Ọjọ́ tí àwọn èèyàn ò le gbàgbé bọ̀rọ̀ ni òní jẹ́ ní Agege látàrí ìjàmbá tó wáyé láàárọ̀ yìí.
Ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí afárá Pen cinema tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ jábọ́ sí ìsàlẹ̀.
Ọkọ̀ akérò kórópe méjì ló já lù mọ́lẹ̀. Awakọ̀ àjàgbé yìí dá lápá méjèèjì nínú ìjàmbá náà.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Èkó; Adebayo Taofiq fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé náà farapa gan-an ni kódà ó dá lápá méjèèjì.
Ó wí pé orí afárá náà ló ti pàdánù ìjánu rẹ̀ léyìí tó mú u jábọ́ sílẹ̀ lu ọkọ̀ méjì.
Ìjàmbá yìí dá súnkẹrẹ-fàkẹrẹ sílẹ̀ àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ojú pópó ṣe àmójútó rẹ̀.
Wọ́n fa awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé náà lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ kí wọ́n tó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Ile-epo.
Adarí ilé iṣé ààbò ojú pópó ti ìpínlẹ̀ Èkó; Olalekan Bakare-Oki ṣe awakọ̀ náà ní pẹ̀lẹ́ ó sì rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe jẹ́jẹ́ lójú pópó.
Nígbà tí a dúpẹ́ pé kò mú ẹ̀mí lọ, ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti àwọn òṣìṣẹ́ Gani Fawehinmi tí wọ́n bèèrè fún pé kí ìjọba ó da ilé ìtura alájà mẹ́rin tó ti ilé náà wó. A gbọ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ agbẹjọ́rò nnì tó tún já fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nígbà ayé rẹ̀; Gani Fawehinmi ti béèrè fún wíwó ilé ìtura alájà mẹ́rin tí wọ́n kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Níbi àpéjọ àwọn oníròyìn tó wáyé nílé náà lónìí ni àwọn agbẹjọ́rò náà rọ ìjọba ti béèrè fún dídá ilé ìtura náà wó.
Ìdí ni pé àwọn ọ̀tá le fara sin sílé ìtura yìí láti pètepèrò ibi sí ilé náà.
Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹtàdínláàdòrùn fún olóògbé ni èyí jáde, wọ́n ní ewu ńlá ni ilé ìtura náà jẹ́ fún ìdílé Fawehinmi.
Ilé tí a ń sọ yìí wà ní agbègbè ìyàsọ́tọ̀ ìjọba ní Ikeja.
Nígbà tí àwọn èyí àti ìjọba ń fà á lọ́wọ́, àjọ EFCC wọ́ Terry Apala lọ sí iwájú ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó ṣe owó ilẹ̀ wa níṣekúṣe.
A gbọ́ pé olórin takasufe nnì; Terry Alexander Ejeh tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ jẹ́ Terry Apala ti dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi lórí ẹ̀sùn pé ó ṣe owó náírà níṣekúṣe.
Adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó fi Terry sí ọgbà ẹwọn Ikoyi títí di ọjọ́ karùn-ún, oṣù Ebibi tí ìgbẹ́jọ́ mìíràn yóó wáyé.
Àjọ EFCC ló wọ́ Terry lọ sí iwájú adájọ́ Akintayo Aluko lórí ẹ̀sùn pé ó tẹ owó náírà mọ́lẹ̀ nígbà tí ó ń jó níbi ayẹyẹ kan tó wáyé ní Oniru, Èkó.
Bí a kò bá gbàgbé, àjọ EFCC ti fìgbà kan gbé Bobrisky lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Terry Apala yìí, ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà ló fi gbára nígbà náà, ẹ jẹ́ á wo ibi tí ti Terry máa yọrí sí.
Kò tán síbẹ̀ o, ìròyìn mìíràn tó tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti bàbá àti ọmọ rẹ̀ tó kú lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èébì.
A gbọ́ pé bàbá kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Light àti ọmọ rẹ̀ Miracle ni wọ́n gbé ẹ̀mí mì lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èébì.
Oríta Ebebe ní Abakaliki tíí ṣe olú ìlú Ebonyi ni ilé Light wà. Àlàyé tí àwọn ará ilé ṣe ni pé àwọn gbọ́ ariwo lọ́gànjọ́ láti igun ilé Light àmọ́ àwọn rò pé ilé ìjọsìn tó ti ilé náà ni ariwo náà ti wá, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n bá òkú Miracle lẹ́nu géétì àbájáde nínú èébì wọ́n sì bá òkú bàbá rẹ̀; Light nínú ilé tí òun náà ti bì kalẹ̀.
Àwọn ará ilé ní májèlé ni àwọn fura sí pé wọ́n jẹ nitori pé ìyàwó Light ti jí kúrò nílé ní àárọ̀ ọjọ́ náà kò sì padà dé.
Inú ọdún yìí ni obìnrin náà kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ọmọ tó ń tọ́ lọ́wọ́ tó sì kó wá sí ilé Light, wọ́n ló jí jáde pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ náà ni ní èyí tí kìí ṣe tẹ́lẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú bàbá àti ọmọ lọ fún àyẹ̀wò láti mọ pàtó irú ikú tó pa wọ́n.
Èyí tí a ó fi kádìí rẹ̀ nílẹ̀ náà ni ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti Kano.
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano tí a mọ̀ sí Hisbah ti lọ wó ibùdó omi ìwòsàn kan tí àwọn èèyàn ń lọ rọ́ mu ní Kano.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde ni a ti rí ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń bu omi mu láti inú ihò àpá ẹsẹ̀ méjì kan tó wà ní ilẹ̀.
Ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn náà ni pé àpá ẹsẹ̀ náà jẹ́ ẹsẹ̀ Ànọ́bì Muhammed, wọ́n sì gbàgbọ́ pé omi náà jẹ́ omi mímọ́ tí yóò ṣe ìwòsàn ati gbígbà àdúrà.
Láti gbogbo orígun Kano ni àwọn èèyàn ti wá mu omi náà, àwọn kan ti ìlú wọn wá mu nínú omi ìwòsàn yìí.
Agbègbè Hotoron Arewa ní Kano ni omi yìí wà, àwọn ọlọ́pàá Hisbah ti lọ sí ibẹ̀ báyìí wọ́n sì ti dí àpá ẹsẹ̀ náà.
Adarí ikọ̀ Hisbah; Dọ́kítà Abba Sufi fi ìdí èyí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé wọ́n ti lọ da ibẹ̀ wó lóòótọ́.
Dọ́kítà Sufi wí pé àwọn kò ní la ojú àwọn sílẹ̀ kí àwọn kan máa fi àdánwò àwọn èèyàn gba owó lọ́wọ́ wọn lábẹ́ ẹ̀sìn. Ó ní àwọn tó gbé omi náà kalẹ̀ fi ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì ni nítorí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ àlàáfíà fún àìlera wọn ni àwọn ṣe dàá wó.
Discussion about this post