Gẹ́gẹ́ bí ohun tí aya gómìnà àná ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó ìyẹn Betty Anyanwu Akérédolú ti wí nípa bí ohun gbogbo ṣe lè kankan bí ìsó wúńdíá lórilẹ̀-èdè yìí, ó ní àwọn tó bá ń rí nǹkan pọ́nlá lábẹ́ ìjọba Ààrẹ Tinubu nìkan ni kò ní í bìkítà fún bí nǹkan ṣe rí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Àsìkò tí àwọn kan ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ló ṣàlàyé ọ̀rínkinniwín yìí.
Aya Akérédolú ní kò sí eni tí kò mọ̀ bí ìnira tí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yìí ń mú bá wa ṣe pọ̀ tó; àfi àwọn tó bá jẹ́ abẹ́ṣin-káwọ́ ìjọba àpapọ̀. Ó ní bí ohun gbogbo ṣe gbówó lórí ti jẹ́ kí ó ṣòro fún ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ra ohun amáyédẹrùn; ohun gbogbo ló wọ́n bí imí eégún ; oúnjẹ́ wọ́n ; epó wọ́n àti àwọn ohun amúgbàdẹrùn mìíràn
” Àwọn tó bá ń rí jẹ lábẹ́ ìjọba nìkan ni yóò sọ pé gbogbo rẹ̀ẹ́ tùbà-tùṣẹ” Ó ní ìṣẹ́ àti ìnira náà pọ̀ débi pé a ò ṣẹ̀ṣẹ̀ lè máa nàka rẹ̀ fáráyé rí.
Ó wá ń rọ ìjọba tó wà lóde kí wọ́n tètè gbé ìgbésẹ̀ láti dín ìyà náà kù ní kíá. Ó ní kí àwọn olóṣèlú mú ìgbáyé-gbádùn aráàlú níbàádà ju ìmọtara wọn lọ. Akérédolú tún rọ àwọn aṣáájú kí wọ́n jẹ́ alákòóyawọ́ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní ilẹ̀ Nàìjíríà, kí wọ́n sì gbájú mọ́ ọ̀nà àbáyọ tòótọ́, dípò àfẹnuṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí kì í kún agbọ̀n.
Ohun tí aya Akérédolú sọ yii tún jẹ́ àfikún àwọn ìpè lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan fún ètò ọrọ̀-ajé tó bẹ́súẹ́; àti Ọ̀nà láti sọ ìgbà dẹ̀rùn fún mùtúmùwà.