Bisola ajimobi Kola-Daisi; ọmọ Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Abiola Ajimobi ti dágbéré fáyé lẹ́ni ọdún méjìlélógójì.
À kò tíì le sọ ohun tó ṣe okùnfà ikú rẹ̀ báyìí àmọ́ ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ilẹ̀ UK ló kú sí láàárọ̀ kùtù òní.
Bisola ti fìgbà kan jẹ́ olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún mínísítà fún ètò ìṣùná; Atiku Bagudu nígbà ayé rẹ̀.
Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ bàbá rẹ̀; Bolaji Tunji fi ìdí ìkú Bisola múlẹ̀ fún àwọn oníròyìn pé lóòótọ́ ni ó ti papòdà.
Ọdún 2020 ni Abiola Ajimobi tó jẹ́ bàbá Bisola dágbéré fáyé tí Bisola náà sì ti rèwàlẹ̀ lọ́dun 2025.
Bí a ṣe ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn kan tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìlú Òṣogbo nípa ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó gbẹ̀mí ara rẹ̀.
Joseph Abodunrin; ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dgbọ̀n ti pa ara rẹ̀ ní agbègbè Dagbolu ní Òṣogbo ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ṣáájú kí Joseph ó tó pa ara rẹ̀ ló ti máa ń kọ ọ́ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀ pé òun fẹ́ pa ara òun àmọ́ ìfẹ́ àwọn àbúrò òun kò jẹ́.
Láti ọdún tó kọjá ló ti ń kọ ọ́ pé nǹkan kò rọrùn fún òun, ó ní àtijẹ àtimu nira fún òun, Joseph ní òun kò gbé ayé ìrọ̀rùn rárá nítorí pé òun kò le dá bùkátà òun gbé.
Nínú oṣù Ṣẹẹrẹ ló kọ ọ́ sójú òpó rẹ̀ pé àwọn àbúrò òun yóò dirú digba lọ́jọ́ iwájú òun kò sì fẹ́ kí ikú òun ó da ìrìn àjò wọn rú.
Ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Èrèlé ni Joseph pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló kọ nínú oṣù Ẹrẹ́nà yìí tó pè ní oṣù ìpinu. Joseph ní ibi tí òun wá ìrànwọ́ lọ dá kún ìṣòro òun ni. Ó tún kọ ọ́ pé òun kò rí ìdí kankan láti gbé ayé. Ó ní òun yóò lọ bá ẹni tó dá òun.
Lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù yìí tó pa ara rẹ̀, ohun tó kọ ni pé kí àwọn àbúrò òun ó má bínú, òun kò ní le tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò náà mọ́.
Abodunrin Grace; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá Joseph túfọ ikú Joseph lójú òpó X rẹ̀, ó ṣe àpèjúwe Joseph bíi ẹ̀gbọ́n dáadáa, ó ní ẹ̀rín àti ọ̀yàyà ni ó fi ń bo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ títí tó fi padà wá pa ara rẹ̀.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ohun tí Akeem Adeoye; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn sọ náà ni pé àwọn kò rí ìfisùn kankan gbà láti ọ̀dọ àwọn ẹbí rẹ̀.
Ẹ jẹ́ ká fẹsẹ̀ kan dé orílẹ̀-ède Japan níbi tí ọkùnrin kan ti lo gbogbo èyí tó dáa nínú ìgbésì ayé rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.
Ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún kan rèé o, tó ti lo ogójì ọdún ó lé mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ tí kò mọwọ́, tí kò mẹsẹ̀, kó tóó șẹ̀șẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tó ti lo èyí tó dáa jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ nínú gáló. A gbọ́ ọ pé ọkùnrín ọmọ orile-ede Pàyán-àn (Japan) yìí ti lo ogójì ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekú pa ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì. Ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọwọ́ – mẹsẹ̀ ni ọkùnrin yìí jìyà lé lórí o.
Àwọn àgbà ní àrìn-fẹsẹ̀-sí ki í ṣe ọjọ́ kan; wọ́n sì ní kílẹ̀ tóó pòṣìkà, ohun gánnágánná ó ti bàjẹ́ o. Lẹ́yìn ogójì ọdún àti mẹ́fà tí ọkùnrin yìí ti ń ra mùúù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn tí kò kàn án rárá, ni ìjọba ilẹ̀ Pàyán-àn ( Japan) ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ọkùnrín náà kọ́ ló ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tó ń jìyà lé lórí. Ǹjẹ́ kó má jìyà gbé ni ìjọba bá fún un ní owó “ gbà-má-bìínú” bílíọ̀nù, ó lé díẹ̀ náírà kó fi tọ́jú ara rẹ̀. Ọkùnrin yìí wọnú gáló ní ọdún 1968; nígbà tó di 2014 ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i pé kò jẹ̀bi.
Ta ni ọkùnrin náà gan-an? Orúkọ rẹ̀ ni Iwao Hakamata tí wọ́n dájọ́ ikú fún ní nǹkan bí ogójì ọdún ó lé mẹ́fà sẹ́yìn. Ó sì wà látìmọ́lé, ó ń retí ọjọ́ tí wọn yóò yẹgi fóun. Àsìkò yìí ni ẹ̀rí titun mìíràn sú yọ kẹ́lẹ́, tó sì sọ ọ́ di òmìnira. Ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè ẹ̀wà soya ni ọkùnrin yìí ti ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Shizuoka. Ọ̀sán ọjọ́ kan ni wọ́n kì í mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án, tí wọ́n yí ẹjọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ pé òun ni ọ̀daràn tí wọ́n ń wá pé ó pa ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì.
Ó ti kọ́kọ́ gbà póun jẹ̀bi ẹ̀sùn náà lẹ́hinytí àwọn olopaa ti fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìyà jẹ ẹ́, tójú rẹ̀ sì ti rí pọ́nǹpọ́nnáyan ìṣẹ́. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ DNA, tí wọ́n fi yẹ ẹ̀jẹ̀ ara aṣọ tí wọ́n rí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ṣé aṣọ yìí náà ni wọ́n fi ṣe ẹ̀rí tí wọ́n fi mú un tẹ́lẹ̀. Ẹ̀yìn-ò-rẹyìn ni wọ́n wá mọ̀ pé kìí ṣe òun ló ṣekú pa ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ àti àwọn ọmọ méjèèjì tí wọ́n kú.
Agbẹjọ́rò ọkùnrin yìí ní owó tí wọ́n san fún un yìí jẹ́ owó gbà-má-bìínú tó ga jù nílẹ̀ Pàyán-àn tí wọn yóò san láti fi tu aláìsẹ̀ tá a fìyà jẹ lọ́nà àìtọ́ nínú. Ó ní ọ̀bẹ́ géni lọ́wọ́ tán, a sọ ọ̀bẹ nù, ọ̀bẹ́ ti ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ó ní ìjọba tí ṣe àṣìṣe ńlá tí kò ṣeé parẹ́ láéláé. Bákan náà, àbúrò arákùnrin yìí tó jẹ́ obìnrin, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hideko, tó ti ń ké gbàjarè lórí ìtúsílẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ látọjọ́ pípẹ́ wá, sọ pé àtìmọ́lé ọlọ́dún gbọọrọ tí wọ́n fi ẹ̀gbọ́n òun sí ti pa ìlera rẹ̀ lára jìnnà-jìnnà.
Tọ̀, ikú pa ẹni lówó lọ́wọ́, ó tún pa ẹni tí ebi ń pa, ẹni kò kú tún rẹ́wọ̀n àìmọ̀dí he. Elédùmarè kò ní jẹ́ a rin àrìnfẹsẹ̀sí. Àṣẹ.
Discussion about this post