Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni Kọmíṣánnà fùn ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínẹ̀ Èkó, Alàgbà JAMIU ALLI-BALOGUN ní ó di èèwọ̀ fún gbogbo olùkọ́ yálà ní ilé ìwé ìjọba tàbí aládàáni láti máa yọ ẹgba kiri, olùkọ́ kò sì gbọdọ̀ lo ẹgba, olùkọ́ tí ó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn yìí jó fi aṣọ pénpé ro oko ọba tàbí san owó ìtanràn. Kọmíṣánnà ní kàkà kí olùkọ́ máa lo ẹgba, ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àwọn eléèbó mọ̀ sí COUSELING ni kí wọ́n máa ṣe fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ọ̀rọ̀ lọmọ elétí n jẹ. Kọ́míṣánnà ní kí àwọn olùkọ́ máa fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ràn lóòrè-kóòrè, fún ìdí èyí, ẹgba lílò ní ilé ìwé wa ní ìpínlẹ̀ Èkó ti di òfin báyìí nítorí ìlú tí kò sí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀. Èèwọ̀ ni láti máa na Akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́gba, a kò faramọ́ ṣíṣe Akẹ́kọ̀ọ́ léṣe, àpá kò sì gbọdọ̀ sí lára ọmọ dípò lílo ẹgba ní ilé ìwé, olùkọ́ le è ní kí wọ́n kúnlẹ̀-káwó sókè-dijú tàbí tún ìyàrá ìkàwé wọn ṣe nípa ṣíṣa ilẹ̀ àyíká.
Lọ́dún 2022, àbádòfin jíjínà sí ẹgba lílò nílé ìwé yìí gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò ní ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ ètò ẹ̀tọ́ ọmọdé láti le è gbógun ti lílo ọmọdé nílòkulò. Kọmíṣánnà JAMIU ALLI-BALOGUN ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni kí ìbáwí jẹ́ fún ọmọdé àgàgà àwọn ògo wẹẹrẹ, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò sọ wí pé kí a máa wo ọmọdé níran, bí wọ́n bá hù ìwà tí kò dára àmọ́ ìbáwí kò gbọdọ̀ pọ̀jù, díẹ̀-díẹ̀ ló gbọ́dọ̀ jẹ́ nítorí Yorùbá wọ́n ní ‘ọwọ́ kótópó la fi n bá ọmọdé wí’. Kọmíṣánnà JAMIU ALLI-BALOGUN ní a mọ̀ dájú gbangba-gbàngbà pé yóò tó bí ọdún márùn ún kí òfin tó gbilẹ̀ káàkiri ilé ìwé ní ìpínlẹ̀ Èkó síbẹ̀, ohun tí a fẹ́ nìyí, ó sì ti di òfin. ọ́míṣánnà ALLI-BALOGUN ní ìdí nìyí tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe n gba àwọn olùkó tó kájú òṣùwọ̀n, àwọn olùkọ́ fọ́nyánmu-kẹ́rù-ó-b’ẹ̀kọ, àwọn olùkọ́ tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́, àwọn tó kọ́ṣẹ́ ìkọ́ni yanjú tí wọ́n sì jẹ́ olùkọ́ aláfọkànsìn. Lótòótọ́, àwọn olùkọ́ mìíràn kò rí bákan náà, wọ́n le è ṣe ọmọ léṣe pẹ̀lú ìbínú. Ìjìyà nlá bí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà àti owó ìtanràn ní ẹnikẹ́ni tí adé ìwà yìí bá ṣímọ́ lórí.
Awuyewuye ni àbádòfin yìí dá sílẹ̀ gbáà! Ọ̀kan lára awuyewuye yìí ni ti ọ̀gá àgbà fún àjọ INTERNATIONAL TRAINING RESEARCH AND ADVOCACY PROJECT ( INTRAP) DR. MACPHELELANE EJAH ti fi ẹ̀họ́nnú rẹ̀ hàn lórí àbádòfin ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lórí dídènà ìbáwí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ìwé ìpínlẹ̀ Èkó yálà ti ìjọba tàbí ti Aládàáni ní ìpínlẹ̀ Èkó láti ọjọ́ rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá lọ́hùn ún.JAMIU ALLI-BALOGUN ní ó di èèwọ̀ fún gbogbo olùkọ́ yálà ní ilé ìwé ìjọba tàbí aládàáni láti máa yọ ẹgba kiri, olùkọ́ kò sì gbọdọ̀ lo ẹgba, olùkọ́ tí ó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn yìí jó fi aṣọ pénpé ro oko ọba tàbí san owó ìtanràn. Kọmíṣánnà ní kàkà kí olùkọ́ máa lo ẹgba, ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àwọn eléèbó mọ̀ sí COUSELING ni kí wọ́n máa ṣe fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ọ̀rọ̀ lọmọ elétí n jẹ. Kọ́míṣánnà ní kí àwọn olùkọ́ máa fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ràn lóòrè-kóòrè, fún ìdí èyí, ẹgba lílò ní ilé ìwé wa ní ìpínlẹ̀ Èkó ti di òfin báyìí nítorí ìlú tí kò sí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀. Èèwọ̀ ni láti máa na Akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́gba, a kò faramọ́ ṣíṣe Akẹ́kọ̀ọ́ léṣe, àpá kò sì gbọdọ̀ sí lára ọmọ dípò lílo ẹgba ní ilé ìwé, olùkọ́ le è ní kí wọ́n kúnlẹ̀-káwó sókè-dijú tàbí tún ìyàrá ìkàwé wọn ṣe nípa ṣíṣa ilẹ̀ àyíká.
Lọ́dún 2022, àbádòfin jíjínà sí ẹgba lílò nílé ìwé yìí gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò ní ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ ètò ẹ̀tọ́ ọmọdé láti le è gbógun ti lílo ọmọdé nílòkulò. Kọmíṣánnà JAMIU ALLI-BALOGUN ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni kí ìbáwí jẹ́ fún ọmọdé àgàgà àwọn ògo wẹẹrẹ, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò sọ wí pé kí a máa wo ọmọdé níran, bí wọ́n bá hù ìwà tí kò dára àmọ́ ìbáwí kò gbọdọ̀ pọ̀jù, díẹ̀-díẹ̀ ló gbọ́dọ̀ jẹ́ nítorí Yorùbá wọ́n ní ‘ọwọ́ kótópó la fi n bá ọmọdé wí’. Kọmíṣánnà JAMIU ALLI-BALOGUN ní a mọ̀ dájú gbangba-gbàngbà pé yóò tó bí ọdún márùn ún kí òfin tó gbilẹ̀ káàkiri ilé ìwé ní ìpínlẹ̀ Èkó síbẹ̀, ohun tí a fẹ́ nìyí, ó sì ti di òfin. ọ́míṣánnà ALLI-BALOGUN ní ìdí nìyí tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe n gba àwọn olùkó tó kájú òṣùwọ̀n, àwọn olùkọ́ fọ́nyánmu-kẹ́rù-ó-b’ẹ̀kọ, àwọn olùkọ́ tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́, àwọn tó kọ́ṣẹ́ ìkọ́ni yanjú tí wọ́n sì jẹ́ olùkọ́ aláfọkànsìn. Lótòótọ́, àwọn olùkọ́ mìíràn kò rí bákan náà, wọ́n le è ṣe ọmọ léṣe pẹ̀lú ìbínú. Ìjìyà nlá bí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà àti owó ìtanràn ní ẹnikẹ́ni tí adé ìwà yìí bá ṣímọ́ lórí.
EJAH MACPHELANE ní kìí ṣe àṣà àti ìṣe ọmọ adúláwọ̀, níṣe là n kọ́ àṣà àtọ̀húnrìnwá fi bo àṣà wa mọ́lẹ̀, a ti gbé àṣà àtọ̀húnrìnwá gorí àṣà ti wa eléyìí sì tàbùkù bá ilẹ̀ Nàìjíríà púpọ̀-púpọ̀ jù. EJAH MACPHELANE ní àbájáde òfin yìí kò le è fi ara rọ, ipa búburú ni yóò jẹ́ fún àwọn ọmọ wa. Alàgbà EJAH MACPHELANE sọ pé :
Nínú ilé pàápàá, òbí n bá ọmọdé wí, ẹgba kìí pa ọmọ, ó n mú ọmọdé gbọ́n ni. Kò burú, kò sì bàjẹ́ bí a bá n lo ẹgba ní ilé ìwé náà. Àṣà àti ìṣe wa ni ìbáwí, ẹ̀sìn àti ìwòye ẹ̀dá pàápàá kò lòdì sí ìbáwí. Kò gbọdọ̀ di ìgbà yìí, kí a ní kò jọọ́, kò ṣe é ṣe tàbí kò sí ohun tó n jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí a wá ti ìdayìí gùnlé òfin kan tí kò ní oore nínú, ká kọ ẹgba nínà sílẹ̀ láì sí gbé ìgbésẹ̀ Akin láti mọ ìdí àti ìtumọ̀ ọ̀nà tí wọ́ wá. EJAH MACPHELANE n tẹpele mọ́ ọ́n pé èyí kìí ṣe àṣà àti ẹ̀sìn ilẹ̀ Nàìjíríà rárá, àṣà àjòjì àti àtọ̀húnrìnwá ni èyí.
EJAH MACPHELANE ní kò yẹ ká kọ ìbáwí pátápátá ní ilé ìwé ìpínlẹ̀ Èkó, nnkan tó yẹ ní ṣíṣe ni kí òfin dé bí a tilè lo ẹgba, ìyẹn ni pé kò gbọdọ̀ sí ìbáwí tí yóò mú àpá wá sára ọmọ tàbí kí ó la ẹ̀mí lọ.Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó gbọdọ̀ rí i pé àwọn olùkọ́ tó dángájíá ní wọ́n gbà sẹ́nu iṣẹ́. EJAH MACPHELANE ní ohun tó dàra ni láti máa gba ọmọdé ní ìmọ̀ràn bí wọ́n bá ṣe nnkan tí kò dára ṣùgbọ́n èyí kò le è ṣe iṣẹ́ tí ẹgba yóò ṣe nínú ayé ọmọ tó ní ìpánlè. EJAH tún tẹ̀síwájú pé : bí i kání ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò mọ láabi tí òfin yìí yóò dá sílẹ̀ lọ́jọ́ iwàjú? Ní gbogbo ilé ìwé ilẹ̀ Nàìjíríà, ìgbaniníyànjú máa n wáyé fún Akẹ́kọ̀ọ́ lóòrè-kóòrè lórí bí Akẹ́kọ̀ọ́ yóò ti yan iṣẹ́ tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájúú , kìí ṣe láti tọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ sọ́nà ìwà àìtọ́ rẹ̀. Ìgbnaniníyànjú àti ẹgba nínà ló jọ n ṣiṣẹ́ papọ̀ mọ́ra wọn nítorí bí ọ̀kan kò bá sí, èkejì kò le è ṣe.
Bí olùkọ́ bà tilẹ̀ n mú ẹgba kiri inú ọgbà ilé ìwé, wọn kìí lò ó lọ́pọ̀ ìgbà ṣùgbọ́n ìtọ́kasí ni fún Akẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ kí orí Akẹ́kọ̀ọ́ pé, kí wọ́n ṣì ṣọ́ra ṣe.
Ọ̀jọ̀gbọ́n AYODEJI OWOLABI ti ifáfitì CALABAR náà ṣe àfikún ọ̀rọ̀ EJAH MACPHELANE pé : Bí kò bá sí ìbáwí tó múnádóko nílé ìwé, àwọn ọmọ wa yóò di arúfin lọ́jọ́ iwájú, ìwọ̀ntún-wọ̀nsì ni kí gbogbo rẹ̀ jẹ́, kò gbọdọ̀ la ẹ̀mí lọ tàbí ṣe Akẹ́kọ̀ọ́ ní ìjàmbá. Ọ̀jọ́gbọ́n AYODJI ní ‘Mi ò lòdì sí àmọ̀ràn Akẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo ilé ìwé, síbẹ̀, lílo ẹgba gbọ́dọ̀ wá.