Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tí ó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Femi Adio Wonder ti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tó ń bá a jà, ọ̀rọ̀ náà gba omijé lójú ẹni.
Adio wí pé ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí òun ti ń ṣiṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ àti olùpolówó sinímá agbéléwò rèé. Adio a máa ṣe ètò lórí rédíò Èkó ìgbà náà tó di Eko FM nísìn yìí, bákan náà ló ti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò Paramount ní Abẹ́òkùta.
Nípa àìlera rẹ̀:
Adio ṣe àlàyé pé ara òun ti ń fún òun ní àpẹẹrẹ àmọ́ òun kò fi ọkàn síi títí tó fi bu rẹ́kẹ, àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni ó ń bá Adio fínra tó sì ti run àwọn ohun ìní rẹ̀ ló lórí.
Adio ní òun ti ta gbogbo ilé òun àfi ọ̀kan tó wà ní Abule Oko tí òun ń gbé, gbogbo ọkọ̀ náà ti lọ sí i.
Adio wí pé akẹgbẹ́ òun ní kí òun ó má dé àìsàn náà mọ́ra àmọ́ ojú ń ti òun láti ké gbàjarè nítorí pé òun máa ń fún àwọn èèyàn ni tẹ́lẹ̀ òun kò sì fẹ́ di alágbe. Nígbà tí àbúrò Gbenga Adeboye ìyẹn Seun Adeboye náà tún wá kàn sí òun pé kí òun ó ké gbàjarè ni ó mú kí òun ó sọ̀rọ̀ síta lórí àìsàn náà.
Adio ṣe àlàyé pé ìnira tí òun ń kojú náà pọ̀ gan-an, ó ti lé lọ́dún mẹ́ta tí òun ti ṣiṣẹ́ gbẹ̀yìn, ó ní tí òun bá rìn báyìí, ṣe ni yóò dàbí ìgbà tí òun ń tẹ ẹ̀kúfọ́ ìgò mọ́lẹ̀ ni, ìnira náà pọ̀ gan-an.
Adio wí pé ẹkún lòun máa ń fi ojoojúmọ́ sun, ó wí pé nǹkan nira fún òun gan-an láti bíi ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ó ní òun kò lérò pé òun le wà ní irú ipò náà. Àwọn èèyàn máa ń wí pé èèyàn ire lòun kò yẹ kí irú èyí tọ́ sí òun.
Àwọn ìrànlówọ́ tó ti rí gbà:
Adio ṣe àlàyé pé àwọn èèyàn sa ipá wọn fún òun, ó ní òun a máa rí àwọn owó dị́ẹ̀díẹ̀ gbà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá wá kí òun, ẹlòmíràn á fún òun ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà, ẹgbẹ̀rún méjì náírà, ẹgbẹ̀rún kan náírà, nígbà mìíràn, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà.
Ó ní òun mọ̀ pé kálukú ló ní bùkátà tirẹ̀, òun kò sì le kó bùkátà àìsàn òun bá ẹlòmíràn ni ó ṣ e ń ba òun lọ́kàn jẹ́.
Adio dúpẹ́ lọ́wọ́ Wasiu Alabi Pasuma fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ó ní ó fún òun ní mílíọ́nù méjì náírà, ó ní òun dúpẹ́ fún ìfẹ́ tó fi hàn sí òun náà. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Alhaji Fatai Bantale, Asiwaju Akeem Enudunjuyo àti àwọn mìíràn tí kò le dárúkọ wọn tán. Adio dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn ó sì ṣe àdúrà fún wọn pé wọn kò ní fi irú rẹ̀ gbà á.
Báwo ni o ṣe ń gbọ́ bùkátà rẹ?
Adio wí pé èyí gangan ló ń jẹ́ òun. Ibi tó le sí gan-an ni èyí, àtigbọ́ bùkátà nira gidigidi nítorí pé òun kò ṣiṣẹ́, ohun tí àwọn èèyàn ń fún òun ni òun fi ń gbéra.
Ó wí pé yàtọ̀ sí owó tí òun fi ń tọ́jú àìsà ìtọ̀ ṣúgà náà, àwọn bùkátà mìíràn wà nílẹ̀ rẹpẹtẹ tí òun kò le gbé. Ó ní ibi tó burú sí ni pé àwọn bùkátà yìí kò le tán.
Adio tẹ̀síwajú pé òun kò fẹ́ kí àwọn èèyàn ó pòṣé bí wọ́n bá rí ìpè òun ni òun ṣe ń ní ìrètí àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ àìsàn yìí ti mú kí o ní ìdẹ́yẹsí láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?
Adio sọ̀rọ̀ lórí ìhà tí àwọn èèyàn kan kọ sí òun. Ó ní lójú òun, wọn yóò káàánú àmọ́ bí wọ́n bá ti kúrò lọ́dọ̀ òun ni wọn yóò yíhùn padà pé ta ló kó bá a?
Adio ní èyí ba òun nínú jẹ́ nítorí pé òun kò fìgbà kan ṣe abúrú tàbí hu ìwà ìkà sí èèyàn rí. Ó ní òun gbìyànjú àti ṣe ìrántí ìrìn àjò òun bóyá òun le rántí ìgbà tí òun ṣe ìkà sí èèyàn rí àmọ́ òun kò rántí ni òun ṣe rí ohun tí wọ́n ṣe yìí bíi ìwà ìkà.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn tí òun ti fìgbà kan ṣe ìrànwọ́ fún ni òun gbọ́ pé wọ́n ń sọ kiri pé kí àwọn èèyàn ó má ṣe ìrànwọ́ fún òun pé òun yóò fi owó náà mu ọtí ni.
Adio wí pé pẹ̀lú ipò tí òun wà yìí, ṣé ọtí ni òun yóò máa mu? ó wí pé ohun tó dun òun níbẹ̀ ni pé àwọn èèyàn tí wọ́n ti jẹ ata, epo àti iyọ̀ òun ni wọ́n ń sọ irú èyí nípa òun.
Adio ṣe àlàyé pé òtítọ́ ni òun dìmú o, òtítọ́ náà sì ni pé ẹni tó wà láyé ló ní àǹfàáni àtimọ ọ̀tá rẹ̀, òun yóò gbìyànjú láti du ẹ̀mí òun láti má kú.
Ó wí pé ìgbà tí Pasuma fún òun lówó náà ni ìkóríra náà pọ̀ síi, àwọn èèyàn náà fi àìdunnú wọn hàn sí mílíọ̀nù méjì náírà tí Pasuma fún òun wọ́n sì fẹ́ pín nínú rẹ̀.
Èyí ló mú kí òun ó kọminú pé ṣé lóòótọ́ ni àwọn èèyàn yìí nífẹ̀ẹ́ òun dénú àbí ọjọ́ ikú òun ni wọ́n ń retí.
Ńjẹ́ o rí mílíọ̀nù méjì náà ṣe ìtọ́jú ara rẹ?
Adio fèsì pé owó náà ká àwọn ìtọ́jú kèékèèkèé ni kò ká ojúlówó ìtọ́jú tí yóò ṣẹ́gun àìsàn náà.
Dọ́kítà wí pé kí òun ó lọ sí orílẹ̀-èdè India fún ìtọ́jú tó péye àmọ́ kò sí agbára.
Adio wí pé àìsàn náà burú débi pé gbogbo ara òun yóò dàbí ìgbà tí wọ́n bá dá iná síi, nígbà mìíràn, òun kò ní lókun kankan nínú.
Èló ni o nílò fún ìtọ́jú àìsàn yìí?
Adio wí pé ogún mílíọ̀nù náírà ni àwọn dọ́kítà bèèrè fún kí wọ́n le gbé òun lọ sí orílẹ̀-èdè India fún ìtọ́jú.
Discussion about this post