Ègbìnrin ọ̀tẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ wa àti kékeré àti àgbà dà báyìí.
Nígbà tí rògbòdìyàn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lójútùú bọ̀ láàrin Obasa àti Meranda, èyí tó ṣẹlẹ̀ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tún gbẹnután.
Natasha Akpoti-Uduaghan; ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ilẹ̀ yìí tó ń ṣojú ẹ̀kun àárín gbùngbùn Kogi tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ìfọrọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán lópin ọ̀sẹ̀ tó lọ yìí.
Natasha wí pé olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ìyẹn Godswill Akpabio ń fòró òun nílé ìgbìmọ̀ nítorí pé òun kò gbà kò báa ní àjọṣepọ̀.
Natasha ṣe àlàyé pé gbogbo ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2023 nígbà tí Akpabio pe òun sì àpèjẹ ọjọ́ ìbí ní ilé rẹ̀.
Natasha wí pé òun àti ọkọ òun ni àwọn jọ lọ sí ìbi àpèjẹ náà, lẹ́yìn tí ó kí ọkọ òun tán, Akpabio di òun lọ́wọ́ mú ó sì wí pé òun fẹ́ fi àyíká ilé náà han òun.
Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí Natasha ṣe, Akpabio mú Natasha kúrò ní iwájú ọkọ rẹ̀ lọ sí yàrá ìgbàlejò kan nínú ilé náà, nígbà tí wọ́n jókòó tán, Akpabio béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé ó fẹ́ràn ilé náà, Natasha fèsì pé ilé náà dára gan-an ni.
Ohun tí Akpabio wá wí ni pé ‘Ní báyìí tí o ti di ọmọ ilé ìgbìmọ̀, wàá wá ààyè máa wá síbi ká jọ máa gbádùn ara wa, wàá dẹ̀ gbádùn ẹ̀ gan-an’
Lẹ́yìn ìgbà náà ni òun ríi pé àwọn wọ́n yọ ìwé tí òun kọ nípa ilé iṣẹ́ irin Ajaokuta sẹ́yìn lẹ́ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà tí òun sì lọ bá olórí ilé ìgbìmọ̀ ìyẹn Akpabio, ohun tó sọ fún òun ni pé ‘ Natasha, èmi ni olórí ilé, bí o bá tọ́jú mi tóo mu inú mi dùn, yùngbà bí èèrà inú ṣúgà lóó máa gbádùn’
Natasha wí pé òun ṣebí ẹni tí kò gbọ́ ohun tó sọ. Natasha ṣe àpèjúwe ọ̀rọ̀ náà bíi ti olùkọ́ tó ń fi ìyà jẹ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nítorí ó kọ̀ láti báa lájọṣepọ̀.
Ohun tó wá fa gbogbo yánpọnyánrin yìí gan-an ni èdè àìyedè tó ṣẹlẹ̀ láàrin Natasha àti Akpabio ní ìjokòó ilé tó kọjá yìí.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n kó ìbọn lọ́wọ́ ló dínà mọ́ ọn nígbà tí ó fẹ́ lọ sí ààyè rẹ̀ lọ jókòó, wọ́n wí fún un pé Akpabio ti pààrọ̀ ìjokòó rẹ̀ kò sí ní anfààní láti jókòó sí ibẹ̀ yẹn mọ́.
Ohun tó bí Natasha nínú ni pé Akpabio kò sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé òun ti pààrọ̀ ààyè rẹ̀, kódà, òun wá sí ìjokòó tó kọjá òun sì jókòó sí ààyè òun.
Natasha tẹ̀síwájú nínú àlàyé rẹ̀ pé àwọn akẹgbẹ́ òun wí fún òun pé kí òun ó má béèrè nítorí pé ẹ̀dẹ ni.
Ọ̀rọ̀ yìí ti bí ọ̀pọlọpọ̀ awuyewuye láàrin àwọn olóṣèlú àti lórí ìkànnì ayélujára.
Igbákejì ààrẹ ìjarùn-ún; Atiku Abubakar ganu sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí pé kí wọn ó ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí Natasha fi kan Akpabio yìí.
Ọ̀ṣẹ̀ méjì ni wọ́n fún ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà láti jábọ̀ fún gbogbo ilé.
Ìwádìí kò tíì parí tí Akpabio fi kọ ọ́ sójú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook rẹ̀ pé ‘Ṣé Natasha rò pé ẹ̀tọ́ òun ni ipò aṣòfin ni? Lẹ́ni tí kò mọ̀ ju kó máa kun ojú kó sì máa wọ aṣọ tó fara sílẹ̀ wá sí ìjokòó ilé’
Ohun tí Akpabio kọ yìí ni agbẹjọ́rò Natasha fi pe ẹjọ́ mìíràn tó sì béèrè fún ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù owó ìtanràn.
Èyí ni wọ́n ń fà lọ́wọ́ tí ìyàwó Akpabio fi jáde wá gbẹ̀rí ọkọ rẹ̀ jẹ́.
Arábìnrin Ekaette Akpabio; Aya Godswill Akpabio pe Natasha lẹ́jọ́ fún ìbanilórúkọjẹ́. Ó wí pé ọkọ òun olówó orí òun jẹ́ ẹni tó kóra rẹ̀ ní ìjánu, ó wí pé Akpabio kò le kọnu sí Natasha débi pé yóò tún ní kó máa wá sí ilé àwọn. Ekaette wí pé kí Natasha ó ki ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ nítorí pé ọkọ òun kò le ṣe irú rẹ̀.
Arábìnrin Ekaette Akpabio kò ṣàì má mẹ́nu ba pé ọkọ òun; Godswill Akpabio ti fi ìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom, ó wí pé àwọn obìnrin tí wọ́n dára ju Natasha lọ wà nínú ìgbìmọ̀ rẹ̀ kò sì sí èyí tó sọ pé ọkọ òun kọnu sí òun rí. Bílíọ̀nù ọ̀tàlérúgba-ó-dín-mẹ́wàá náírà ni Ekaette bèèrè fún bíi owó ìtanràn lọ́wọ́ Natasha.
Oríṣìí àwọn èèyàn, ikọ̀ àti lájọlájọ ló ti dìde sí ọ̀rọ̀ yìí. Gbogbo wọn ló bèèrè fún ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí Natasha fi kan Akpabio yìí.
Wọ́n ní àwọn obìnrin máa ń kojú àwọn nǹkan báyìí ní àwùjọ ní èyí tó máa ń mú ìfàsẹ́yìn bá wọn làtàrí àwọn ọ̀gá tàbí olóríkórí báyìí, wọ́n ní àwọn ń retí èsì tó yanrantí láti ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí náà.
Nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin —
Àwọn obìnrin mẹ́ta yòókù wí pé ó lòdì sí òfin ilé kí àwọn ó tú ìdí ara àwọn síta, nítorí náà, àwọn kò ní le wí nǹkankan nípa Natasha. Àmọ́, ọ̀kan nínú wọn wí pé kìí ṣe obìnrin nìkan ni wọ́n máa ń pa ìjokòó rẹ̀ dà nínú ilé àmọ́ obìnrin ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí jù.
Àwọn ọkùnrin ilé gbè lẹ́yìn Akpabio, ọ̀kan nínú àwọn wí pé irọ́ funfun balau ni Natasha ń pa pé nítorí Akpabio pa ìjokòó rẹ̀ dà ló ṣe pa adúrú irọ́ bàǹtàbanta yẹn mọ́ ọn.
Ẹ̀yìn ará, èèyàn méjì kìí pàdánù irọ́, ta ni ẹ rò pé ó ń parọ́ láàrin Natasha àti Akpabio?