Olajobi Taiwo ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Olajobi nígbà tí ọmọbìnrin náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.
Ìyá rẹ̀ fẹ́ nà án ló ṣe sá kúrò nílé, ọwọ́ Olajobi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló kó sí, wọ́n tàn án wọlé wọ́n sì fi ipá báa ní àjọṣepọ̀. Agbègbè Oke ila ní Ado Ekiti ni èyí ti ṣẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì; Sunday Abutu wí pé ọwọ́ àwọn ti tó Olajobi o lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá ọmọdébìnrin náà lò. Wọ́n ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà ṣọwọ́ sí ẹ̀ka tó kàn gbọ̀ngbọ̀n.
Ta ni ká di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí rù? Ṣé ìyá tó lé ọmọ síta nítorí pé ó ṣẹ̀ ni àbí ọmọ tó sá kúrò nílé nítorí ẹgba?
Ọ̀rọ̀ ìfipábánilò yìí ti gba àpérò gidi, àsìkò ti tó fún ìjọba láti gbé ìgbésẹ̀ tó nípọn lé e lórí. Ọmọbìnrin kò gbọdọ̀ rìn mọ́ ní títì, wọn ó fipạ bá a lò ni. Bí ìyá rán ọmọ níṣe, àwọn kínní burúkú yìí ò gbọdọ̀ pàdé rẹ̀ lọ́nà, ọmọ náà kò ní gbá ìbálé rẹ̀ padà délé.
Houn tó tún wá burú nípa rẹ̀ ni pé kò mọ láàárín àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ìgboro mọ́, tó fi dé inú ilẹ àti iléèwé ni wọ́n ti ń fipá bá àwọn ọmọbìnrin lò.
Ṣé ẹ rántí ìròyìn tí a mú wá fún yín nígbà kan nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì tí àwọn olùkọ́ wọn fipá bá wọn lò? A kọ ọ́ pé ‘Àwọn olùkọ́ ilé ìwé ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ni ilé ẹjọ́ gíga ti fi téèbù wọn ẹ̀wọ̀n fún bíi ẹni wọn gààrí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fipá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lò pọ̀. Ohun tó so okùn ọ̀ràn yìí mọ́ wọn lọ́run daindain ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ọmọdé lábẹ́ òfin nítorí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlọgún.
Àwọn olùkọ́ náà ni: Gbenga Ajibola; ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti Ayodele Olaofe: ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta. Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́ta ni wọ́n fi kan àwọn olùkọ́ méjì yìí, ìfipábánilò ni olúborí àwọn ẹ̀sùn náà. Àwọn olùkọ́ náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ẹni máa parọ́ lá ní ẹlẹ́rìí òun wà lọ́run, àwọn ọmọbìnrin yìí jẹ́rìí níwajú adájọ́ Adeniyi Familoni ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti. Ọ̀kan nínú wọn ṣe àlàyé pé ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ni ọ̀gbéni Ajibola ń kọ́ òun nílé ìwé náà, ó ní lọ́jọ́ náà, ọ̀gbéni Ajibola wí pé kí òun ó wọ aṣọ ilé wá ó sì fún òun ní igba náírà pé kí òun ó lọ dúró de òun ní iwájú ilé epo kan ní òpópòná ilé ìfowópamọ́ kan ní Ado-Ekiti.
Ọmọ yìí wí pé nígbà tí òun dé ibẹ̀, ọmọ kíláàsì òun kan náà dé bá òun níbẹ̀ ó sì wí pé ọ̀gbẹ́ni Olaofe ló ní kí òun ó wá dúró de òun níbẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn olùkọ́ méjéèjì yìí dé wọ́n sì kó wọn lọ sí ilé ìtura kan tó wà ní Oke-Ila, Ado-Ekiti. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n mú àwọn ọmọ náà lọ́kọ́ọ̀kan lọ sí yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n sì fi okó ba abẹ́ wọn jẹ́.
Ọmọ yìí wí pé láti ìgbà náà ni ọ̀gbẹ́ni Ajibola ti ń da òun láàmú pé kí àwọn ó tún lọ ṣe síi, nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ ló sọ fún ìyá rẹ̀ tí àwọn ìyá méjéèjì sì fi tó àwọn agbófinró létí.
Agbẹ̀jọ́rò àwọn olùkọ́ yìí gbìyànjú tirẹ̀, àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́fà ló kó wá sílé ẹjọ́ tí wọ́n wá tako ẹ̀sùn náà, ó wí pé àwọn ọ̀tá àwọn olùkọ́ yìí ló fi ìtàn náà sí àwọn ọmọ náà lẹ́nu pé irọ́ ni wọ́n ń pa.
Adájọ́ Adeniyi ṣe àyèwò àwọn ẹ̀rí àwọn ọmọ náà láti orí ìwé àyẹwò dọ́kítà nílé ìwòsàn tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọ náà gba kùmọ̀ sára tó fi dé orí ìwé ìforúkọsílẹ̀ ilé ìtura náà, Adájọ́ wí pé àwọn olùkọ́ yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún ló wọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ìdí nip é àwọn ọmọ náà jẹ́ màjèsín, ẹ̀kejì ni pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni àwọn olùkọ́ yìí àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà lábẹ́ òfin kí àwọn yóòkù ó le fi tiwọn kọ́gbọ́n’
Ṣé ẹ ríi pé Oke-ila ni eléyìí náà ti ṣẹlẹ̀? Kò síbi tí wọn kii tíí kó adìyẹ alẹ́ àmọ́ kìí ṣe bíi ká fipá bá obìnrin lò pàápàá fífi ipá gba ìbálé àwọn ògo wẹẹrẹ ọjọ́ ọ̀la.
Bí wọ́n ṣe ń fipá bá abarapá lò ni wọ́n ń fipá bá àkàndá lò, ọ̀rọ̀ náà wá dàbi ti oníkínní ńlá tí ò nítìjú. Ṣé ẹ gbọ́ nípa Ezekiel tó fipá bá àkàndá lò? A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Ezekiel Elijah; ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá tó ní ìpèníjà ara ni Ezekiel tàn wọ inú ilé rẹ̀ tó sì fipá bá a lájọṣepọ̀.
Agbègbè Aviara ní Isoko ìpínlẹ̀ Delta ni èyí ti ṣẹ̀. Àlàyé tí Ezekiel ṣe fún àwọn ọlọ́pàá ni pé òun kò mọ ọjọ́ orí ọmọ náà rárá òun kò mọ̀ pé kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe wí pé àwíjàre Ezekiel kò múná dóko. Yálà ọmọ náà gbà láti ní àjọṣepọ̀ tàbí kò gbà, ohun tó kan òfin ni pé ọjọ́ orí ọmọ náà kéré lábẹ́ òfin láti dá ìpinu ṣe.
Bright ṣàlàyé pé ìfipábánilò pàápàá ìbálòpọ̀ ọmọdé kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kékeré lábẹ́ òfin, fún ìdí èyí, Ezekiel yóò fojú ba ilé-ẹjọ́’
A rọ gbogbo òbí láti mójútó àwọn ọmọbìnrin wọn dáadáa kí wọ́n má baà ṣe àgbákò ẹpọ̀n.
Discussion about this post