Àwọn olùjọ́sìn kan tí wọ́n lọ sí orí òkè lọ pàdé Jesu ní Gálílì láàárọ̀ yìí ni ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ mẹ́rin pa nínú wọn.
Ohun tí a gbọ́ ni pé bí àwọn èèyan náà ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà ni ọkọ̀ yìí já wọ àárín wọn tó sì tẹ àwọn mẹ́rin pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn mẹ́jọ mìíràn di èrò ilé ìwòsàn.
Kíá ni àwọn èrò ti sọ iná sí ọkọ̀ àjàgbé yìí, àwọn ọlọ́pàá ló dá wọn lọ́wọ́ kọ́, wọn ò láwọn ò ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Òpópónà Billiri ní ìpínlẹ̀ Gombe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ láàárọ̀ òní ọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ ọdún àjíǹde. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn, ọ̀gbẹ́ni Buhari Abdullahi wí pé èèyàn mẹ́rin ló dèrò ọ̀run nínú ìkọlù náà nígbà tí àwọn mẹ́jọ mììràn farapa yánnayànna.
Ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì ni àwọn tó kú náà, ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Gombe tó wà ní Billiri náà ni wọ́n gbé àwọn tó farapa náà lọ.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn èèyàn márùn-ún ló bá ìjàm̀bá ọkọ̀ lọ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Ife sí Ilesa. Àlàyé tí a rí gbà ni pé Ilé iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kéde pé àwọn èèyàn márùn-ún ló gbẹ́mì mìn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta. Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Ife sí Ilesa ni ìjàm̀bá náà ti wáyé láàrín ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó kó èrò mẹ́sàn-án kan àti ọkọ̀ àjàgbé eléjò.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ yìí; Arábìnrin Agnes aya Ogungbemi ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìwàkuwà awakọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ló fàá tó fi lọ forígbárí pẹ̀lú ọkọ̀ àjàgbé eléjo náà.
Àwọn ọkùnrin mẹ́fà, obìnrin méjì àti ọmọdé kan ni ó wà nínú ọkọ̀ akérò náà, márùn-ún nínú wọn ló gbẹ́mì mìn, ẹnìkan farapa nígbà tí àwọn mẹ́ta yòókù wà lálàáfíà.
Wọ́n gbé ẹni tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tí wọ́n gbé àwọn tó kú náà lọ sí ilé ìgbókùúsí.
Aya Ogungbemi wí pé àwọn ti kó àwọn ohun ìní àwọn tó kú náà fún àwọn ẹbí wọn ní èyí tí àwọn ọlọ́pàá le jẹ́rìí sí.
Ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti ikú ọ̀gbẹ́ni Akinyele, ẹni tó dágbére fáyé lọ́jọ́ ìbí ìyàwó rẹ.
Fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan bani lọ́kàn jẹ́ púpọ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti gbọnmi lójú lónìí nígbà tí wọ́n wo fọ́nrán náà. Fọ́nrán wo ni a ń sọ nípa rẹ̀?
Fọ́nran ọ̀gbẹ́ni Akinyele tó ṣubú níbi àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí ìyàwó rẹ̀ tó sì kú náà ni. Nínú fọ́nrán náà la ti rí ọ̀gbẹ́ni Akinyele tó ń kọrin ọpẹ́ pẹ̀lú àwọn alábàáṣe lórí pẹpẹ gbọ̀ngán ìgbàlejò kan tó wà ní Egbeda, ó wí nǹkan kan sí etí ìyàwó rẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ mu omi, nígbà tí ìyàwó rẹ̀ kò tètè dáhùn, ó tún ṣẹ́wọ́ sí i, kò tó ìṣẹ́jú àáyá lẹ́yìn ìgbà náà ló múdìí lọlẹ̀ tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ dágbére fáyé.
Wọ́n tilẹ̀ ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn àmọ́ àwọn dọ́kítà ní ọ̀gbẹ́ni Akinyele ti kú kí wọ́n tó gbé e dé. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò tíì fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀.
Lónìí yìí kan náà ni wòlíì ìjọ Àgùdà nnì; Wòlíì Francis dágbére fáyé. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé Wòlíì Francis dágbére fáyé lẹ́ni ọdún méjìdínláàdọ́rùn-ún.
Ìjọ Vatican ló kéde ikú wòlíì Francis láti ẹnu Kevin Farrel pé wòlíì Francis dákẹ́ sí ilé rẹ̀ tó wà ní Casa Santa Marta.
Wọ́n wí pé aago mẹ́jọ ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n gérégé ni wòlíì Francis pajú dé.
Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ni gbogbo ìjọ Àgùdà lágbàáyé fi dárò ẹni tó lọ, wọ́n ṣe àpèjúwe wòlíì Francis bíi ẹni tó fi ara rẹ̀ jìn fún Ọlọ́run títí di àsìkò ikú rẹ̀.
Nípa àìlera wòlíì Francis:
Ọjọ́ méjìdínlógójì ni wòlíì Francis lò nílé ìwòsan Agostino Gemelli níbi tí wọ́n ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó ní àwọn kòkòrò kan ní ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ láti yọ àwọn ibi tí kòkòrò náà ti jẹ kúrò ní Argentina, àti ìgbà náà ni èémí rẹ̀ kò ti bára mu mọ́ tó sì ti wà lẹ́nu rẹ̀ títí di ìgbà tó kú yìí.
Òní yìí kan náà ni olùbádámọ̀ràn okòwò fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta; Olóyè Love Shimite dágbére fáyé. A gbọ́ pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti pàṣẹ kí ìwádìí tó jinlẹ̀ ó wáyé lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú Love Shimite. Ìdí ni pé ọkọ Love Shimite sá tọ àwọn ọlọ́pàá pé ní kété tí ìyàwó òun kú láàárọ̀ yìí ni àwọn ẹbí rẹ̀ ti fi ẹ̀sùn kan òun tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ òun pé òun lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé ọkọ Shimite pamọ́ nítorí bí àwọn ẹbí ìyàwó rẹ̀ ó bá lọ káa mọ́lé.
Àlàye tí a rí gbà lẹ́nu Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ni pé Olóyè Love Shimite dágbére fáyé lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ. Ọkọ rẹ̀ ló gbé e lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí àwọn dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti kú.
Àwọn ẹbí Love Shimite kọ̀ láti gbà pé ọmọ wọn ṣe àìsàn ni, wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀ wọ́n sì lọ fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò ṣe ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí àwọn ẹbí Love Shimite fi kan ọkọ rẹ̀ yìí, àmọ́ ní báyìí, ọkọ rẹ̀ wà ní ọ̀dọ̀ àwọn nítorí kí wọ́n má ba à ṣe é ní ìjàm̀bá.
Ṣé ẹ ríi pé ọjọ́ ǹlá ni òní jẹ́? Aburú ò ní kàn wá o, àṣẹ.
Discussion about this post