Kò sí ìgbà tí àwọn akọ̀ròyìn wa ò kúkú ní tẹ̀ ẹ́ pa sí ìpínlẹ̀ Rivers títí oṣù mẹ́fà náà ó fi pé. Ìdí ni pé ìpínlẹ̀ náà ò yé bá ọ̀nà míì yọ lójoojúmọ́.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní yàjóyàjó báyìí tí a ní ká mú wá fún yín ní ìgbóná-ìgbóoru tí a ń jẹ ọ̀pọ̀lọ́, ṣé ẹ̀yin náà mọ̀ pé àwa ni baba nínú ìròyìn tó gbòde, ìròyìn náà ni ti olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lánàá ọjọ́ Ajé.
Ohun tí a gbọ́ ni pé Dọ́kítà George Nwaeke kọ̀wé ìfipòsílẹ̀ ránṣẹ́ sí olórí ìlú titun; Admiral Ibos-Ete Ibas pé òun kò ṣe iṣẹ́ mọ́ o.
Nínú èsì tí Ibas fi ránṣẹ́ síi ni ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò péréte tó lò pẹ̀lú òun, Ibas kọ ọ́ pé kò dùn mọ́ òun nínú pé ó ń lọ àmọ́ kò sí ohun tí òun le fi dáa dúró. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì ro rere síi fún ọjọ́ iwájú.
Àfi bí ìgbà tí Ibas ń retí kí George ó fipò rẹ̀ sílẹ̀ kó tó yan akọ̀wé ìjọba ni, Lọ́gán ló yan akọ̀wé àgbà ìjọba titun sípò. Ẹni tó yàn náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibibi Worika.
Ibas wí pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò àwọn ìwé ẹ̀rí àti àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, kò sí ẹlòmíràn tó tó ipò náà dì mú ju Ibibi Lucky Worika lọ.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ àti Gómìnà Fubara fi ohùn ránṣẹ́ síra wọn, ààrẹ fi ẹsùn kan Fubara pé òun ló ń fa rúgúdù ìpínlẹ̀ náà, Fubara náà fèsì pé òun kò mọ nǹkan kan nípa àwọn ẹ̀sùn náà.
Àwọn ẹsùn tí ìjọba Tinubu fi kan Fubara ni lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn adàlúrú láti bẹ́ ọ̀pá epo, àìkúnjú òṣùwọ̀n àti ìfẹ́ ara ẹni.
Èsì tí Fubara fọ̀ náà ni pé òun kò ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú tó ń fọ́ ọ̀pá epo káàkiri ìlú náà. Gómínà tí a dá dúró náà sọ láti inú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé rẹ̀; Nelson Chukwudi gbé jáde pé òun kò lọ́wọ́ sí tàbí mọ ohunkóhun nípa bí àwọn jàǹdùkú ṣe ń fọ́ ọ̀pá epo. Ó wí pé ẹ̀sùn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí wọn dáadáa.
Nínú àtẹ̀jáde náà la ti rí i kà pé gbogbo àwọn fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde náà níbi tí wọ́n ti fọ́ ọ̀pá epo ló jẹ́ ayédèrú. Fubara wí pé àwọn ará agbègbè náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní agbègbè wọn.
Siminalayi Fubara sọ gbangba gbàǹgbà pé òun k̀ò lọ́wọ́ tàbí mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí ìjọba àpapọ̀ fi kan òun nípa àwọn tí wọ́n ń fọ́ àgbá epo, ó wí pé kí ìjọba ó ṣe ìwádìí rẹ̀ fínní.
Nígbà tí èyí ń lọ lápá kan, dùgbẹ̀ kan tún jábọ́ láti ẹnu ààrẹ wa tẹ́lẹ̀rí; Olusegun Obasanjo ní èyí tó bu epo sí iná tó ń jó.
Kudugbẹ̀ Òótọ́ ọ̀rọ̀ ti jábọ́ látẹnu Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀ èdè yìí o. Olóyè Olusegun Obasanjo ti sọ ọ́ pé ẹní gbé pañlá ti jẹ́wọ́ o. Ó ní ọkàn nínú àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin àgbà ti jẹ́wọ́ fóun pé lóòótọ́ ni àwọ́n gba owó ìbọ̀bẹ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́wọ́ Tinubu káwọn tóó fọwọ́ sí òfin ìjọba pajawiri tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Rivers láìpẹ́ yìí.
Níbi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn oníròyìn ló ti fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-òfin Ikenga Ugochinyere sẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, Ọbásanjọ́ ní èyí gan-an ló mú kóun fẹ́ẹ́ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀. Ó ní gbogbo ìfun tó wà nínú adìẹ ọ̀rọ̀ náà ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ òún ti rí o. Ó ní lára àwọn tó gba owó náà ti jẹ́wọ́ fóun gbañgba. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Olóyè Ọbásanjọ́ ní ohun tó bá wu ẹlẹ́nu ló lè fẹnu rẹ̀ sọ o, àmọ́ òún ti gbọ́ lẹ́nu àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn gbọ̀ngbọ̀n pé òótọ́ làwọ́n tẹ́wọ́ gba owó ìbọ̀bẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là lórí ṣíṣe àtìlẹhìn fún ìjọba pàjáwìrì tí Ààrẹ Tinubu pàșẹ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Ẹ̀sùn tí Ọbásanjọ́ fi kàn yìí wáyé nítorí sísẹ́ tí alága Kọmití fún àbójútó olú ilẹ̀ yìí ní Àbújá sẹ́ pé kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Mukhtar Betara sọ pé kò sóhun tó jọ ọ́ pé àwọ́n gba owó ìbọ̀bẹ́ kankan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni káwọn tó fi àtìlẹhìn wọn hàn sí ìjọba lórí ìjọba pàjáwìrì náà.
Ní báyìí, Ọ̀gbẹ́ni Wike tó jẹ́ Mínístà fún olú-ìlú ilẹ̀ yìí ti ń pàrọwà fún Fubara pé kó wá bá òun ni Abuja, kí àwọn jọ bẹ Ààrẹ lórí ètò ìjọba pàjáwìrì tó gbé kalẹ̀ lórí rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Wike ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè yìí ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ìfẹ́ ara ẹni lọ.
Ta ni ká gbàgbọ́ nínú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, Fubara, Obasanjo àti Nyesom Wike?
Discussion about this post