yàn án sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo. Natasha ló ń ṣojú ẹ̀kun Egor lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ní báyìí, ìyá Innocent ti ganu sí ọ̀rọ̀ náà pé kí àwọn èèyàn ó bá òun bẹ Natasha kó tú ọmọ òun sílẹ̀ o nítorí pé òun mọ̀ pé orí Innocent kò pé mọ́ lásìkò yìí.
Arábìnrin Rose Idibia ṣe àlàyé pé òun mọ Innocent ọmọ òun dáadáa, kìí ṣe ẹni tó le kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí náà kí Natasha ó tú ẹ̀gbà ọrùn to fún ọmọ òun nítorí pé òun ló fi dè é mọ́lẹ̀’
Ipò tí Annie wà báyìí.
Annie Idibia, ìyàwó ilé Tuface Idibia kò wà dáadáa láti ìgbà tí ọkọ rẹ̀ ti jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún un. Ọdún kejìlá rèé tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó, ọmọ méjì ló wà láàárín wọn. Lóòótọ́, wọ́n ti máa ń ní àwọn gbólóhùn asọ̀ ṣaájú àsìkò yìí, kódà, Tuface ti kúrò nílé nígbà kan rí àmọ́ wọ́n máa ń parí aáwọ̀ wọn àfi èyí tó kọ̀ tí ò parí yìí.
Ìjayà ni gbogbo ọ̀rọ̀ ìkọsílẹ̀ Annie mú báa, ó sì dá kún àìlera rẹ̀. Ó ti lọ fún ètò àtúntò àti àtúnṣe Rehab lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ìlera rẹ̀ ló mú lọ́kùn-úndùn ju ti ìkọ̀sílẹ̀ náà lọ.
Annie kọ̀ láti fi àtẹ̀jáde léde lórí ọ̀rọ̀ náà àmọ́ àwọn tó sún mọ́ ọn wí pé ipò ìlera rẹ̀ ń ṣe ṣégeṣège.
Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró.
Annie ń pààrà ilé ìwòsàn nítorí àìlera rẹ̀, Tuface ń gbé olólùfẹ́ rẹ̀ titun lọ ra aṣọ, kí ló le mú ìfẹ́ tó dun bíi oyin tẹ́lẹ̀ ó parade kan bíi ìbó?
Discussion about this post