Orílẹ̀-ède Saudi ti kéde pé àwọn ti rí òṣùpá titun tó ṣe àmì ìbẹ̀rẹ̀ oṣù ọdún iléyá. Ọ̀la, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Èbìbí ni yóò jẹ́ ọjọ́ kìíní, oṣù tó gbẹ̀yìn oṣù Mùsùlúmí náà.
Wọ́n wí pé ọjọ́ karùn-ún, oṣù Igbe ni àwọn alálàájì yóò gun Àràfá nígbà tí iléyá yóò jẹ́ ọjọ́ kẹfà, oṣù Igbe tó ń bọ̀ yìí.
Bí a bá sì wo àyíká wa, a ó ríi pé pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún iléyá ti bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìkéde yìí, gbogbo àwọn odò ẹran ló ti kún fún àgbò ọdún tí oníkalukú sì ti ń nawọ́ mú tirẹ̀.
A gbàá ládùúrà pé kò ní jẹ́ àṣemọ fún àwa àti ẹ̀yin, àmín.
HAJJ 2025.
Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ hájì ọdún yìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adizatu Dazumi ti dágbére fáyé lọ́hùn-ún. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin ni Adizatu lásìkò ikú rẹ̀ yìí. Ilé ìwòsàn King Fahad ló dákẹ́ sí láàárọ̀ àná; ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ́.
Ọmọ ìpínlẹ̀ Edo ni Adizatu, alága ètò hájì ìpínlẹ̀ Edo; Musah Uduimoh ló túfọ̀ ikú Adizatu lónìí ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Àlàyé tí Musah ṣe ni pé lẹ́yìn tí Adizatu parí tàwáàfù ni àárẹ̀ náà dé bá a tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìyẹn lọ́jọ́ Àìkú tó sì padà dákẹ́ lọ́jọ́ Ajé.
Wọ́n ti sin Adizatu sí Mẹ́kà ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí wọ́n sì ti fi tó àwọn ẹbí rẹ̀ létí. Musah fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí Adizatu ó sì kí wọn kú aráfẹ́rakù.
NÍ IKORODU.
Ilé alájà méjì kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní agbègbè Ota-Ona ní Ikorodu ti dà wó lulẹ̀ lọ́sàn-án àná, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Èbìbí.
Rasheed Fatuga ló kọ ọ́ sí ojú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé ilé náà tó wà ní àdojúkọ ilé epo Mobil ti dà wó lulẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọlọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ nínú rẹ̀.
Kíá ni àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti dé ibẹ̀. Àwọn èèyàn márùn-ún ni wọ́n ti rí yọ láàyè báyìí àmọ́ a kò le sọ pàtó iye àwọn èèyàn tó ṣì wà lábẹ́ èérún ilé náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ilé dídàwó ti di ohun àpérò fún ìjọba báyìí pàápàá àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́. Nínú ọdún yìí nìkan, ó ti lé ní ilé márùn-ụn tó ti dà wó lulẹ̀. Bẹ́ẹ̀ kò sí èyí tí kò mú ẹ̀mí dání.
Èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Berger tilẹ̀ burú jáì nítorí pé ilé oúnjẹ kan wà níbẹ̀ tó sì kún fọ́fọ́ lásìkò náà. Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kà báyìí pé:
Ilé alájà méjì kan tó wà ní òpópónà ọ̀rẹ́mẹ́ta ní Ojodu-Berger, Èkó ti dà wó ní àárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Igbe. Inú ilé yìí ni ilé oúnjẹ ìgbàlódé nnì Equal rights wà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n wà níbẹ̀ lásìkò tó dà wó náà.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ń lọ lù ni ilé náà ṣàdédé bì wó. A rí àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ panápaná tí wọ́n ti ń gbìyànjù láti dóòlà ẹ̀mí àwọn tó há náà.
Akọ̀wé fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó; Dọ́kítà Oluwafemi Oke-Osanyintolu ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé èèyàn márùn-ún ni àwọn ti rí yọ láàyè báyìí, wọ́n ní ọgbọ́n ni ọ̀rọ̀ náà gbà àwọn sì ti kó àwọn irin iṣẹ́ ńlá ńlá tí wọn yóò lò dé. Dọ́kítà Oluwafemi wí pé àwọn ń ti igun kan bọ́ sí ìkan ni láti wá àwọn èèyàn tó há náà.
Ní báyìí, ìròyìn ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti rí òkú ẹnìkan nínú èérún ilé náà, ilé iṣẹ́ to ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wí pé àwọn ko le sọ iye àwọn èèyàn tó há gan-an ní pàtó nítorí pé àwọn èrò pọ̀ nínú ilé oúnjẹ náà lásìkò tó wó. Wọ́n ní àwọn ń tẹ̀síwájú nínú wíwá àwọn èèyàn náà jáde nígbà tí àwọn èèyàn ní ìrètí àtirí ẹbí wọn padà láàyè.
IPÒ WO NI ILÉ TÓ DÀ WÓ NÁÀ WÀ TẸ́LẸ̀?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ́ kan kìí déédé ṣẹ́, àwọn akọ̀ròyìn gbìyànjú láti mọ ipò tí ilé alájà méjì náà wà tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí ó tó dà wó yìí. Ẹnìkan tí ìsọ̀ rẹ̀ wà ní ìtòsí ibẹ̀ àmọ́ tí a kò ní le dárúkọ rẹ̀ ṣe àlàyé pé ilé náà ti kẹ láti ọjọ́ tó ti pẹ́, ó ní òun kìí tilẹ̀ ra oúnjẹ níbẹ̀ nítorí pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ó le dà wó nígbàkúùgbà.
Ẹlòmíràn náà wí pé ó ti pẹ́ tí àwọn ará àdúgbò ti ń ṣe ìkìlọ̀ pé ilé náà le dà wó nítorí pé ó ti kẹ kalẹ̀ àmọ́ kò sí ẹni tó kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí.
Ní báyìí,ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló sì ti há sí abẹ́ rẹ̀.
Ìyẹn ọ̀kan, ilé mìíràn tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ dà wó ní inú oṣù Igbe tó kọjá yìí kan náà. A gbọ́ pé:
Ilé alájà mẹ́ta tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpópónà Agarawu ní Island, Èkó kò jẹ́ tí wọn ó kọ́ òun tán tó fi dà wó lulẹ̀. Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Igbe tí a wà yìí ni ilé náà dà wó lulẹ̀ wìì. Àwọn òṣìṣẹ́ méjì ló farapa yánnayànna.
Nínú ọ̀rọ̀ tí agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin sọ ni a ti ríi dì mú pé nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ni ilé náà bì wó lọ́jọ́ náà, ilé yìí sì farati ilé ìwòsàn ìjọba alábọ́dé primary health center Agarawu ni. Kíá ni wọ́n ti gbé àwọn òṣìṣẹ́ méjì náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Marina fún ìtọ́jú.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà dídàwó náà.
Ọdún iléyá la ń múra rẹ̀ lọ́wọ́, ilé ò ní wó pa wá a ò ní rìn lọ́jọ́ tí ebi ń pa ọ̀nà. Àṣèyìí ṣẹ̀míì.
Discussion about this post