ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Tó Gbòde

OBÌNRIN KAN RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ PÉ KÍ WỌ́N BÁ ÒUN WÁ IṢẸ́.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
January 11, 2026
in Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
7
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Fọ́nrán kan ti jáde tó sì ń jà ràìnràin lórí ìtàkùn ayélujára báyìí. Obìnrin kan ló fi fọ́nrán náà léde, nínú rẹ̀ ló ti ń wa ẹkún mu tó sì ń bẹ̀bẹ̀ pé òun fẹ́ iṣẹ́ tí òun yóò máa ṣe, ó rọ àwọn èèyàn láti pín fọ́nrán náà káàkiri kí ó le délé dóko.
Obìnrin yìí ṣe àlàyé pé kò rọrùn fún òun láti ṣe fọ́nrán náà àmọ́ òun ti sún kàngiri, ó ní òun kò mọ ohun tó le ṣẹlẹ̀ bí òun kò bá rí iṣẹ́ tí òun yóò fi máa rí owó ní kíákíá.
Wàyí o, obìnrin yìí là á pé iṣẹ́ tó bá òfin mu ni òun fẹ́ ṣe òun kò fẹ́ èyí tó lòdì sí òfin.
Àwọn èèyàn ti ń ṣe àtagbà fọ́nrán náà, àwọn kan kọ ọ́ sínú àríwísí pé kìí ṣe òun nìkan ló wà nípò yìí, àwọn mìíràn gan-an kọ ọ́ pé àwọn náà ń fẹ́ iṣẹ́ wọ́n sì fi ìwé ẹ̀rí wọn gbá a nídìí.
Oríṣìí ìhà ni àwọn èèyàn ti kọ sí fọ́nrán tí obìnrin yìí fi léde, wọ́n ní àìríṣẹ́ṣe kìí ṣe titun mọ́ nílẹ̀ yìí pàápàá láàrín àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.

Ọ̀DỌ́KÙNRIN KAN KÚ SÍNÚ ODÒ ÌWẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.

Ọ̀dọ́kùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ti kú sínú odò ìwẹ̀ ní ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Babaseyi Oluwaseyi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi àtẹ̀jáde kan sí ojú òpó X rẹ̀ pé ògo mìíràn tún wọ̀ọ̀kùn sínú odò ìwẹ̀. Babaseyi rọ àwọn onílé ìgbafẹ́ àti ilé ìtura láti ríi dájú pé odò ìwẹ̀ wọn kò léwu fún àwọn èèyàn.
Ó wí pé ó yẹ kí àwọn onílé ìgbafẹ̀ ó ní awẹdò níkàlẹ̀ tí yóò má dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn tí wọ́n bá fẹ́ rì, èyí yóò dẹ́kun bí àwọn èèyàn pàápàá àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń kú sínú odò ìwẹ̀.

ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌ KÚ SÍNÚ KÀNǸGA NÍ ÌPÍNLẸ̀ KANO.

Ọmọ ọdún méjì kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Sa’idu Ahmad ti kú sínú kànǹga ní ìlú Kwankwanso, ìpínlẹ̀ Kano.
A gbọ́ pé àwọn òbí rẹ̀ ló pe ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ náà ní Ọjọ́bọ pé ọmọ náà kó sínú kànǹga. Wọ́n yọ ọ́ jáde àmọ́ kò wà dáadáa nígbà tí wọn yóò sì fi ṣe aájò rẹ̀, ẹ̀pa kò bá oró mọ́. Ìwádìí ṣì ń lọ lórí bí ọmọ náà ṣe kó sínú kànǹga àti ẹni tó ṣí kànǹga náà sílẹ̀.

ÀWỌN AGBÉBỌN ṢE ÌKỌLÙ SÍ IBÙDÓKỌ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́.
Àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù sí ibùdókọ̀ tó wà ní Oloka ní ìjọba ìbílẹ̀ Orire, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn agbébọn náà kó wọ́n ní pápá mọ́ra, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, àwọn èèyàn mẹ́rin ni wọ́n rán lọ́run àṣàǹte nígbà tí èèyàn kan wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run nílé ìwòsàn báyìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Ayanlade Olayinka. Ó ṣe àlàyé pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Femi Haruna àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò mìíràn ti ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Femi Haruna ti pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ó yí agbègbè náà ká, ìdí ni láti dẹ́kun irú ìkọlù báyìí àti láti dá àlàáfíà padà sí agbègbè náà.

ADVERTISEMENT

IBÀ LASSA TÚN SẸ́LẸ̀RÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ NASARAWA.

ADVERTISEMENT

Kò dín ní àwọn èèyàn mẹ́rin tí wọ́n ti kú ní ìpínlẹ̀ Nasarawa pẹ̀lú àwọn àmì tó jọ ti ibà Lassa.
A gbọ́ pé ìjọba ti ti ilé ìwòsàn Awe wọ́n sì ti fi àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sí yàrá ìyàsọ́tọ̀ láti mọ̀ bí wọ́n bá ti kó ààrùn náà.
Ìdí ni pé ilé ìwòsàn náà ni àwọn ará àdúgbò gbé obìnrin kan lọ tó sì kú lẹ́yìn wákàtí díẹ̀. Àwọn àmì tí obìnrin yìí fi hàn fi ara pẹ́ ti ibà Lassa, èyí wọ́n ń gbìyànjú àti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ tí ọkọ rẹ̀ náà fi kú lọ́jọ́ kẹta pẹ̀lú àmì kan náà.
Adarí ẹ̀ka àjàkálẹ̀ ààrùn ní ìpínlẹ̀ náà; Ahmad Abdullahi bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà pé wọ́n fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ náà ni ó ṣe ń tàn báyìí.
Abdullahi wí pé àwọn fi ọkọ̀ ránṣẹ́ sí Awe láti kó àwọn mẹ́fà wá sí Lafia kí wọn ó fi wọ́n sí yàrá ìyàsọ́tọ̀ àmọ́ wọ́n sá lọ mọ́ wọn lọ́wọ́, èyí yóò mú kí ààrùn náà ó tàn kálẹ̀ báyìí.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà; Dọ́kítà Peter Awe ṣe àlàyé pé èsì àyèwò obìnrin tó kú náà fi hàn pé ó ní ààrùn ibà Lassa, yàtọ̀ sí ọkọ rẹ̀, àwọn méjì mìíràn ló tún kú tí àyẹ̀wò wọn sì fi hàn pé wọ́n ní ààrùn náà lára.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti wà ní Awe báyìí láti máa mú gbogbo ẹni tó bá fi àmì ààrùn náa hàn lọ sí yàrá ìyàsọ́tọ̀, àwọn mẹ́fà tí wọ́n sá lọ náà ni ó ń ba ìjọba lẹ́rù báyìí.

ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ YÌNBỌN PA OBÌNRIN KAN.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti yìnbọn pa obìnrin kan nígbà tó fẹ́ fi ọkọ̀ rẹ̀ gun orí àwọn èṣọ́ náà lọ bẹrẹbẹ.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà ni pé obìnrin náà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tí wọ́n dá a dúró jọ ní gbólóhùn asọ̀ lórí ìwé ìgbélùú rẹ̀, obìnrin yìí ṣíná sọ́kọ̀ ó sì fẹ́ gbá wọn kọjá lọ ní tirẹ̀, ọ̀kan nínú wọn ló yìnbọn fún un tó sì kú.
Àwọn èṣọ́ yìí ṣe àpèjúwe ìwà obìnrin yìí gẹ́gẹ́ bíi ìwà ìfẹ̀míṣòfò, wọ́n ní àwọn kò jẹ̀bi ìbọn ti àwọn yìn pa á wọ́n sì ti kó àwọn ẹ̀ṣọ́ tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.
Àwọn èṣọ́ aṣọ́bodè orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà ń kojú oríṣìí àdojúkọ láti ìgbà tí ààrẹ orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà; Donald Trump ti pàṣẹ fún wọn kí wọn ó fi gbogbo ẹni tí kò bá ní ìwé tó yẹ sọkò padà sí ìlú wọn.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newstodaybreaking newsÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubanewsnewsinyorubanewsonlinetrendingtrendingnewsviralposts
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀÌBÌKÍTÀ ILÉ ÌWÒSÀN LÓ ṢEKÚ PA ỌMỌ MI.

ÌJỌBA TI DÁ DỌ́KÍTÀ TÍ CHIMAMANDA FI Ẹ̀SÙN KAN DÚRÓ NÁ.

Recommended

Olatunji Alausa

Ẹ YÀGÒ FÚN ÀHESỌ Ọ̀RỌ̀ – MÍNÍSÍTÀ FÚN ÈTÒ Ẹ̀KỌ́.

1 year ago
ÌYÀWÓ NI OLAMIDE FẸ́ FỌ́ IRIN MỌ́ LÓRÍ TÓ FI BA ỌMỌ RẸ̀, ỌMỌ ỌDÚN KAN.

ỌWỌ́ TẸ ỌLỌ́PÀÁ TÓ Ń DIGUN JALÈ NÍ ÌPÍNLẸ̀ EDO.

10 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.