Wasiu Akinwande, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri báyìí lórí ẹ̀sùn oníkókó mọ́kànlá.
Adájọ́ Mobolaji Tanimola pàṣẹ kí Olori Esho gẹ́gẹ́ bíi inagijẹ Wasiu ó wà ní àtìmọ́lé fún ọgbọ̀n ọjọ́ gbáko títí àṣẹ yóò fi wá láti òkè lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Wasiu ni ìpànìyàn rẹpẹtẹ, ìpanilára, ìdúnkokò mọ́ni, ìní ìbọn lọ́nà àìtọ́, ìní àwọn ohun ìjà olóró àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn bẹ́ẹ̀.
Láàrin ọdún 2010 sí oṣù Igbe, ọdún 2025 ni Olori Esho àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ ṣẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó.
Àwọn ibi tí wọ́n ti ṣọṣẹ́ náà ni Mushin, Idi Araba, Surulere àti Fadeyi.
Agbègbè Alagbado ni ó sá lọ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ń wá a.
Àwọn èèyàn tí Olori Esho ti yìnbọn pa náà ni Yusuf Bolakale; ẹni ọgbọ̀n ọdún, Yusuf Ramadan; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, Aminat Lateef; ọmọ ọdún mẹ́wàá, Anyila àti Ojajo tí a kò mọ àpèjá àti ọjọ́ orí wọn pẹ̀lú àwọn mẹ́rin mìíràn láàrin ọdún 2010 sí ọdún yìí.
Bákan náà ni ìjọba fi ẹ̀sùn ìjẹ́-ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan Olori Esho nínú èyí tó ti sẹkú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn.
Wasiu Akinwande ti wà ní kirikiri báyìí títí di ìgbà tí ìjọba yóò pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
ILÉ ITURA WÓ PA OLÓWÓ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ EDO.
Ilé ìtura kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní agbègbè Idumoza ní ìpínlẹ̀ Edo ti dà wó lọ́jọ́ Ẹtì. Ẹni tó ni ilé ìtura náà; Andrew Isesere wà níbẹ̀ lásìkò tó dàwó ó sì kú sínú rẹ̀.
Àwọn òṣìṣẹ́ bíi ogún ni wọ́n rápálá jáde àmọ́ Andrew há sínú ilé náà, ọjọ́ Àìkú ni wọ́n tó rí òkú rẹ̀ yọ.
Àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣe àlàyé pé àwọn irinṣẹ́ tí Andrew rà fún ilé náà kò kún ojú òṣùwọ̀n, wọ́n ní kò gba akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ alámòójútó pé òun ló ń mójútó ilé ìtura náà fúnra rẹ̀.
Ilé ìtura náà ti dà wó báyìí ó sì ti pa olówó rẹ̀.
ỌMỌ TITUN SỌNÙ NÍ ILÉ ÌWÒSÀN ÌJỌBA ÈKÌTÌ.
Ọmọ titun jòjòló tí ìyá rẹ̀ bí ní alẹ́ àná ọjọ́ Àìkú ti sọnù ní òwúrọ̀ yìí ọjọ́ Ajé.
Ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Ado Ekiti ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀.
Nọ́ọ̀sì tó wọ iṣẹ́ ní àárọ̀ yìí ṣe àlàyé pé òun kò bá ọmọ náà, nọ́ọ̀sì tó ṣiṣẹ́ lálẹ́ àná ní òun gbé ọmọ kalẹ̀.
Àwọn afurasí mẹ́rin ni àwọn ọlọ́pàá ti mú báyìí.
OMI TI GBA IJEDE IKORODU, ÀWỌN ARÁ ÌLÚ KÉ SÍ ÌJỌBA.
Àwọn ará agbègbè Ijede Ikorodu ti ké sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó láti wá gbà wọ́n kalẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé yìí o.
Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tọ́ bẹ̀rẹ̀ láti àná ti fa omiyalé ní gbogbo àgbègbè náà.
Aṣọ tí àwọn èèyàn náà wọ̀ sọ́rùn nìkan ni ohun ìní wọn tí wọ́n le fi ọwọ́ sọ̀yà rẹ̀ báyìí nítorí pé omi náà wọ inú yàrá ẹnikọ̀ọ̀kan.
Àwọn ilé tó jẹ́ alájà méjì nìkan ni àwọn èèyàn rí òkè rẹ̀ sá sí, gbogbo ilé ìsàlẹ̀ lomi ti bo òrùlé wọn mọ́lẹ̀.
Ìjọba Èkó ti fèsì sí èyí, ó rọ àwọn èèyàn náà láti ṣe pẹ̀lẹ́ pé àwọn ń bọ̀ wá kó wọn jáde.

SALAWU PA WAHAB, Ó TÚN KUN ÚN WẸ́LẸ́WẸ́LẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.
Bàbá ọmọdékùnrin kan tí Salawu Omikansola pa nípakúpa ti ṣe àlàyé ikú tó pa ọmọ náà.
Olumide Lawal ni orúkọ bàbá Wahab, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni Wahab lásìkò ikú rẹ̀.
Agbègbè Igbile Ijebu ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
Lọ́jọ́ kọkànlélógún, oṣù Agẹmọ ni Wahab sọnù tí kò wá sílé, nígbà tó di ọjọ́ kẹta, wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ títì tí ẹ̀yà ara rẹ̀ kò sì pé mọ́.
Wọ́n ti gé orí àti ọrùnwọ́ rẹ̀ wọ́n sì ti yọ ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.
Bàbá Wahab ṣe àlàyé pé Igbile Ijebu ni ìyá ọmọ náà ń gbé nígbà tí òun ń gbé ní Ijebu Ode.
Lọ́jọ́ náà, ìyá Wahab pe bàbá rẹ̀ pé ṣé Wahab wá sí ọ̀dọ rẹ̀ ni nítorí pé wọn kò ríi.
Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń wá a kiri gbogbo Igbile Ijebu àti Ijebu Ode.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta ni àwọn ará àdúgbò wá pe baba Wahab nílé pé wọ́n rí òkú kan lọ́nà oko pẹ̀lú irú asọ Wahab.
Olumide ní òun kò gbàgbọ́ àmọ́ òun tẹ̀lé wọn dé ibẹ̀. Wọ́n bá òkú Wahab nílẹ̀, aṣọ àti bàtà ni wọ́n fi dá a mọ̀ nítorí pé wọ́n ti gé orí rẹ̀, ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lọ.
Àwọn ọdẹ àdúgbò ló júwe Salawu Oyinkansola fún wọn pé àwọn pàdé rẹ̀ lóru ọjọ́ tí ọmọ náà sọnù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ lára aṣọ rẹ̀.
Salawu sọ fún àwọn ọdẹ pé òun lọ bá àwọn èèyàn kan pa ajá fún Ògún ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ta sí òun láṣọ, ni wọ́n bá fi sílẹ̀.
Ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú Salawu Oyinkansola, òun ló dárúkọ Serefusi Agemo.
Salawu ṣe àlàyé pé Serefusi ló ní kí òun ó pa ọmọ náà kí òun ó sì yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀. Ó ní ẹ̀rù ba òun àmọ́ Serefusi ló ki òun láyà.
Serefusi Agemo ni olórí àwọn Alágẹmọ agbègbè náà. Kò sọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn tí Salawu fi kàn án àmọ́ ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Baba Wahab; Olumide Lawal rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ rẹ̀. Ó wí pé òun gbọ́ pé Serefusi ní igi lẹ́yìn ọgbà tó sì máa ń mú ẹ̀sùn jẹ àti pé àwọn kan ti ń dúnkokò mọ́ òun láti pa ẹjọ́ náà tì.