ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Tó Gbòde

ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN ADIGUNJALÈ MÁRÙN-ÚN TÍ WỌ́N DÍBỌ́N BÍI Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
December 25, 2025
in Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
23
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti tẹ àwọn márùn-ún kan tí wọ́n ń dúró lọ́nà gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé àmọ́ tó ṣe pé adigunjalè ni wọ́n.
Àwọn ẹni yìì yóò gbé ọkọ̀ kórópe wọn tí wọ́n ti kùn ní ààwọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò jáde, wọn yóò dá àwọn awakọ̀ dúró lójú pópó wọn yóò sì jà awakọ̀ náà lólè.
Ọkùnrin ni gbogbo àwọn márùn-ún yìí, agbègbè Ring Road ní ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Awka ni wọ́n ti ń ṣọṣẹ́. Orúkọ wọn ni; Solomon Saddah, Okolocha George Kaosisochukwu, John Obi Ogwaju, Chukwuemeka Chisom Ikenwa àti Eze Obinna Joshua.
Àwọn ohun tí wọ́n rí gbà padà lọ́wọ́ wọ́n ni ìbọn, ọta ìbọn, ọkọ̀ kórópe, ìbojú àti àwọn nọ́ḿbà ọkọ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ní àwọn ní fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò lọ́wọ́ wọn yóò sì fi ojú ba ilé ẹjọ́ lọ́gán tí ìwàdìí bá parí.

MỌ̀LÉBÍ CHISOM TI GÚN UN PA NÍTORÍ ṢÁJÀ!

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Chisom ti dèrò lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gún un lọ́bẹ káàkiri ara.
A gbọ́ pé Chisom yá ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ lásìkò yìí ní ṣájà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kó dẹ̀ gba ṣájà rẹ̀ padà ni ọ̀rọ̀ bá ṣebí ọ̀rọ̀ láàrin wọn, ẹni tó yá ní òun kò ṣetán àti dá a padà, Chisom yarí pé òun yóò gbà á dandan.
Èyí ni wọ́n ń fà tí ọmọ náà fi fa ọ̀bẹ yọ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gún Chisom. Àbúrò bàbá rẹ̀ tó jẹ́ bàbá ọmọ náà kún ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti gún un wọ́n sì gún un káàkiri ara ní èyí tí ojú ọgbẹ́ rẹ̀ kò ṣe é kà.
Agbègbè Ihiala ní ìpínlẹ̀ Anambra ni èyí ti ṣẹ̀ lọ́jọ́ kọkàndínlógún, oṣù Ọ̀pẹ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò fa ìbínú yọ, wọ́n sọ iná sí ilé àbúrò bàbá Chisom.
Àti bàbá àti ọmọ ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí. Wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aye ni Chisom àmọ́ ẹni tó gún un pa náà kò sí nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kankan.
A kò rí Tochukwu Ikenga; agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra bá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

ỌKỌ̀ ÀJÀGBÉ ELÉJÒ DÀNÙ LÓRÍ AFÁRÁ OJUELEGBA.

Okọ̀ àjàgbé akẹ́rù kan ti gbókìtì nígbà tó kù gẹ̀rẹ̀ kó sọ̀ kalẹ̀ lórí afárá Ojúẹlẹ́gba ní àbáwọ Surulere.
Gẹ́gẹ́ bíi ohun tí Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA fi léde, ọkọ̀ àjàgbé náà ga tó ìwọ̀ ẹsẹ̀ ogójì bàtà. Nígbà tí ọkọ̀ náà sọ̀ kalẹ̀ lórí afárá náà ní àbáwọ bárékè ni ó ṣàdédé gbókìtì tó sì dùbú ọ̀nà.
Kò sí ẹni tó farapa nínú èyí ó kàn dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ ni. Àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ti wà níbẹ̀ láti wọ́ ọ kúrò kí ọ̀nà le já geere.

ỌKỌ̀ ÀJÀGBÉ AGBÉPO GBANÁ NÍ ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́ ỌDÚN KÉRÉSÌ.

Àwọn èèyàn méjì ló ti dèrò ọ̀run láìrò tẹ́lẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé agbépo gbaná lójijì ní ojú ọ̀nà mároṣẹ̀ Badagry, ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé tí Ọ̀gbẹ́ni Adebayo Taofiq fi léde ni pé ọkọ̀ àjàgbé agbépo náà gbìyànjú àtila ọkọ̀ tó wà ní iwájú rẹ̀ ló fi pàdánù ìjánu rẹ̀, ó gbókìtì ó sì gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Awakọ̀ náà àti obìnrin kan tó gbé síwájú ni wọ́n bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA yára pààlè síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti dènà òmíràn, wọ́n gbìyànjú àti wọ́ ọkọ̀ náà kúrò lójú pópó.

ỌKỌ̀ ÀJÁGBÉ TẸ ỌKỌ̀ AKÉRÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ GOMBE.
Kò dín ní àwọn èèyàn márùn-ún tó balẹ̀ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan kọlu ọkọ̀ wọn.
Àwọn èèyàn méjìdínlógún ló wà nínú ọkọ̀ akérò náà, ojú ọ̀nà Kaltungo sí Cham ń Kaluwa, ìpínlẹ̀ Gombe ni ìjàm̀bá náà ti wáyé.
Ọkọ̀ akérò yìí ń lọ ní tirẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kọlù ú láti ẹ̀yìn, èyí ló mú kí ọkọ̀ náà gbókìtì lọ́pọ̀ ìgbà kó tó dúró.
Àwọn èèyàn mẹ́sàn-án ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn márùn-ún farapa, àwọn mẹ́rin yòókù jáde láì farapa.
Àjọ FRSC èka ìpínlẹ̀ Gombe fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Samson Kaura pé ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì kọlu ọkọ̀ akérò náà láti ẹ̀yìn.
Ilé ìwòsàn ìjọba Kaltungo ni wọ́n kó àwọn tó farapa náà lọ nígbà tí wọ́n kó àwọn tó kú náà sí ilé ìgbókùúsí ilé iwòsàn náà.
Samson Kaura rọ àwon awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé tó le fa ìpàdánù ìjánu ọkọ̀.

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

GÓMÌNÀ SANWOOLU ṢE ÀBẸ̀WÒ SÍ ILÉ ÌDÓJÚTÒFÒ TÓ JÓNÁ.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu ti ṣe àbẹ̀wò sí ilé alájà rẹpẹtẹ Great Nigeria Insurance tó jóná lánàá, ọjọ́ kẹrìnlélógún.
Àjà kẹrin ni iná náà ti bẹ̀rẹ̀ tó sì ràn mọ́ gbogbo ilé náà, ó tún nawọ́ gán ilé alájà méje ti Radio Nigeria, ọjà Oluwole àti àwọn ilé mìíràn tó yíi ká.
Nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì jó di àárọ̀ ọjọ́ ọdún kérésì ó sì gba ilé iṣẹ́ panápaná ní wákàtí mẹ́wàá gbáko kí wọ́n tó iná náà pa.
Gboyega Akosile; ẹni tó jẹ́ olùbádámọ̀ràn Gómìnà Sanwoolu lórí àtẹ̀jáde ló fi léde pé Sanwoolu ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ohun tó tọ́ fún ìjọba tó ráyè ti ará ìlú. Ó fi fọ́nrán bí Gómìnà ṣe ń rin inú àjókù náà kọjá síta pẹ̀lú.
Àjọ tó ń gbọ́ ti ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì èka ìpínlẹ̀ Èkó LASEMA náà sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Nosa Okunbo pé àwọn kojú iná náà, àwọn èèyàn méje ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn èèyàn márùn-ún ni wọ́n fa èéfín símú tí wọ́n sì tọ́jú wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ níbẹ̀.

NÍTORÍ ẸGBẸ̀RÚN KAN NÁÍRÀ NI EZEKIEL ṢE PA MỌ̀LẸ́BÍ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.

Níbi tí Ezekiel ti ń bínú lórí ẹgbẹ̀rún kan náírà tó fẹ́ gbà ni ó ti gbá mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tí onítọ̀ún sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹni Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ni pé àwọn ẹbí Ezekiel pe ìpàdé mọ̀lẹ́bí lẹ́yìn tí wọ́n sìnkú ọ̀kan nínú wọn tán.
Níbi ìpàdé yìí ni Ezekiel ti fi àáké kọ́rí pé kí wọn ó pín owó tó ṣékù ní èyí tí ẹgbẹ̀rún kan náírà yóò kàn án nínú iye tó dá fún ìsìnkú náà.
Ọ̀rọ̀ ni di wàhálà, Ezekiel sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá gbogbo mọ̀lẹ́bí jà pé òun yóò gba owó náà dandan, ibi tí wọ́n ti ń mú un ni ó ti fi ọwọ́ gbá ẹnìkan dànù tí ìyẹn sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú pátápátá.
Ẹni ọdún méjìlélógójì ni Ezekiel, ó ní òn kábàámọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ezekiel ní ẹ̀mí burúkú kan ń gbé inú òun tó máa ń jẹ́ kí òun bínú sódí. Ẹni tó kú náà jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá Ezekiel.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyorubaÌròyìnÌròyìn Tó Gbòde
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÈÈYÀN MÉJÌ JÓNÁ NÍBI ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ ÈKÓ.

ÈÈYÀN MÉJÌ JÓNÁ NÍBI ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ ÈKÓ.

Recommended

A kò rẹ́ni ra ohun tí a ń tà- àwọn oníṣòwò Kastina figbe ta

A Kò Rẹ́ni Ra Ohun Tí A ń Tà- Awọn Oníṣòwò Kastina Figbe Ta

2 years ago
ÈÈYÀN MÉJÌ JÓNÁ NÍBI ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ ÈKÓ.

ÈÈYÀN MÉJÌ JÓNÁ NÍBI ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ ÈKÓ.

5 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.