Àwọn olùkọ́ ilé ìwé ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ni ilé ẹjọ́ gíga ti fi téèbù wọn ẹ̀wọ̀n fún bíi ẹni wọn gààrí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fipá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lò pọ̀. Ohun tó so okùn ọ̀ràn yìí mọ́ wọn lọ́run daindain ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ọmọdé lábẹ́ òfin nítorí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlọgún.
Àwọn olùkọ́ náà ni: Gbenga Ajibola; ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti Ayodele Olaofe: ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta. Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́ta ni wọ́n fi kan àwọn olùkọ́ méjì yìí, ìfipábánilò ni olúborí àwọn ẹ̀sùn náà. Àwọn olùkọ́ náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ẹni máa parọ́ lá ní ẹlẹ́rìí òun wà lọ́run, àwọn ọmọbìnrin yìí jẹ́rìí níwajú adájọ́ Adeniyi Familoni ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti. Ọ̀kan nínú wọn ṣe àlàyé pé ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ni ọ̀gbéni Ajibola ń kọ́ òun nílé ìwé náà, ó ní lọ́jọ́ náà, ọ̀gbéni Ajibola wí pé kí òun ó wọ aṣọ ilé wá ó sì fún òun ní igba náírà pé kí òun ó lọ dúró de òun ní iwájú ilé epo kan ní òpópòná ilé ìfowópamọ́ kan ní Ado-Ekiti.
Ọmọ yìí wí pé nígbà tí òun dé ibẹ̀, ọmọ kíláàsì òun kan náà dé bá òun níbẹ̀ ó sì wí pé ọ̀gbẹ́ni Olaofe ló ní kí òun ó wá dúró de òun níbẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn olùkọ́ méjéèjì yìí dé wọ́n sì kó wọn lọ sí ilé ìtura kan tó wà ní Oke-Ila, Ado-Ekiti. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n mú àwọn ọmọ náà lọ́kọ́ọ̀kan lọ sí yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n sì fi okó ba abẹ́ wọn jẹ́.
Ọmọ yìí wí pé láti ìgbà náà ni ọ̀gbẹ́ni Ajibola ti ń da òun láàmú pé kí àwọn ó tún lọ ṣe síi, nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ ló sọ fún ìyá rẹ̀ tí àwọn ìyá méjéèjì sì fi tó àwọn agbófinró létí.
Agbẹ̀jọ́rò àwọn olùkọ́ yìí gbìyànjú tirẹ̀, àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́fà ló kó wá sílé ẹjọ́ tí wọ́n wá tako ẹ̀sùn náà, ó wí pé àwọn ọ̀tá àwọn olùkọ́ yìí ló fi ìtàn náà sí àwọn ọmọ náà lẹ́nu pé irọ́ ni wọ́n ń pa.
Adájọ́ Adeniyi ṣe àyèwò àwọn ẹ̀rí àwọn ọmọ náà láti orí ìwé àyẹwò dọ́kítà nílé ìwòsàn tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọ náà gba kùmọ̀ sára tó fi dé orí ìwé ìforúkọsílẹ̀ ilé ìtura náà, Adájọ́ wí pé àwọn olùkọ́ yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún ló wọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ìdí nip é àwọn ọmọ náà jẹ́ màjèsín, ẹ̀kejì ni pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni àwọn olùkọ́ yìí àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà lábẹ́ òfin kí àwọn yóòkù ó le fi tiwọn kọ́gbọ́n.
*** *** ***** ***** **** *** ***** ***** ***** **** ***** **** ***** ***** ***** ****
Ọ̀rọ̀ àwọn afípábá-ọmọdé-lò yìí ń fẹ́ àmójútó tó nípọn. Káàkiri orílẹ̀-èdè yìí ni ìròyìn ti ń gbé e pé wọ́n fipá bá ọmọdé lò. Ìwé ìròyìn yorùbá kọ nípa ìfipábánilò kan tó wáyé ní ọdún tó kọjá nìgbà tí Ezekiel fi ipá bá àkàndá kan lájọṣepọ̀ pe:
Ezekiel Elijah; ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá tó ní ìpèníjà ara ni Ezekiel tàn wọ inú ilé rẹ̀ tó sì fipá bá a lájọṣepọ̀.
Agbègbè Aviara ní Isoko ìpínlẹ̀ Delta ni èyí ti ṣẹ̀. Àlàyé tí Ezekiel ṣe fún àwọn ọlọ́pàá ni pé òun kò mọ ọjọ́ orí ọmọ náà rárá òun kò mọ̀ pé kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe wí pé àwíjàre Ezekiel kò múná dóko. Yálà ọmọ náà gbà láti ní àjọṣepọ̀ tàbí kò gbà, ohun tó kan òfin ni pé ọjọ́ orí ọmọ náà kéré lábẹ́ òfin láti dá ìpinu ṣe.
Bright ṣàlàyé pé ìfipábánilò pàápàá ìbálòpọ̀ ọmọdé kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kékeré lábẹ́ òfin, fún ìdí èyí, Ezekiel yóò fojú ba ilé-ẹjọ́.
A kọ ìròyìn kan náà nígbà kan lórí ìfipábánilò yìí pé:
Akeem Sumonu, ẹni ogún ọdún ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Agbègbè Olodo ní ìjọba ìbílẹ̀ Odeda, ìpínlẹ̀ Ogun ni èyí ti ṣẹ̀.
Àárọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọdún kérésì ku ọ̀la ni àwọn ọlọ́pàá lọ gbé Akeem nílé rẹ̀.
Inú oṣù Ọ̀wàrà ni Akeem fi ipá bá ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò tó sì tún ṣẹ̀rù bà á pé kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.
Ọmọ yìí kò wí lóòótọ́, ìyá rẹ̀ ló kíyèsí pé ọmọ náà ń yí padà, ó pè é ó sì tẹ̀ ẹ́ nínú dáadáa, ọmọ yìí jẹ́wọ́ pé bùọ̀dá Akeem ló fi ipá bá òun lò.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé wọ́n fi ipá gba ìbálé ọmọ náà ni, pabambarì ni pé ọmọ yìí ti fẹ́rakù látàrí ìbálòpọ̀ tìpátìkúùkù yìí.
Christiana; ẹni tó jẹ́ ìyá ọmọdébìnrin yìí ló fi ọlọ́pàá gbé Akeem, pàkò bí ẹni ọkọ̀ já sílẹ̀ ni ó ń wò, ó jẹ́wọ́ pé òun hu ìwà náà lóòótọ́.
Tọ̀, inú agódo àwọn ọlọ́pàá ni Akeem ti ké HAPPY NEW YEAR ọdún 2025 tirẹ̀.
Mélòó la ó kọ nípa ìfipábánilò tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́? Bí a ṣe ń kọ ìròyìn yìí lọ́wọ́ ni ìròyìn kan tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ pé àwọn méjì kan ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́páà fún ifipábánilò yìí kan náà. Ìpínlẹ̀ Yobe ni èyí ti ṣẹlẹ̀ báyìí, ọmọdébìnrin kan ni àwọn ọkùnrin méjéèjì kì mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe é báṣubàṣu. Ọmọ yìí ti balẹ̀ sílé ìwòsàn báyìí nítorí ipá ni wọ́n fi gba ìbálé rẹ̀
Àsìkò ti tó fún ìjọba láti gbé ìjìyà tó le dain kalẹ̀ fún ìwà ìfipábánilò yìí kí wọ́n má sọ gbogbo ọmọ di apẹ̀rẹ̀ àjàṣẹ́ kalẹ̀ tán.