Láti ọdún 2024 ni Onoriode Bethel ti sọ̀nu tí wọ́n sì ti ń wá a, inú ilé ìtura Century Home tó wà ní Owehlogho ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ níbi tí wọ́n sin ín sí.
Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí àwọn ọlọ́pàá wá lọ sí ilé ìtura náà tí wọ́n fi túlé kan òkú Bethel. Arákùnrin arìnrìnàjò kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sunday Ogofohta ni ó sun ilé ìtura Century Home tí kò sì padà jáde mọ́.
Sunday ni àwọn ọlọ́pàá tọpinpin lọ sí ibẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní tú gbogbo yàrá, wọ́n kan yàrá kan tó ṣe pé òkú àwọn èèyàn ni wọ́n ń sin sínú rẹ̀, lára àwọn tó ti sin síbẹ̀ ni Bethel wà.
Iboirode ni orúkọ alámòójútó ilé ìtura yìí, ó jẹ́wọ́ pé òun ló pa Bethel ní ọdún 2024 nítorí pé ó ba òun lórúkọ jẹ́. Iṣẹ́ fi ẹ̀rọ gbowó POS ni Bethel ń ṣe, ní ọdún tó kọjá, Iboirode fi èrú gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ rẹ̀, nígbà tí Bethel padà ríi pé òfegèé ni àtẹ̀jíṣẹ́ owó tí Iboirode fi ránṣẹ́ sí òun, ó kò ó lójú ó sì gba owó rẹ̀.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni Iboirode tàn án wọ inú ilé ìtura náà pé òun fẹ́ parí ìjà náà, ó tìí wọ inụ́ yàrá náà tí ó máa ń sin àwọn èèyàn sí, ó gba píínì ẹ̀rọ POS rẹ̀ kí ó tó pa á. Lẹ́yìn náà ló wọ́ gbogbo owó tó wà nínú àpò owó náà, ó tún pe bàbá Bethel pé kí ó san owó ìtúsílẹ̀ ọmọ rẹ̀.
Ìyàwó Iboirode náà jẹ́rìí síi pé ọkọ òun máa ń pa àwọn arìnrìnàjò tó bá wá sun ilé ìtura náà, yóò wọ́ owó inú àpò owó náà yóò sì tún gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta wí pé afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú ìròyìn báyìí má jáde nípa àwọn tó ni ilé ìtura.
Ọdún tó kọjá náà ni wọ́n ṣe àwárí ilé ìtura Udoka Golden Point tí wọ́n tún dà pè sí La cruise níbi tí wọ́n ti ń ṣe àpatà àwọn èèyàn.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ilé ìtura ni àwọn èèyàn ń wò lórí ilẹ̀ náà, àmọ́ abattoir èèyàn ni ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
Udoka Golden point hotel tí wọ́n tún dà pè sí La Cruise hotel ni àsìrí rẹ̀ lu síta lónìí.
Ó lé ní ọgbọ̀n sàrê tó wà ní ìsàlẹ̀ ilé náà, ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró, oògùn dúdú, igbá ẹbọ àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló farasin sí abẹ́ ilé ìtura yìí.
Omi gbígbóná kò gbọdọ̀ pẹ́ lẹ́nu, ọwọ́ kò gbọdọ̀ pẹ́ nísà akekě, ìjọba ti da ilé náà wó.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Onitsha sí Owerri ní ìpínlẹ̀ Anambra ni ilé ìtura yìí wà, àwọn ajinigbe àti agbénipa ló tẹ̀dó sí ibẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi ilé ìtura ni wọ́n fi bo ojú ilé náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ló fúnra rẹ̀ kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lójú òpó X rẹ̀ pé àwọn da ilé ìtura là cruise wó nítorí àwọn èèyàn ni wọ́n ń pa tà ní ibẹ̀.
Mélòó la ó kà nínú eyín adìpèlé? Ṣé ẹ rántí Timothy tí wọ́n pa nílé ifẹ̀? Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo ni Timothy, ilé ìtura Hilton ló dé sí fún ìdánwò tó fẹ́ ṣe nílé ìwé náà, oorun tí Timothy sùn nílé ìtura náà kò padà jí sáyé.
Ẹni tó ni ilé ìtura náà; Rahman Adedoyin ni adájọ́ ti dá ẹjọ́ ikú fún báyìí.
Ti àwọn onílé ìtura lápá kan, èwo ni kí èèyàn ó tún wọ akérò dáràn? Kìí tún ṣe ọkọ̀ ìgboro o, ọkọ̀ akérò ìjọba BRT ni Bamishe wọ̀ tí kò padà délé mọ́.
Ìgbẹ́jọ́ ikú Bamishe ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní kọ̀pẹ́kòpẹ́ yìí níbi tí adájọ́ ti pàṣẹ kí wọn ó so awakọ̀ rọ̀ títí ẹ̀mí rẹ̀ ó fi bọ́.
Ìròyìn náà kà báyìí pé
Awakọ̀ BRT tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ṣekú pa Oluwabamishe Ayanwola ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó ti dá ẹjọ́ ikú fún lónìí, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí.
Andrew Ominikoron ni orúkọ awakọ̀ BRT náà, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó bá Bamishe ní àjoṣepọ̀ tìpátìkúùkú ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ẹni ọdún méjìlélógún ni Bamishe, ní ọjọ́ náà lọ́hùn-ún, Bamishe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ ó sì wọ ọkọ̀ BRT tí Andrew jẹ́ awakọ̀ rẹ̀. Ohùn tó fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa bí Andrew ṣe gbé àwọn èèyàn kan lọ́nà àti bí ara ṣe fu ú ni ó jẹ́ ẹ̀rí nígbà tí wọ́n rí òkú rẹ̀.
Àti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin mìíràn tó ti fipá bá lò pọ̀ sì jáde sọ̀rọ̀.
Òní ni adájọ́ Sherifat Sonaike gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà pé Andrew jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Lẹ́yìn èyi ni àwọn ẹbí Bamishe bèèrè fún ìfòfingbé àwọn tí wọ́n jọ pa á pé
Àwọn ẹbí Bamishe Ayanwola bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tí adájọ́ gbé kalẹ̀ .
Ẹ̀gbọ́n Bamishe tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Onaopemipo Damilola wí pé àwọn dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Adájọ́ Sherifat Sonaike lórí ìdájọ́ òdodo tó gbé kalẹ̀ àmọ́ àwọn tí wọ́n jọ pa Bamishe kò jẹ́jọ́ rárá.
Damilola wí pé àwọn yóò fẹ́ kí àwọn méjì tí wọ́n jọ pa ọmọ náà ó fojú ba ilé-ẹjọ́ kí wọ́n má mu un jẹ.
Discussion about this post