Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí ìyá ọmọbìnrin ọmọ oṣù mẹ́jọ́ fi kan ọ̀gá ilé ìwé tí ó ti ń ṣiṣẹ́.
Gloria Umukoro ni orúkọ obìnrin yìí, ó jẹ́ olùkọ́ ó sì ń tọ́ ọmọbìnrin ọmọ oṣù mẹ́jọ lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù yìí, àwọn ọmọ ti jáde iléèwé àmọ́ Gloria dúró láti parí àwọn ìbéèrè ìdánwò. Ó fi ọmọ rẹ̀ ṣọ́ ọ̀gá ilé ìwé àmọ́ olùdásílẹ̀ ilé ìwé náà; Ọ̀gbẹ́ni Korede Afuye wá gbé ọmọ náà tó sì gbé e ọ, lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni ó dá ọmọ náà padà fún ọ̀gá iléèwé.
Gloria ṣe àlàyé pé ojú òun ni Ọ̀gbẹ́ni Afuye ti dá ọmọ náà padà tí ọ̀gá sì tẹ́ ọmọ náà sílẹ̀ tó sì jáde. Ìyá ọmọ ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ lọ àmọ́ ó ríi pé ara ọmọ náà kò lélẹ̀ àmọ́ kò kọbi ara síi. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí ó ríi pé ọmọ náà kò fi ara lélẹ̀ ni ó lọ yẹ̀ ẹ́ wò.
Ìlédí tí ó wà nídìí rẹ̀ kò jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ó ṣàn síta àmọ́ ipa ẹjẹ tí ìyá rẹ̀ rí ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fi tú ìlédí ìdí rẹ̀, gbogbo abẹ́ ọmọ náà kún fún ẹ̀jẹ̀ láti ojú ara rẹ̀ pẹ̀lú ojú egbò, ó jọ pé wọ́n bá ọmọ náà lò pọ̀.
Àlàyé Gloria tẹ̀síwájú pé òun lọ ya bá olùdásílẹ̀ tó gbé ọmọ náà lọ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú pé kín ni ó fi ṣe ọmó? Èsì tí Afuye fọ̀ ni pé kí ó ṣe sùúrù kí àwọn ó yanjú rẹ̀ ní tùbí-ǹ-nùbí.
Gloria ní òun gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn tí àwọn dọ́kítà sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n bá ọmọ náà lò pọ̀ ni, inú ìnira ni ọmọ náà wà báyìí. Lẹ́yìn tí ó gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn ni ó lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Afuye tún padà sọ fún Gloria pé ṣebí òun ní kó má lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kí àwọn ṣe é ní òkú òru.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti gba ìfisùn náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.
Ó ti pẹ́ tí a ti ń mú ìròyìn nípa ìfipábánilò wá àmọ́ èyí yàtọ̀, ọmọ oṣù mẹ́jọ!
Lára àwọn èyí tó ti ṣẹ̀ sẹ́yìn ni:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ti tẹ bàbá kan ẹni àádọ́ta ọdún tó fi ipá gba ìbálé ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé ìyá ọmọ yìí ló fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Iléṣà nígbà tó rí ikun funfun nínú pátá ọmọ rẹ̀ náà.
Ọmọ náà jẹ́wọ́ pé bàbá náà tó jẹ́ alábàágbé wọn ló fipá bá òun lájọṣepọ̀. Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ìjákújàá ni bàbá yìí já ìbálé ọmọ náà, gbagada ló fa abógundé rẹ̀ ya.
Ọmọ yìí ṣe àlàyé pé láti inú oṣù Agẹmọ ni bàbá yìí ti ń bá òun lájọṣpọ̀ tí yóò sì fún un ní igba náírà kó fi ra oúnjẹ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ibrahim Gotan korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó rọ àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.
Ṣebí ìyẹn tilẹ̀ pé ọdún méjìlá, ọmọ ọdún mẹrin ní Ibadan ńkọ́?
Aṣọ́gbà ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan tó wà ní Ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin tó jẹ́ ọmọ ilé ìwé náà lò.
Josiah Ayomide ni orúkọ aṣọ́gbà yìí, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni pẹ̀lú.
Ìròyìn fi yé wa pé lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ògún ni Josiah ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ tó sì fipá já ìbálé rẹ̀.
Ọmọ yìí sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé ojú ara ń dun òun, nígbà tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ nínú ló ṣe àlàyé pé aṣọ́gbà ilé ìwé bọ́ pátá òun lọ́jọ́ kan tó sì ki nǹkan bọ̀ ìdí rẹ̀.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn Eleyele fi hàn pé ìbálé ọmọ náà ti já, ojú ara rẹ̀ sì tún dégbò.
Josiah náà kò jiyàn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá, ó jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni òun fipá bá ọmọ náà lò.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Josiah yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Adewale Osifeso; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Bàbá ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanuel George ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi ipá gba ìbálé ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé nínú keke maruwa tí bàbá yìí ń wà ni ó ti já ìbálé ọmọ náà.
Ọjọ́ kẹfà, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ ọdún 2025 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní agbègbè Mini Orlu ní Portharcourt tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.
Ọmọbìnrin yìí ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wá lo ìsinmi lọ́dọ̀ rẹ̀ rán níṣẹ́ nígbà tí Emmanuel fi ipá wọ́ ọ sínú keke rẹ̀, ó fi aṣọ díi lẹ́nu ó tún so ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kó tó fi ipá já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sálọ.
Ọmọ yìí délé ròyìn fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ìtọpinpin awọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ gbé Emmanuel níbi tó lọ farasin sí, kò tilẹ̀ jiyàn, pẹ̀lú sùúrù ló fi jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọ náà lò lóòótọ́.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn òbí ati alagbato láti mójútó àwọn ọmọ wọn daadaa.
Ǹjẹ́ ọ̀ràn ni láti jẹ́ ọmọbìnrin bí? Ọ̀rọ̀ yìí ń fẹ́ àmójútó gidi.




