Ó ti lé lọ́dún kan gbáko báyìí ti Ọba Alápetúmodù ti Ìlú Ìpétúmodu ti di àfẹ́kù. Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni Ọba Joseph Olugbenga Oloyede dágbéré fún gbogbo ìlú pé àwọn ń lọ láti oṣù kínní ọdún 2024 tí wọn kò sì tíì padà sí ìlú títí di àsìkò yìí, òfìfò ni orí àpèrè Alápétúmọdù ti ìlú Ìpétúnmọdù wa títí di òní tílẹ̀ mọ́.
Ìdíwọ́ nla gbáà ni èyí jẹ́ fún ìwúyè àti gígun orí àpèrè Aláàfin tuntun, Ọba Owoade nitórí Bá ò rÍgún, a kò le è ṣẹbọ, bá ò rÁkàlà, a ò le è ṣoro, Bá ò rÉrelú, Òṣùgbó kan kò le è ṣe, Bá ò r’Álápetúmọdu ti ìlú Ìpétúmọdú kó gbé idà àṣẹ lé Aláàfin tuntun lọ́wọ́, Aláàfin kan ko le è joyè.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà àtayébáyé tó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò Ọ̀rànmíyàn tó jẹ́ àbíkẹ́yìn ọmọ Odùduwà látí bu ọlá fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ọ̀kan nínú wọn sì jẹ́ Alápètúmodù pé kí ó gbé idà àṣẹ lé è lọ́wọ́, orò ìkẹyìn ni kí ọba Ọ̀yọ́ tuntun tó le è jẹ tàbí gun orí àpèrè baba nlá wọn.
Bọ́mọdé ò bátàn, á bá àrọ́bá, àrọ́bá sì ni baba ìtàn; Inú ìtàn ni a ti gbọ́ pé ààyè ọ̀wọ̀ àti ààlà ni Ìpétúmọdù jẹ́ sí ìlú Ọ̀yọ́, dandan sì ni kí Ọba Joseph Olugbenga Oloyede ó ṣe é bí wọ́n ṣe ń ṣe é, kó le è rí bó ti yẹ kó rí fún Aláàfin tuntun; Ọba Owoade.
Oríkì orílẹ̀ ìlú Ìpétúmọdù tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ‘Ẹ̀yin lọmọ á gbédà f’Áláàfin…..’
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àhésọ là ń gbọ́ lórí rírá tí Ọba Ìpétúmọdù rá, àwọn kán ló n jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìkówójẹ òbítíbitì owó nílẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn kan tilẹ̀ ló ní ọwọ́ kan ọ̀wọ̀ kan àwọn Ọ̀yọ́mèsì nínú látàrí pé Aláàfin tuntun kìí ṣe Ìlúfẹ́milóyè.
Gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun n rọ Gómìnà Ademola Adeleke láti gbé ìgbésẹ̀ Akin lórí ọ̀rọ̀ yìí.